Home Blog Page 23

Adájọ́ ní ọnà tó bá wu àjọ elétò ìdìbò ní wọ́n fi lè gbé èsì wọn jáde

Adájọ́ ní ọnà tó bá wu àjọ elétò ìdìbò ní wọ́n fi lè gbé èsì wọn jáde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Pẹ̀lú bí ìdájọ ṣe ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹsùn tí olùdíje ẹgbẹ́ Labour, Peter Obi, fi kan Ààrẹ Bọla Tinubu àti ẹgbẹ́ APC, tó fi mọ́ àjọ elétò ìdìbò, lórí ètò ìbò Ààrẹ tó wáyé nínú oṣù Kejì, ọdún yìí, ilé-ẹjọ́ tó ń gbọ́ awuyewuye lórí èsì ìdìbò náà ti sọ pé kò sí ọ̀rọ̀ nínú pé àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wa kò gbé èsì àbájáde ètò ìdìbò náà sórí ẹ̀rọ alátagbà.

Ilé-ẹjọ́ ṣọ pé kò sí òfin tó kàn-ań nípá fún àjọ elétò ìdìbò láti gbé èsì ìdìbò náà jáde sórí afẹ́fẹ́, tàbí kí wọ́n máa ṣe àfihàn èsì ìdìbò láti ibùdó ìdìbò tí wọ́n ti ń dì í, tàbí sí orí ayélujára. Wọ́n ní àṣẹ àti agbára wà lọ́wọ́ àjọ elétò ìdìbò láti lo ọ̀nà tó bá wù wọ́n láti kó èsí ìdìbò jọ ní orílẹ-èdè Nàìjíríà.

Fún ìdí èyí, adájọ́ dá ẹjọ́ tí olùpẹ̀jọ́ pè lórí eléyìí nù. Wọ́n ní kò sọ́rọ̀ níbẹ̀.

Bẹ́ ò bá gbàgbé, lára àwọn ẹ̀sùn tí Peter Obi fi kan àjọ elétò ìdìbò nílé-ẹjọ́ náà ni bí wọ́n ṣe kọ̀ láti máa ṣàfihàn èsì ìdìbò náà bó ṣe n jáde láwọn ibùdó ìdìbò kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n sì tún kọ̀ láti gbé èsì ìdìbò náà sórí ayélujára bó ṣe ń lọ sí gẹ́gẹ́ bí àjọ elétò ìdìbò ṣe ṣèlérí pé àwọn máa ṣe kó tóó di pé ètò ìdìbò náà wáyé.

Bákan náà ni ilé-ẹjọ́ kò gba ẹ̀rí èsì ìdìbò tó rí bálabàla tí Obi kó wá sí kóòtù gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀rí, wọ́n ní kò so ó mọ́ ibùdó ìdìbò kankan pé àwọn ni wọ́n ni-ín, bẹ́ẹ̀ ni kò sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ẹ̀rí tó so mọ́ ẹ̀sùn rẹ̀.

Àjẹbánu ò bá ti dojú Nàíjíríà bolẹ̀… – Buhari

Àjẹbánu ò bá ti dojú Nàíjíríà bolẹ̀… – Buhari

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní aríṣe laríkà, aríkà yóó padà di ọ̀rọ̀ ìrègún .
Ààrẹ àná ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti kan sáárá sí ìṣèjọba rẹ̀ pé òhun ló gba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ ìwà àjẹbánu.

Buhari ní ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà kò bá ti dẹnu kọlẹ̀ tí kìí bá ṣe wí pé ìjọba òun tètè dìde sí ìwà àjẹbánu tó ti gbokùn láàárín àwùjọ.

Ó ní àṣeyọrí tí ìṣèjọba òun ní lórí gbígbé ogun ti ìwà ìbàjẹ́ kò kéré rárá.

Ọ̀rọ̀ yìí ló jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ Buhari, Garba Shehu fi síta lọ́jọ́ Àìkú.

Èyí ni Buhari fi fèsì sí àwọn ẹ̀sùn ti agbẹjọ́rò àgbà àti Mínísítà fétò ìdájọ́ tẹ́lẹ̀ rí, Mohammed Adokie fi kàn án lórí ọ̀rọ̀ Process & Industrial Development (PID), owó Paris Club àti ilé iṣẹ́ Ajaokuta.

