Home Blog

Àparò kan ò jùkan lọ níjọba a mi- Mákindé

Àparò kan ò jùkan lọ níjọba a mi- Mákindé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ẹnjinnia Ṣèyí Mákindé, ti fi àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn balẹ̀ pé wíwọlé tí òun wọlé ìdìbò fún sáà kejì nípò Gómìnà yìí yóó ṣi ọ̀nà àṣeyọrí fún wọn.

Níbi àríyá tí wọ́n ṣe láti ṣàjọyọ̀ bí Gómìnà Mákindé ṣe wọlé ìdìbò fún sáà kejì ló ti sọ̀rọ̀ náà níléègbafẹ́ Ìlàjì Hotel and Resort, tó wà ládùgbóò Àkánrán, n’Íbàdàn, lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọ̀sẹ̀ yìí.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, “Àparò
kan kò ga ju ọ̀kan lọ mọ́ níìpínlẹ̀ Òyọ́ lọ́wọ́ tá a wà yìí, àwọn àparò tí wọ́n gorí ebè láti fi han gbogbo ayé pé àwọn ga ju ará yòókù lọ, èmi Ṣèyí Mákindé ti fi òkò nlá lé wọn kúrò lórí ebè, bákan náà ni gbogbo wá rí báyìí.

Ó kan sáárá sí Olùdásílẹ̀ iléègbafẹ́ náà, Ẹnjinnia Dọ̀tun Sanusi, fún ipa tó kó nínú ìdìbò tó gbé e wọlé. Bẹ́ẹ̀ ló dúpẹ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́sìnjẹ̀sìn gbogbo fún àtìlẹ́yìn tí wọ́n ṣe fún un lásìkò ìdìbò náà láì fi ti ẹsìn ṣe.

Bákan náà ló fi àwọn èèyàn ti kò dìbò fún un lọ́kàn balẹ̀ pé òun kò ní ín ránró, kódà òun ti ṣetán láti gbà wọ́n mọ́ra nínú ìṣèjọba òun.

Lára àwọn tó péjú síbi ayẹyẹ ọhún ni adarí ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù (CAN), àwọn Mùsùlùmí, ẹgbẹ́ àwọn òǹtàjà, ẹlẹ́ṣin ìbílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ààwẹ̀ Ramadan wọlé dé! Máa ṣàkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú oṣù ọlọ́rẹ

Ààwẹ̀ Ramadan wọlé dé! Máa ṣàkíyèsí àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú oṣù ọlọ́rẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààwẹ̀ Ramadan ọdún 2023 dé, bẹ́ẹ̀ kúkú kẹ̀kẹ̀ rẹ̀ sì ti gbòde bí ọ ṣe bẹ̀rẹ̀ nínú osù kẹta òǹkà ti òyìnbó yìí.

Èyí wáyé lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ tó ń ṣọ yíyọ oṣù ààwẹ̀ Ramadan ní Nàìjíríà, kéde pé àwọn ti rí oṣù láwọn ìpínlẹ̀ kan.

Gbogbo wà la mọ̀ pé ọgbọ̀n, tàbí ọ̀kàndínlọ́gbọ̀n ọjọ́ gbáko ni ààwẹ Ramdan fi má ń wáyé, èyí tó mú kí ètò jíjẹ àti mímu jẹ́ pàtàkì nínú oṣù náà.

Kìí kàn án ṣe oúnjẹ lásán, ó sẹ kókó láti jẹ oúnjẹ àti mu omi lọ́nà tó yẹ, tó sì bá àgọ́ ara mu, kí okun lè wà fún ààwẹ gbígbà.
Oríṣìí oúnjẹ méjì ni jíjẹ lásìkò ààwẹ Ramadan, lójoojúmọ́.

Àwọn oúnjẹ náà ni wọ́n ń pè ní Suhoor (Yorùbá ń pè é ní Sààrì), àti Iftar (Ìṣínu) ní ìrọ̀lẹ́. Oúnjẹ fún Suhoor gbọdọ̀ jẹ́ èyí tó lè fún ọ ní okun láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́ tí ìṣínu yóó wáyé.

