Ó parí! Èdè Yorùbá di ọ̀kan lára àwọn èdè fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọkọ̀ wíwà I’Ámẹ́ríkà

Ó parí! Èdè Yorùbá di ọ̀kan lára àwọn èdè fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọkọ̀ wíwà I’Ámẹ́ríkà

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé ilé kúkú ni àkùkọdìyẹ wa kò ti níyì, tiyì tẹ̀yẹ ni bó bá ti dóde tó kọ jákè gaaraga.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Maryland, níleẹ̀ Amẹ́ríkà ti fi èdè Yorùbá kún ara àwọn èdè tí yóó ma lò fún ẹ̀kọ́ àwọn tó bá fẹ́ gba ìwé ẹ̀rí moyege ọkọ̀ wíwà ní ìpínlẹ̀ náà.

Iléeṣẹ́ ìròyìn CBS jábọ̀ pé lọ́wọ́ yìí, èdè Gẹ̀ẹ́sì, Spanish, French, Korean, Chinese àti Vietnamese ni wọ́n gbà láàyè.

Ní báyìí, wọ́n ti fi èdè Yorùbá kún ara àwọn èdè tí wọn yóòoo máa lò.

Ìgbésẹ̀ yìí ló wáyé ní bi wọ́n ṣe n fi àwọn èdè tuntun kún ètò náà.

Yàtọ̀ sí èdè Yorùbá, àwọn èdè tuntun mìíràn tí wọ́n fi kún ètò ọ̀hún ni Tagalog, Amharic, Arabic, Russian, Urdu, Hindi, Farsi, Portuguese, àti American Sign Language.

Bẹ̀rẹ̀ láti inú oṣù Kẹsàn án yìí, àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Maryland yóó láǹfàní láti lo èdè Yorùbá àtàwọn èdè tuntun náà fún ìdánwò ìwé ẹ̀rí i mo yege ọkọ̀ wíwà wọn.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ Motor Vehicle Agency tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìwé ẹ̀rí náà, Chrissy Nizer, ṣàlàyé èrèdí tí wọ́n ṣe fí Yorùbá kún àwọn èdè ọ̀hún.

Ó ní àwọn ṣe àwọn ìwádìí kan, àwọn sì rí pé èdè Yorùbá jẹ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn èdè ti àwọn èèyàn ń sọ jù ní Maryland.

Nizer sọ pé “ Ó ṣe pàtàkì fún wa láti lo èdè tí àwọn tó ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń wa ọkọ̀ gbọ́ dáadáa ní Maryland tó jẹ ìlú tí onírúurú èdè pọ̀ sí .”

Wàyí ò, ọ̀pọ̀ àwọn Nàìjíríà, pàápàá àwọn tó gbọ́, tí wọn sì ń sọ èdè ló ti kan sáárá sí ìgbésẹ̀ náà, tí wọ́n sì ń sọ pé ó yẹ kí irúfẹ́ ìgbésẹ báyìí wáyé ní Nàìjíríà tó jẹ orísun èdè Yorùbá.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here