Àtẹ̀jáde náà ní gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí Adokie mú jáde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ló jẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lábẹ́ ìjọba tó ti ṣe Mínísítà fétò ìdájọ́.

Buhari ní ìjọba tí òun gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ àkànṣe iṣẹ́ P&ID àti pé ìjọba ló ṣe ìdádúró iṣẹ́ náà èyí tó ti dá gbèsè tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là sọ́rùn Nàìjíríà.

Bákan náà ló ní ọ̀rọ̀ rí lórí ti Paris Club èyí tí Adokie fi ṣàpèjúwe ìwà àjẹbánu lábẹ́ ìṣèjọba Buhari, ó ní Adokie wà lára ìjọba tó gbin èèbù ìkà sílẹ̀ fún Nàìjíríà àti àwọn ìdájọ́ tó wáyé lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́ náà.

Ó ní òun tí ó dájú ni pé ìṣèjọba òun wá mú àtúnṣe bá àwọn ìwà àjẹbánu tó ti ń lọ lórí P&ID, Paris Club ati Ajaokuta àti láti gba Nàìjíríà kalẹ̀ lọ́wọ́ ìdẹnukọlẹ̀ ètò ọrọ̀ ajé tí kò bá tẹ̀yìn àwọn ìwà náà yọ.

Ó ní àwọn àṣeyọrí tí ìjọba òun ṣe kò kéré rárá bíi gbígbé àwọn òfin dìde lórí ìwà àjẹbánu, gbígba àwọn owó tí àwọn kan jí lọ sílẹ̀ òkèrè padà sílé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn owó yìí ni àwọn lò láti fi ṣe àwọn ìdàgbàsókè sí orílẹ̀ èdè yìí.

Ó ní èyí ló mú kí àjo ìṣọ̀kan ilẹ̀ Adúláwọ̀, AU fi yan òun ní akọni nídìí gbígbógun ti ìwà àjẹbánu.

Àtẹ̀jáde náà ní gbogbo ọmọ Nàìjíríà ló lè sọ̀rọ̀ nípa ìṣèjọba Buhari àmọ́ ẹni tí yóò bá nàka àléébù ìwà àjẹbánu sí ìṣèjọba Buhari gbọ́dọ̀ ri dájú pé ọwọ́ òun mọ́ nídìí ìwà ìbàjẹ́ pàápàá ìwà àjẹbánu.

Alàgbà Taiwo Akinkunmi ṣe díẹ̣̀ lọ́rọ̀ Nàìjíríà kó tó tẹ́rígbaṣọ

  1. Alàgbà Taiwo Akinkunmi ṣe díẹ̣̀ lọ́rọ̀ Nàìjíríà kó
    tó tẹ́rígbaṣọ

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní aríṣe la rì kà,aríkà ni baba ìrègún,
ọkùnrin tó ṣe àsìá orílẹ-èdè wa, Nàìjíríà, Alàgbà Taiwo Akinkunmi (O.F.R), ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rùn-ún lẹ́yìn tí wọ́n kí àwọn òbí ẹ̀ kú ewu. Ọ̀rọ̀ tí padà di ẹ kú aráfẹ́rakù fún ẹbí,ará,ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀.

Ọmọ rẹ̀, Akinkunmi Akinwunmi Samuel, ló sọ èyí di mímọ̀ lójú òpó ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀, níbi tí ó ti ṣèdárò bàbá tó bí i lọ́mọ ọ̀hún.

Ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún, ọdún 1936, ni wọ́n bí i. Ìyẹn ni pé ọdún mẹ́tàdínláàdọ́rùn-ún (87) ni bàbá náà lò lókè èèpẹ̀ kó tó dágbére fáyé

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú Ìbàdàn ni bàbá yìí ń gbé, ọmọ bíbí ìlú Òwu, ní ìpínlẹ̀ Ògùn, ní í ṣe.

Ó lọ sílé ẹ̀kọ́ Baptist Day fún ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, àti Ìbàdàn Grammar School, fún ẹ̀kọ́ girama rẹ̀.

Akinkunmi gba iṣẹ́ ìjọba ní sẹkitéríàtì Ìbàdàn, lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ díẹ ló sì lọ sílùú Norway, níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀.