Àwọn nǹkan tó lè mú kí èèyàn já ààwẹ rẹ̀
Lásìkò àwẹ Ramadan, dandan ni fún àwọn Mùsùlùmí láti yago fún jíjẹ àti mímu, tó fi mọ́ àwọn nǹkan fàájì láti àárọ̀ di ìrọ̀lẹ́. Ṣùgbọ́n ṣá, èèyàn lè já ààwẹ rẹ̀ nítorí àwọn ìdí kan.

Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nínú Kùràánì, àwọn tó bá ní àìsàn tó sì nílò kí wọ́n ó lo òògùn, àwọn arúgbó, àwọn tó wà lẹ́nu ìrìnàjò, aláboyún, obìnrin tó ń fún ọmọ ní ọyàn, tó fi mọ́ àwọn ọmọdé tí kò tíì bàlágà, lè yàn láti má gba àwẹ – papàá tó bá lè ní ipa tí kò dára lórí ìlera wọn.

Bákan náà obìnrin lè já ààwẹ rẹ̀ tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ lààrin àsìkò tó ń gbààwẹ̀

Àwọ n tí ọrọ̀ kan sì lè padà gba àwọn ọjọ́ ààwẹ tí wọ́n pàdánù lọ́jọ́ iwájú.

Ìlànà tí àwọn Mùsùlùmí ń gbà ṣínu yàtọ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan
Ní àwọn ibì kan, àṣà wọn ni láti ṣínu ní ilé olórí ẹbí wọn, tàbí ẹni tó dàgbà jù nínú ẹbí.

Oúnjẹ ní wọ́n ní àwọn kan fi má a ń ṣínu. Ṣùgbọ́n, ní àwọn orílẹ̀-èdè bí i UAE, oúnjẹ onípele mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n fi ń ṣínu.

Oṣù Ramadan gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí oṣù ọlọ́rẹ
Lásìkò yìí, ọ̀pọ̀ Mùsùlùmí ló má a ń ṣe iṣẹ́ àánú àti ìtanilọ́rẹ bí i fífún àwọn tí kò ní, ní oúnjẹ àti owó.

Ìgbésẹ̀ yìí, Zakat, jẹ́ ọ̀kan lára òpó márùn-ún tó gbé ẹ̀sìn Islam dúró.

Ọdún ìtúnu ààwẹ, Eid, ló má a ń gbẹ̀yìn Ramadan
Eid al-Fitr, tó túmọ̀ sí ìtúnu ààwẹ, tàbí àsè ìṣínu ààwẹ, má a ń wáyé fún ọjọ́ mẹ́ta tó kẹ́hìn ààwẹ Ramadan.

Ní kété tí wọ́n bá ti rí oṣù tuntun lójú ọ̀run ni ìtúnu ààwẹ má a ń bẹ̀rẹ̀.

Èyí tó mú kí ọjọ́ ìtúnu yàtọ̀ láti orílẹ-èdè kan, sí orílẹ-èdè míìràn ní àgbáyé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ju ọjọ́ kan sí méjì tó má a ń wà láàrin wọn.

Ǹ jẹ́ ní báyìí tí àwọn Mùsùlùmí jákèjádò Orílẹ̀ yìí ti wà ní ìkáraró, ó wá yẹ kí à ṣàmúlò ẹ̀kọ́ inú oṣù ààwẹ̀ ọ̀hún, láti fọ tọkàntara wa mọ́ kangá kúò níbi àwọn ìwà burúkú tó lè tapo sí àṣọ àlà a wa gẹ́gẹ̀ bí i ẹlẹ́sìn mùsùlùmí.
Ó yẹ kí á gbìyànjú nawọ́ ìfẹ́ sí àwọn èèyàn ju tàtẹ̀yìnwá lọ ,yálà ni àyíká a wa tàbí ní àwọn agbègbè mìíràn tí a bá ti gbọ́ pé wọ́n nílò ìrànwọ́,kí à sì sà fún ṣekárími, kí láádá a wa lè kún kẹ́kẹ́.
Kí Ọlọ́run Ọba Àlekèọlá gbàá lẹ́sìn lọ́wọ́ ọ wa.

Ààwẹ̀ Mùsùlùmí bẹ̀rẹ̀ lónìí, Sultan ti Sokoto kédè!

Ààwẹ̀ Mùsùlùmí bẹ̀rẹ̀ lónìí, Sultan ti Sokoto kédè!

