Àjẹbánu ò bá ti dojú Nàíjíríà bolẹ̀… – Buhari

Àjẹbánu ò bá ti dojú Nàíjíríà bolẹ̀… – Buhari

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní aríṣe laríkà, aríkà yóó padà di ọ̀rọ̀ ìrègún .
Ààrẹ àná ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti kan sáárá sí ìṣèjọba rẹ̀ pé òhun ló gba orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ ìwà àjẹbánu.

Buhari ní ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà kò bá ti dẹnu kọlẹ̀ tí kìí bá ṣe wí pé ìjọba òun tètè dìde sí ìwà àjẹbánu tó ti gbokùn láàárín àwùjọ.

Ó ní àṣeyọrí tí ìṣèjọba òun ní lórí gbígbé ogun ti ìwà ìbàjẹ́ kò kéré rárá.

Ọ̀rọ̀ yìí ló jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ Buhari, Garba Shehu fi síta lọ́jọ́ Àìkú.

Èyí ni Buhari fi fèsì sí àwọn ẹ̀sùn ti agbẹjọ́rò àgbà àti Mínísítà fétò ìdájọ́ tẹ́lẹ̀ rí, Mohammed Adokie fi kàn án lórí ọ̀rọ̀ Process & Industrial Development (PID), owó Paris Club àti ilé iṣẹ́ Ajaokuta.

Àtẹ̀jáde náà ní gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí Adokie mú jáde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ló jẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lábẹ́ ìjọba tó ti ṣe Mínísítà fétò ìdájọ́.

Buhari ní ìjọba tí òun gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ àkànṣe iṣẹ́ P&ID àti pé ìjọba ló ṣe ìdádúró iṣẹ́ náà èyí tó ti dá gbèsè tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là sọ́rùn Nàìjíríà.

Bákan náà ló ní ọ̀rọ̀ rí lórí ti Paris Club èyí tí Adokie fi ṣàpèjúwe ìwà àjẹbánu lábẹ́ ìṣèjọba Buhari, ó ní Adokie wà lára ìjọba tó gbin èèbù ìkà sílẹ̀ fún Nàìjíríà àti àwọn ìdájọ́ tó wáyé lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́ náà.

Ó ní òun tí ó dájú ni pé ìṣèjọba òun wá mú àtúnṣe bá àwọn ìwà àjẹbánu tó ti ń lọ lórí P&ID, Paris Club ati Ajaokuta àti láti gba Nàìjíríà kalẹ̀ lọ́wọ́ ìdẹnukọlẹ̀ ètò ọrọ̀ ajé tí kò bá tẹ̀yìn àwọn ìwà náà yọ.

Ó ní àwọn àṣeyọrí tí ìjọba òun ṣe kò kéré rárá bíi gbígbé àwọn òfin dìde lórí ìwà àjẹbánu, gbígba àwọn owó tí àwọn kan jí lọ sílẹ̀ òkèrè padà sílé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn owó yìí ni àwọn lò láti fi ṣe àwọn ìdàgbàsókè sí orílẹ̀ èdè yìí.

Ó ní èyí ló mú kí àjo ìṣọ̀kan ilẹ̀ Adúláwọ̀, AU fi yan òun ní akọni nídìí gbígbógun ti ìwà àjẹbánu.

Àtẹ̀jáde náà ní gbogbo ọmọ Nàìjíríà ló lè sọ̀rọ̀ nípa ìṣèjọba Buhari àmọ́ ẹni tí yóò bá nàka àléébù ìwà àjẹbánu sí ìṣèjọba Buhari gbọ́dọ̀ ri dájú pé ọwọ́ òun mọ́ nídìí ìwà ìbàjẹ́ pàápàá ìwà àjẹbánu.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here