Ìlú Òyìnbó ló wà tó fi rí ìkéde kan pé wọ́n ń wá ẹni tí yóó ṣe àsìá tí Nàìjíríà yóò máa lò ní ìpalẹ̀mọ́ fún òmìnira orílẹ-èdè yìí.

Ọkùnrin ọmọ bíbí ìlú Owu yìí náà wà lára ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó dábàá irú àsìá tí Nàìjíríà lè máa lò, tìẹ ni wọ́n sì mú nínú àwọn èèyàn bíi ẹgbẹ̀rún méjì tó dán kinní ọ̀hún wò.

Àwòrán tó kọ́kọ́ ṣe ni àwọ̀ funfun láàrin pẹ̀lú àwọ̀ ewéko méjì, tí ìtànsan òòrùn sì wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ìgbìmọ̀ tó ṣàyẹ̀wò fún un ló yọ ìtànsan òòrùn yìí dànù.

Ìdí tí wọ́n ṣe mú ti Akinkunmi ni pé ó ṣàkótán àpèjúwe ilẹ̀ wa. Àwọ ewéko dúró fún àwọn igbó àti ohun àlùmọ́ọ́nì tó sodo sílẹ̀ wa, tí àwọ̀ funfun sì dúró fún àlàáfíà.

Ọjọ́ kin-in-ni, oṣù Kẹwàá, ọdún 1960, ni wọ́n ta àsìá yìí níbi ayẹyẹ òmìnira ilẹ̀ yìí, dípò àsìá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ ti ìjọba àwọn Òyìnbó amúnisìn.

Ọgọ́rùn-ún pọun (100€) nìjọba fún Akinkunmi fún iṣẹ́ ribiribi náà, tí ìjọba Ààrẹ tẹlẹ, Goodluck Jonathan, sì fi àmi-ẹ̀yẹ MON dá a lọ́lá lọ́dún 2014, lẹ́yìn tí ileegbimọ aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti kọ́kọ́ fún un lámì-ẹ̀yẹ lọ́dún 2013, lásìkò ìjọba Gómìnà Abíọ́lá Ajimọbi.

A ó ṣètò ìdìbò tó mọ́yánlórí láìpẹ́— Ológun adìtẹ̀gbàjọba Gabon

A ó ṣètò ìdìbò tó mọ́yánlórí láìpẹ́— Ológun adìtẹ̀gbàjọba Gabon

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà ní àìníláárí aráayé ní-ín múwọn rántí araọ̀run.
Olórí ìjọba ológun lórílẹ̀ èdè Gabon ti ṣe ìlérí láti dá agbára padà sọ́dọ̀ ìjọba alágbádá lẹ́yìn tí ètò ìdìbò tó bá òfin mu bá wáyé.

Ó sọ èyí lásìkò tó ń búra wọlé gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ fìdíhẹẹ́ ṣùgbọ́n kò sọ ọjọ́ pàtó tí ìjọba ológun yóò gbé agbára sílẹ̀.

Ògágun Brice Nguema léwájú ìdìtẹ̀gbàjọba ìjọba lọ́wọ́ Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Ali Bongo lẹ́yìn ètò ìdìbò tó wáyé kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí.

Ọpọ àwọn èèyàn ló tú síta síbi ayẹyẹ ọhún, tí wọ́n sì tẹ́wọ́gba ìgbésẹ̀ ológun ọ̀hún.

Bákan náà ni àwọn mìíràn sọ pé ìjọba Ọ̀gágun Nguema ni ó jẹ́ ìtẹ̀síwájú ọdún márùndínlọ́gọ́ta ìdílé Bongo.

Bàbá Ali Bongo, Omar, wa ni ìjọba fún ọdún mọ́kànlélógójì kó tó kú ní ọdún 2009, ti ọmọ sì bọ́ sí ìjọba.

Ọ̀gágun, ẹni ọdún méjìdínláàdọ́ta lo gbogbo ọgbọ́n rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ológun nínú ìdílé Bongo, ti ọ̀pọ̀ sì rí i gẹ́gẹ́ bí i mọ̀lẹ́bí Bongo.

Nguema ni òun ti paá láṣẹ pé kí ìjọba tuntun yìí tú gbogbo àwọn olóṣèlú tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀.