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ ìgbìmọ̀ àpapọ̀ fún àwọn ẹlẹ́sìn Islam àti Sultan ti Sokoto, Muhammad Sa’ad Abubakar ti fi àrídájú hàn wí pé wọ́n ti rí Oṣù tuntun nínú àwọn sánmọ́ọ̀ èyiùn Òṣùpá èyí tó ń sàmì ìbẹ̀rẹ̀
Oṣù alápọ̀ọ́nlé tí Ramadan 1444AH.

Nínú atẹjade kan tó jáde lójú òpó abẹ́yẹfò ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó rírí òṣùpá ní Nàìjíríà, Sultan ti Sokoto pé gbogbo Mùsùlùmí jákèjádò Nàìjíríà láti bẹ̀rẹ̀ Ààwẹ̀ gbígbà ní Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, ọdún 2023 .

Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé orílẹ-èdè Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń parí ètò ìdìbò ni, Sultan ti Sókótó tún késí àwọn Mùsùlùmí Nàìjíría láti Sàdúrà fún àṣeyọrí àwọn adarí tuntun tí wọ́n dìbò yàn.

Ìtàn ayé Seyi Makinde, gómìnà kejì tó wọlé fún sáà kejì l‘Ọ́yọ̀ ọ́

Ìtàn ayé Seyi Makinde, gómìnà kejì tó wọlé fún sáà kejì l‘Ọ́yọ̀ ọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Orí tí yóó dádé,ọrùn tí yóó lèjìgbà ìlẹ̀kẹ̀,ìbàdí tí yóó lo mọ́sàajì aṣọ ọba tí í taná yanranyanran, inú agogo idẹ ní ti í wá.
Bíntín ladáhunṣe tó mewéere, gbogbo wa lòpè nípa àkúlẹ̀yàn.
Àṣamọ̀ yìí ló fọhùn fún Gómìnà tuntun àyánrán Mákindé tí ìlú tún fìbò gbé sípò fún sáà kejì ẹni tí wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 1967 sínú ìdílé Pà á Ọlátúbọ̀sún Mákindé àti Madam Abigail Mákindé ti agboolé Àìgbọ́fá ní Oja’ba, Ìbàdàn, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ‘Michael’s Primary School,’ Yemetu nílùú Ìbàdàn àti ‘Bishop Phillips Academy,’ Iwo Road Ibadan.

Ṣèyí Mákindé lọ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì ìpínlẹ̀ Èkó ní Akoka Yaba, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ nípa ẹ̀rọ iná mọ̀nàmọ́ná, ‘Electrical Engineering’ lọ́dún 1990.

Bákan náà ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ nípa àmójútó àwọn ilé-iṣẹ́ ńlá, ‘Industrial Control Services’ ni Houston, Texas lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1998.

Ó tún lọ sílé ẹkọ ìmọ nípa ìdàgbàsókè èsì ìṣirò, ‘Development of Analytical Competence’ ní ilé ẹ̀kọ́ fún i ìdókoòwò ní ìpínlẹ̀ Èkó (tí ó ti di Fásitì àpapọ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀ báyìí) lọ́dún 1999.

Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àyẹ̀wò epo rọ̀bì ilé ẹ̀kọ́ ‘Jiskoot Auto Control Training Centre’, Kent lórílẹ̀ èdè England lọ́dún 2002.

Bákan náà ló lọ ilé ẹ̀kọ́ ìmọ nípa bí a ṣe ń yanjú àwọn ìṣòro ìdókoòwò ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ‘Massachusetts Institute of Technology,’ lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 2005.

Mákindé ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ epo rọ̀bì ‘Shell Petroleum Development Company’ fún ọdún méjì láti 1990 sí 1992 gẹ́gẹ́ bíi Onímọ̀ ẹ̀rọ.

Lẹ́yìn èyí ló ṣiṣẹ́ fún iléeṣẹ́ ‘Rebold International Limited’ gẹ́gẹ́ bíi Onímọ̀ẹ̀rọ àti igbákejì alámòójútó láàrin ọdún 1992 sí 1997.

Lọ́dún 1997 ni Mákindé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aládàáni ti ẹ̀ gangan tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní, ‘Makon Engineering and Technical Services Limited (METS) lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀kan ò jọ̀ kan iléeṣẹ́ epo rọ̀bì fún ọdún márún un gbáko.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí iṣẹ́ àdáni rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Mákindé darapọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ òṣèlú.