Àwọn Mínísítà ìjọba tẹ́lẹ̀ wá síbi ibúra wọlé náà ṣùgbọ́n àwọn aráàlú pariwo mọ́ wọn.

Gabon ni orílẹ-èdè kẹfà tó gba òmìnira láti ilẹ̀ France ti ìjọba ológun ti gba ìṣàkóso ìjọba láàrin ọdún mẹ́ta

Ìṣèjọba alawọ dúdú, àwọn orílẹ̀ èdè kan nìyí tí Ààrẹ wọn ti lò tayọ ọgbọ̀n ọdún nípò

Ìṣèjọba alawọ dúdú, àwọn orílẹ̀ èdè kan nìyí tí Ààrẹ wọn ti lò tayọ ọgbọ̀n ọdún nípò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹnìkan ṣoṣo kò dùn tó ní yànmùyànmù ekìrí ọ̀yà. Ó túmọ̀ sí pè èèyàn kan kìí jẹ kílẹ̀ ó fẹ́.Jẹ́ kí n jẹ́ ní-ín máyò dùn.
Sùgbọ́n ìwádìí àti àkọsílẹ̀ ti fojúhàn pé ìṣesí àwọn dúdúláwọ̀ mú ìwọ̀ra dáni.Èyí kò sì jẹ́ kí lámùúyẹ lábala ètò
ẹ̀kọ́ lápapọ̀, ọrọ̀ ajé, ètò ìṣèlú, ètò ọ̀gbìn, abbl. Ẹ tẹ̀síwájú.

Kó sí àwítúnwí mọ́,Gabon ni orílẹ̀ èdè tuntun tí àwọn ológun ti kéde pé àwọn ti gbàjọba níbẹ̀ lásìkò yìí tí àwọn ológun ń gbàjọba kiri ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Ní orí amóhùnmáwòrán ni àwọn ológun náà ti kéde l’Ọ́jọ́rú pé àwọn ti gbàjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Ali Bongo.

Ikede wọn waye lẹyin ti wọn ti wọ́gilé èsì ìdìbò tó wáyé lọ́rílẹ̀ èdè náà lópin ọ̀sẹ̀ níbi tí wọ́n ti kéde Ali Bongo gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ìbò náà.

Ọdún kẹrìndínlọ́gọ́ta tí ẹbí Ali Bongo ti ń jẹ Ààrẹ Gabon.

Bongo di ààrẹ Gabon lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ jáde láyé lẹ́yìn tó ṣe ààrẹ orílẹ̀ èdè náà láti ọdún 1967 sí ọdún 2009 tó sì lo ọdún 42 lórí ipò.

Ẹ̀wẹ̀, Ali Bongo kọ́ ni Ààrẹ tó ti lo ọdún pípẹ́ lórí ipò pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn nílẹ̀ Adúláwọ̀.

Teodoro Obiang Nguema Mbasogo – Equatorial Guinea

Teodoro Obiang Nguema Mbasogo tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin ni Ààrẹ tó ti pẹ́ lórí ipò jùlọ ní àgbàyé pẹ̀lú bó ṣe ti pé ọdún mẹ́rìnlélógójì lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.

Láti ọjọ́ Kẹta oṣù Kẹjọ ọdún 1979 ló ti wà lórí ipò bíi ààrẹ Equatorial Guinea, òun sì ni ààrẹ kejì tí yóò jẹ ní orílẹ̀ èdè náà.

Ní oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni wọ́n tún kéde pé Obiang ló tún jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀ èdè náà.

Ní àgbáyé, òun ni Ààrẹ Kejì tó ti pẹ́ lórí oyè láì kìí ṣe ìdílé olóyè.

Ọmọ Obiang, Teodoro Nguema Obiang Mangue ni igbákejì rẹ̀, tó sì sọ lẹ́yìn ìbò oṣù Kọkànlá náà pé ẹgbẹ́ àwọn ń ṣe dáadáa ni ọ̀pọ̀ ènìyàn tún fi dìbò fún àwọn.

Ààrẹ Obiang di orílẹ̀ èdè Equatorial Guinea mú ṣinṣin, tí àwọn ẹbí rẹ̀ sì di ipò gidi mú ní orílẹ̀ èdè náà.

Paul Biya – Cameroon

Paul Biya ni ààrẹ orílẹ̀ èdè Cameroon tó sì ti wà lórí ipò náà láti ọdún 1982.

Ogójì ọdún ni Paul Biya ti lò lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Cameroon.

Ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kejì ọdún 1933 ni wọ́n bí Biya, òun sì ni ààrẹ tó dàgbà jù ní ẹkùn Áfíríkà.

Ní ọdún 2018 ni wọ́n dìbò yan Paul Biya fún sáà Keje ní ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.

Ìròyìn ní àwọn ènìyàn k]o fi bẹ́ẹ̀ jáde dìbò lásìkò ètò ìdìbò náà.

Ẹgbẹ́ alátakò pè fún àtúndì ètò ìdìbò ọ̀hún àmọ́ ilé ẹjọ́ da ìpè náà nù.

Biya gba ipò Ààrẹ Cameroon lọ́wọ́ Ahmadou Ahidjo tó jẹ́ olóòtú ìjọba àti ààrẹ àkọ́kọ́ fún Cameroon, tó sì jẹ láàárín oṣù Kẹfà ọdún 1975 sí oṣù Kọkànlá ọdún 1982.

Ní ọdún 2025 ni ètò ìdìbò mìíràn yóò tún wáyé ní Cameroon.

Denis Sassou Nguesso – Republic of the Congo

Denis Sassou Nguesso ni ààrẹ Congo- Brazzaville, ẹni tó padà sípò lkyìn tí wọ́n tún ìwé òfin orílẹ̀ èdè náà kọ ní èyí tó fi ààyè gbà á láti dupò fún sáà Kẹta lọ́dún 2016.

Ní ọdún 1979 sí 1992 ló ti kọ́kọ́ jẹ ààrẹ orílẹ̀ èdè náà kọ tọ fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò tí wọ́n ṣe lọ́dún náà.

Ọdún 1997 ló tún díje padà tó sì ti wà lórí ipò láti ìgbà náà.

Ọdún méjìdínlógójì ni Denis Sassou Nguesso ti lò lórí ipò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Republic of Congo báyìí.

Wọ́n mú àyípadà bá ìwé òfin orílẹ̀ èdè náà níbi tí wọ́n ti yọ ọjọ́ orí àti iye ìgbà tí ènìyàn ti ṣe ìjọba rí gẹ́gẹ́ bí ohun ìdènà láti dupò Ààrẹ.

Nguesso tó i pé ọgọ́rin ọdún báyìí ṣì ń gbèrò láti díje dupò ààrẹ fún ìgbà karùn-ún.

Yoweri Museveni – Uganda

Ọdún mẹ́rìndínlógójì rèé tí Yoweri Museveni ti wà nípò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Uganda.

Museveni ni Ààrẹ Kẹsàn-án tó máa jẹ ní Uganda, tí wọ́n sì bi ní ọdún 1944 tó sì ti pé ọmọ ọdún méjìdínlọ́gọ́rin.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ, ìròyìn ní ìgbà rẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdàgbàsókè bá orílẹ̀ èdè rẹ̀ tí ìgbà rẹ̀ sì tu àwọn ènìyàn lára.

Fún àwọn ènìyàn Uganda, òun ni bàbá àti bàbábàbá wọn.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló máa ń pè é ní “Sevo” tí òun náà sì máa ń dàhún pẹ̀lú Bazukulu, èyí tó túmọ̀ sí ọmọọmọ ní èdè Uganda.

Ó parí! Èdè Yorùbá di ọ̀kan lára àwọn èdè fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọkọ̀ wíwà I’Ámẹ́ríkà

Ó parí! Èdè Yorùbá di ọ̀kan lára àwọn èdè fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọkọ̀ wíwà I’Ámẹ́ríkà

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé ilé kúkú ni àkùkọdìyẹ wa kò ti níyì, tiyì tẹ̀yẹ ni bó bá ti dóde tó kọ jákè gaaraga.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Maryland, níleẹ̀ Amẹ́ríkà ti fi èdè Yorùbá kún ara àwọn èdè tí yóó ma lò fún ẹ̀kọ́ àwọn tó bá fẹ́ gba ìwé ẹ̀rí moyege ọkọ̀ wíwà ní ìpínlẹ̀ náà.

Iléeṣẹ́ ìròyìn CBS jábọ̀ pé lọ́wọ́ yìí, èdè Gẹ̀ẹ́sì, Spanish, French, Korean, Chinese àti Vietnamese ni wọ́n gbà láàyè.