Oríṣiríṣi ẹgbẹ́ òṣèlú ló darapọ̀ mọ́, kí ó tó di pé ó di ọmọ oyè fún ẹgbẹ́ òṣèlú ‘People’s Democratic Party (PDP)’ lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn án ọdún 2018.

Mákindé sì ló jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò sí ipò Gómìnà tí ó wáyé lọ́jọ́ kẹtàlélógún oṣù Kejì ọdún 2019, pẹ̀lú ònkà ìbò 515, 621.

Orúkọ aya Ṣèyí Mákindé ni Tamunominini Mákindé. Ìgbéyàwó sì ti ṣàtìwáyé àwọn ọmọ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí orúkọ wọn ń jẹ́, Fèyí, Táyọ̀ àti Tóbi.

Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, Mákindé ló borí ìbò Gómìnà tó wáyé ní ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù kẹta ọdún 2023.

Òun sì ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Kejì tí yóò wọlé fún sáà ìkejì lẹ́yìn Abíọ́lá Ajímọ̀bi tó se sáà Kejì lórí àlééfà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ .
Ìròyìn Òwúrọ̀ kí Gómìnà kú oríire.

Ilẹ̀ rírì ṣọṣẹ́ ní Ecuador, èèyàn 12 kú, ọ̀pọ̀ farapa

Ilẹ̀ rírì ṣọṣẹ́ ní Ecuador, èèyàn 12 kú, ọ̀pọ̀ farapa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èèyàn tí kò tíì kú, kò tíì mọ irú ikú tí yóó pa á.
Kò dín ní ènìyàn méjìlá tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ilẹ̀ rírì tó wáyé ní ẹkùn gúúsù orílẹ̀ èdè Ecuador.

Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ló ti dàwó ní àwọn ìlú káàkiri lẹ́yìn tí ilẹ̀ rírì tó jìn tó ìwọ̀n 6.7 magnitude èyí tó wáyé ní nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ orílẹ̀èdè náà.

Agbègbè El Oro wà lára àwọn ìlú tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti burú jùlọ níbi tí àwọn àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní àwọn ènìyàn ṣì há sábẹ́ àwọn ilé tó dàwó.

Àwọn aláṣẹ ní El Oro ni ènìyàn mọ́kànlá ti pàdánù ẹ̀mí wọn ti ẹnìkan sì kú ní agbègbè Azuay.
Agbegbe Machala àti Cuenca náà wà lára àwọn ìlú tí ọ̀pọ̀ ilé ti dàwó, táwọn ọkọ̀ náà sì bàjẹ́ àmọ́ àwọn tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti lọ ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

Oníṣòwò kan ní Cuenca, Magaly Escandon sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn AFP pé òun sá jáde kúrò nínú ilé òun bọ́ sí ìta nígbà tí òun rí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sá fi ọkọ̀ wọn sílẹ̀.

Ààrẹ Guillermo Lasso rọ àwọn ènìyàn láti ṣe sùúrù kí àwọn aláṣẹ fi mọ iye ìpalára tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti fà.

Iléeṣẹ́ Ààrẹ ní gbogbo àwọn tó farapa nínú ìjàǹbá ọ̀hún ló ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn tí wọn kò sọ ohunkóhun síwájú sí i.

Wọ́n ní ọ̀pọ̀ òpópónà ni àwọn ilé ti dàwó dí ojú ọ̀nà wọn àti pé àwọn ilé ẹ̀kọ́, ilé ìwòsàn ni ìjàǹbá náà ṣe àkóbá fún.

Ilẹ̀ rírì yìí ni èyí tó fẹ́ẹ̀ lágbára jùlọ tó ń wáyé ní Ecuador lẹ́yìn èyí tó wáyé lọ́dún 2016, níbi tí ọgọ́rùn-ún méje ènìyàn ti pàdánù ẹ̀mí wọn tí ọ̀pọ̀ sì farapa.

Àwọn aláṣẹ ní Peru ní àwọn gbúròó ilẹ̀ rírì ní orílẹ̀ èdè ti àwọn náà àmọ́ kò sí ìròyìn bóyá ènìyàn ṣèṣe tàbí pàdánù ẹ̀mí wọn níbẹ̀.