Ní báyìí, wọ́n ti fi èdè Yorùbá kún ara àwọn èdè tí wọn yóòoo máa lò.

Ìgbésẹ̀ yìí ló wáyé ní bi wọ́n ṣe n fi àwọn èdè tuntun kún ètò náà.

Yàtọ̀ sí èdè Yorùbá, àwọn èdè tuntun mìíràn tí wọ́n fi kún ètò ọ̀hún ni Tagalog, Amharic, Arabic, Russian, Urdu, Hindi, Farsi, Portuguese, àti American Sign Language.

Bẹ̀rẹ̀ láti inú oṣù Kẹsàn án yìí, àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Maryland yóó láǹfàní láti lo èdè Yorùbá àtàwọn èdè tuntun náà fún ìdánwò ìwé ẹ̀rí i mo yege ọkọ̀ wíwà wọn.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ Motor Vehicle Agency tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìwé ẹ̀rí náà, Chrissy Nizer, ṣàlàyé èrèdí tí wọ́n ṣe fí Yorùbá kún àwọn èdè ọ̀hún.

Ó ní àwọn ṣe àwọn ìwádìí kan, àwọn sì rí pé èdè Yorùbá jẹ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè ti àwọn èèyàn ń sọ jù ní Maryland.

Nizer sọ pé “ Ó ṣe pàtàkì fún wa láti lo èdè tí àwọn tó ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń wa ọkọ̀ gbọ́ dáadáa ní Maryland tó jẹ ìlú tí onírúurú èdè pọ̀ sí .”

Wàyí ò, ọ̀pọ̀ àwọn Nàìjíríà, pàápàá àwọn tó gbọ́, tí wọn sì ń sọ èdè ló ti kan sáárá sí ìgbésẹ̀ náà, tí wọ́n sì ń sọ pé ó yẹ kí irúfẹ́ ìgbésẹ báyìí wáyé ní Nàìjíríà tó jẹ orísun èdè Yorùbá.

Kò sí olórin Ghana tó ju Asake lo̩ – Shatta Wale

Kò sí olórin Ghana tó ju Asake lo̩ – Shatta Wale

Olorin ile ijo Ghana, Charles Nii Armah Mensah Jr., ti a mo si Shatta Wale, ti so pe ko si olorin Ghana to ju olorin Naijiria, Asake lowo yii.

O so eyi ninu eto Twitter kan ti atokun eto Ghana, Serwaa, tuko re ni Ojoru.

Shatta Wale so pe, “Ko si olorin Ghana to ti se oriire bii Asake. Koda kii se emi.

“Ko si enikeni ni ile ise [orin] Ghana to ti se nnkan ti Asake se. E je ka so ooto”.

Atokun naa jalu oro re: “Sugbon o so pe iwo ni olorin to lowo ju ni Ghana sibe o tii se nnkan de ipele Asake?”

Shatta Wale fesi pe: “Kilo de ti mo fi gbodo se de ipele Asake [saaju ki n to di olorin to lowo ju ni Ghana]? Olorin omo Spain kan wa ni Spain tabi Dominican Republic to n mu owo wole ti a o mo.”

E ranti pe Shatta Wale laipe yi so pe aseyori awon olorin Naijiria mu ki aseyori awon olorin Ghana dabi arara nigba to n ki Asake ku oriire fun tita tiketi iwole si gbongan ti o le e gba oke kan eniyan, O2 Arena ni London, United Kingdom tan.

 

E̩ jé̩ kí ìjo̩ba fagilé ètò àgùnbánirò̩ lásìkò yí – Kate Henshaw

E̩ jé̩ kí ìjo̩ba fagilé ètò àgùnbánirò̩ lásìkò yí – Kate Henshaw

Mary Fágbohùn

Ogbontarigi osere tiata Naijiria, Kate Henshaw ti ro ijoba apapo lati fagile eto agunbaniro (National Youth Service Corps, NYSC) nitori aisi aabo to peye.

E ranti pe awon odo mejo to n sinru ilu ni won jigbe ni popona kan ni ipinle Taraba.

Nigba ti yoo fesi lati oju awe Twitter ni Ojoru, Henshaw so pe ni iwon igba ti aabo awon odo to n sinru ilu ko ba ti daju, ki won fagile eto naa.