Seyi Makinde jáwé olúborí níbùdó ìdìbó rẹ

Seyi Makinde jáwé olúborí níbùdó ìdìbó rẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́wọ́,Ẹnjiníà Ṣèyí Mákindé ti jáwé olúborí ní ibùdó ìdìbò rẹ̀, níbi tó ti dìbò láàárọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Àpapọ̀ iye ìbò tí Mákindé ni jẹ 174 nígbà tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni ibo 28 níbùdó ìdìbò náà.

Àdúgbò Àbáyọ̀mí, ni ibùdó ìdìbò náà wà ní Iwo road, nílùú Ìbàdàn.

Àṣeyọrí Mákindé níbùdó ìdìbò yìí jẹ́ ìdùnnú nlá fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tó péjú sí ibùdó ìdìbò ọ̀hún.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èsì ìbò tí ń jáde láwọn ibìkan,wọ́n ṣì ń ṣe àkójọpọ̀ àwọn èsì ìbò lọ́wọ́ káàkiri ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láwọn ìbomíràn, ó sì di ìgbà tí gbogbo èsì ìbò náà bá wọlé tán kí àjọ elétò ìdìbò, INEC, tó kéde ẹgbẹ́ òṣèlú tó jáwé olúborí.

Ṣèyí Mákindé ń du ipò Gómìnà fún sáà kẹjì lẹyìn tó ti kọ́kọ́ ṣe ọdún mẹ́rin àkọkọ́ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Àbájáde ìbò láti Ward 11, unit 001, Iwo Road, Ìbàdàn níbi tí Gómìnà Ṣèyí Mákindé ti dìbò:

PDP- 174

APC – 28

ACCORD – 5

LABOR – 3

Gómìnà Mákindé la Adelabu mọ́ iwájú ìta baba rẹ̀

Gómìnà Mákindé la Adelabu mọ́ iwájú ìta baba rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Olùdíje fúnpò Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord Party nínú ìdìbò tó ń lọ lọwọ́, Olóyè Adebayọ Adelabu ti fìdí rẹmi níbùdó ìdìbò rẹ̀.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ẹnjiníà Ṣèyí Mákindé ló là á mọ́lẹ ní gbàdede ìta bàbá rẹ̀ níbẹ̀.

Ibùdó ìdìbò kẹwàá, ní wọ́ọ̀dù kẹsàn-án, lágboolé Oluokun, ní Kudẹti, nijọba ìbílẹ̀ Ila-Oorun Gúúsù Ìbàdàn, nígboro Ìbàdàn tí í ṣe agboolé tí wọ́n bí Adelabu sí náà ló ti máa ń dìbò.

Gẹ́gẹ́ bí aṣojú àjọ elétò ìdìbò nílẹ̀ yìí, INEC ṣe kéde ẹ,ọ̀kàndínláàdọ́rin (69) ìbò ni Mákindé ní. Ṣùgbọ́n èèyàn méjìdínlógójì (38) péré ló dìbò fún Adelabu tó jẹ́ ọmọ agboolé ọ̀hún nígbà tí Sẹ́nẹ́tọ̀ Teslim Fọlarin, olùdíje lórúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, tó ṣe ipò kẹta ní ìbò méjìlélógún (22) níbudó ìdìbò náà.

Bí Gómìnà Mákindé ṣe la Adelabu mọ́lẹ̀ nínú ìdìbò Gómìnà ọdún 2019 náà ló tún lù ú mọ́ iwájú ìta bàbá ẹ nínú ìdìbò ọdún 2023 tó wáyé lónìí ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta tá a wà yìí.

Bákan náà ni Gómìnà yìí tún fàgbà han gbogbo àwọn tí wọ́n bá a du agbára ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ níbi tí òun fúnra rẹ̀ ti máa ń dìbò níbudó ìdìbò kínní, wọọdu kọkànlá níjọba ìbílẹ̀ Ìlà-Oòrùn Àríwá Ìbàdàn.