Osere naa ro ijoba lati dekun “fifi emi awon odo wa we’wu pelu iru eto naa.”

O ko o pe, “Nigba ti mo sinru ilu ni iha Ariwa, o je iriri mani gbagbe. Ni igba naa irinajo oju popo lati Bauchi si papako ofurufu ni aabo leyin eyi ti mo wo oko ofurufu lo si Eko pelu iwe idanimo agunbaniro mi, eyi to duro bii iwe irinna mi.

“O ti to akoko lati fagile eto isinru ilu ni igba ti awon agunbaniro ko le e rin irinajo pelu aabo to peye ni orile ede laisi idena!

“E dekun lati maa fi emi awon odo wa we’wu pelu iru eto yii. Aabo se pataki o si nilo iyanju patapata, kii se lerefe.”

Mo ju mílíò̩nù ló̩nà méjìlélógún dó̩là lo̩ – Burna Boy

Mo ju mílíò̩nù ló̩nà méjìlélógún dó̩là lo̩ – Burna Boy

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria olugbafe eye Grammy, Damini Ogulu, ti a mo si Burna Boy, ti soro nipa iduwon dukia re.

O soro yato si oun to jade lori ayelujara pe o ni milionu lona mejilelogun dola (bilionu lona merindinlogun le mejo) pere, o wi pe iduwon dukia oun “ju bee lo.”

O safihan eyi ninu iforo-wani-lenu-wo to se pelu onirohin Amerika, Complex.

Olu-foro-wani-lenu-wo naa beere pe: “Lori ohun ti a sawari lori Google iduwon dukia re je ko ju milionu mejilelogun dola.”

Burna Boy fesi pe: “Hahaha. E ma je ka soro nipa re. O dara, maa so pe won koja bee. Iyen dara. Sugbon kii se ooto. Won ju bee lo”

O so pe ibukun lo je fun oun lati le gbo bukata ebi oun.

“Nnkan nla ni, arakunrin. Ibukun ni. Ko kere si ibukun.

“Mo maa n so fun iya mi nigba ti mo wa ni kekere pe maa ra ile ati oko fun won ni ojo kan. Mo dupe pe Olorun gba fun mi bee.

 

Ajé wọgbó! Iná ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá jẹ́ lọ́jà Ogunpa, n’Íbàdàn

Ajé wọgbó! Iná ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá jẹ́ lọ́jà Ogunpa, n’Íbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀pọ̀ dúkìá ti owó wọn tayọ mílíọ̀nù Náírà ló sègbé sínú ìjànbá iná tó wáyé lọ́jà Ogunpa, Lábọ-Owó, tó wà lágbègbè Àgbókojó, nílùú Ìbàdàn.

Òru mọ́jú ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejìdílógún oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 yìí, làwọn ará ọjà yìí ṣàdéédé rí i tí iná ọhún ti fẹjú kẹkẹ, láìmọ ohun tó ṣokùnfà ìjànbá náà.

Gbogbo akitiyan àwọn ará ọjà yìí láti pa iná ọhún kò tunrun títí tí ọpọlọpọ dúkìá fi jóná tán gbúrúgbúrú.

Lára àwọn ọhún tó jónà ni bẹ́ẹ̀dì, àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń tún ọkò ṣe àtàwọn nǹkan mí-ìn.

Alága ẹgbẹ́ àwọn mẹkálíìkì lọjà Ogunpa Labowo, Ọgbẹni Azeez Ibrahim, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdájí ọjọ́ Jimọ làwọn tíṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sọ pé iná ọhún bẹ̀rẹ̀

Ó ní ó ṣeé ṣe kó jẹ́ iná tí àwọn ilé-iṣẹ́ amúnáwá mú dé lójijì ló fa sábàbí.

Ó wá rọ ìjọba láti ṣíjú àánú wo gbogbo àwọn tí dúkìá wọn sòfò látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Títí di bá a ṣe ń sọrọ yìí, làwọn tó pàdánù ọjà àti dúkìá wọ́n sínú ìjànbá ọ̀hún ṣì ń ṣírò iye owó wọn tó ṣofo sínú àjálù ọhún. Kí Edùmàrè Ó fòfò rẹ̀mí.