Èèyàn mẹ́rìnlèláàádọ́sàn-án (174) ló dìbò fún Gómìnà tí wọ́n tún ń pé ní GSM yìí níbudó ìdìbò náà. Fọlarin, ẹni tó pọwọ́ lé e níbudó ìdìbò ọ̀hún ní ìbò méjìdínlọgbọn (28) péré nígbà tí ìbò Adélabú tó ṣe pò kẹta kò ju ẹyọ márùn-ún péré lọ.

Ikú dóró! ìgbákejì Gómìnà tó ṣẹṣẹ fipò sílẹ̀ jáde láyé

Ikú dóró! ìgbákejì Gómìnà tó ṣẹṣẹ fipò sílẹ̀ jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àìsàn la rí wò, àwọn àgbà sọ pé kò séèyàn tó rí ti ọlọ́jọ́ ṣe.
Lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́ tí wọ́n ló ṣe é, Ìgbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, lábẹ́ ìṣèjọba Káyọ̀dé Fáyẹmí tó ṣẹṣẹ kógba wọlé, Ọ̀túnba Bisi Ẹgbẹyẹmi, ti kú lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin.

Oun tí a gbọ́ ni pé ó ti tó ọjọ́ mẹ́ta tó ti tẹ bàbá tó ti fìgbà kan jẹ alága ìjọba ìbílẹ̀ Ado-Ekiti náà díẹ̀, tí wọ́n sì gbé e lọ sí ọsibítù aládàáni kan tí wọ́n ń pè ní Multisystem Hospital, nílùú Ado-Ekiti, tí í ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ ọhún fún ìtọ́jú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó mọ irú àìsàn tó ń ṣe bàbá náà, ó padà kú sí ọsibítù ọ̀hún ní òru ọjọ́ Ẹtì mọ́jú àárọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹta yìí.

Láàrin ọdún 2018 sí 2022 ni ọkùnrin tó jẹ́ agbẹjọ́rò, tó sì tún jẹẹ́ olóṣèlú náà fi ṣe igbákejì gómínà lábẹ́ ọ̀gá rẹ̀, Ọ̀mọ̀wé Káyọ̀dé Fáyẹmí.

Ọjọ́ kẹjọ, oṣù Karùn-ún, ọdún 1944 ni wọ́n bí ọkùnrin ọmọ bíbí ìlú Ado Èkìtì ọ̀hún.

Wọn kò tí ì kéde ikú ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n àwọn tó sún mọ bàbá náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọkùnrin náà ti rewalẹ àṣà.

Wọ́ọ̀dùWọ́ọ̀dù ! Ìdìbò sípò Gómìnà àti ìlé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní rẹbutu káàkiri ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Wọ́ọ̀dùWọ́ọ̀dù ! Ìdìbò sípò Gómìnà àti ìlé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìbílẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní rẹbutu káàkiri ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó fojúhàn pé nǹkan yàtọ̀ díẹ̀ lásìkò yìí níbi Ìdìbò sípò Gómìnà àti ìlé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí, yàtọ̀ sí bí àwọn èèyàn ṣe ń fi apa jánú lásìkò ìbò ÀàrẹOrílẹ̀ yìí tí a dì kọjá.
Àkọ́kọ́,àwọn òṣìṣẹ́ INEC tètè dé ibùdó ìdìbò.
Ẹ̀ẹ̀kejì, àwọn olùdìbò jádé láwọn Wọ́ọ̀dù káàkiri tí aṣojú kọ̀ròyìn Òwúrọ̀ dé.
Ẹ̀kẹta, àgbáríjọpọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò dúró gírí láwọn ibùdó ìdìbò gbogbo.
Ẹ̀kẹrin, àwọn olùdìbò kò sọ pé ẹ̀rọ tó yàwòrán àti dátà kò ṣiṣẹ́ .
Ọ̀kan tí a ò tíì lè fi ìdí i rẹ̀ múlẹ̀ ni pé , ṣé àwọn òṣìṣẹ́ tí àjọ náà lò rí ẹ̀tọ́ ọ wọn gbà. Ṣùgbọ́n ìròyìn Òwúrọ̀ yóó tọpinpin èyí náà , ní kété tí ètò ìdìbò bá ti kásẹ̀ ńlẹ̀.
Ẹ máa tẹ̀lé wa, pẹ̀lú ojúlówó ìròyìn, a ò ní-ín jáayín kulẹ̀.