Ìṣèjọba alawọ dúdú, àwọn orílẹ̀ èdè kan nìyí tí Ààrẹ wọn ti lò tayọ ọgbọ̀n ọdún nípò

Ìṣèjọba alawọ dúdú, àwọn orílẹ̀ èdè kan nìyí tí Ààrẹ wọn ti lò tayọ ọgbọ̀n ọdún nípò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹnìkan ṣoṣo kò dùn tó ní yànmùyànmù ekìrí ọ̀yà. Ó túmọ̀ sí pè èèyàn kan kìí jẹ kílẹ̀ ó fẹ́.Jẹ́ kí n jẹ́ ní-ín máyò dùn.
Sùgbọ́n ìwádìí àti àkọsílẹ̀ ti fojúhàn pé ìṣesí àwọn dúdúláwọ̀ mú ìwọ̀ra dáni.Èyí kò sì jẹ́ kí lámùúyẹ lábala ètò
ẹ̀kọ́ lápapọ̀, ọrọ̀ ajé, ètò ìṣèlú, ètò ọ̀gbìn, abbl. Ẹ tẹ̀síwájú.

Kó sí àwítúnwí mọ́,Gabon ni orílẹ̀ èdè tuntun tí àwọn ológun ti kéde pé àwọn ti gbàjọba níbẹ̀ lásìkò yìí tí àwọn ológun ń gbàjọba kiri ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Ní orí amóhùnmáwòrán ni àwọn ológun náà ti kéde l’Ọ́jọ́rú pé àwọn ti gbàjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Ali Bongo.

Ikede wọn waye lẹyin ti wọn ti wọ́gilé èsì ìdìbò tó wáyé lọ́rílẹ̀ èdè náà lópin ọ̀sẹ̀ níbi tí wọ́n ti kéde Ali Bongo gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ìbò náà.

Ọdún kẹrìndínlọ́gọ́ta tí ẹbí Ali Bongo ti ń jẹ Ààrẹ Gabon.

Bongo di ààrẹ Gabon lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ jáde láyé lẹ́yìn tó ṣe ààrẹ orílẹ̀ èdè náà láti ọdún 1967 sí ọdún 2009 tó sì lo ọdún 42 lórí ipò.

Ẹ̀wẹ̀, Ali Bongo kọ́ ni Ààrẹ tó ti lo ọdún pípẹ́ lórí ipò pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn nílẹ̀ Adúláwọ̀.

Teodoro Obiang Nguema Mbasogo – Equatorial Guinea

Teodoro Obiang Nguema Mbasogo tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin ni Ààrẹ tó ti pẹ́ lórí ipò jùlọ ní àgbàyé pẹ̀lú bó ṣe ti pé ọdún mẹ́rìnlélógójì lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.

Láti ọjọ́ Kẹta oṣù Kẹjọ ọdún 1979 ló ti wà lórí ipò bíi ààrẹ Equatorial Guinea, òun sì ni ààrẹ kejì tí yóò jẹ ní orílẹ̀ èdè náà.

Ní oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni wọ́n tún kéde pé Obiang ló tún jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó wáyé ní orílẹ̀ èdè náà.

Ní àgbáyé, òun ni Ààrẹ Kejì tó ti pẹ́ lórí oyè láì kìí ṣe ìdílé olóyè.

Ọmọ Obiang, Teodoro Nguema Obiang Mangue ni igbákejì rẹ̀, tó sì sọ lẹ́yìn ìbò oṣù Kọkànlá náà pé ẹgbẹ́ àwọn ń ṣe dáadáa ni ọ̀pọ̀ ènìyàn tún fi dìbò fún àwọn.

Ààrẹ Obiang di orílẹ̀ èdè Equatorial Guinea mú ṣinṣin, tí àwọn ẹbí rẹ̀ sì di ipò gidi mú ní orílẹ̀ èdè náà.

Paul Biya – Cameroon

Paul Biya ni ààrẹ orílẹ̀ èdè Cameroon tó sì ti wà lórí ipò náà láti ọdún 1982.

Ogójì ọdún ni Paul Biya ti lò lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Cameroon.

Ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kejì ọdún 1933 ni wọ́n bí Biya, òun sì ni ààrẹ tó dàgbà jù ní ẹkùn Áfíríkà.

Ní ọdún 2018 ni wọ́n dìbò yan Paul Biya fún sáà Keje ní ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.

Ìròyìn ní àwọn ènìyàn k]o fi bẹ́ẹ̀ jáde dìbò lásìkò ètò ìdìbò náà.

Ẹgbẹ́ alátakò pè fún àtúndì ètò ìdìbò ọ̀hún àmọ́ ilé ẹjọ́ da ìpè náà nù.

Biya gba ipò Ààrẹ Cameroon lọ́wọ́ Ahmadou Ahidjo tó jẹ́ olóòtú ìjọba àti ààrẹ àkọ́kọ́ fún Cameroon, tó sì jẹ láàárín oṣù Kẹfà ọdún 1975 sí oṣù Kọkànlá ọdún 1982.

Ní ọdún 2025 ni ètò ìdìbò mìíràn yóò tún wáyé ní Cameroon.

Denis Sassou Nguesso – Republic of the Congo

Denis Sassou Nguesso ni ààrẹ Congo- Brazzaville, ẹni tó padà sípò lkyìn tí wọ́n tún ìwé òfin orílẹ̀ èdè náà kọ ní èyí tó fi ààyè gbà á láti dupò fún sáà Kẹta lọ́dún 2016.

Ní ọdún 1979 sí 1992 ló ti kọ́kọ́ jẹ ààrẹ orílẹ̀ èdè náà kọ tọ fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò tí wọ́n ṣe lọ́dún náà.

Ọdún 1997 ló tún díje padà tó sì ti wà lórí ipò láti ìgbà náà.

Ọdún méjìdínlógójì ni Denis Sassou Nguesso ti lò lórí ipò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Republic of Congo báyìí.

Wọ́n mú àyípadà bá ìwé òfin orílẹ̀ èdè náà níbi tí wọ́n ti yọ ọjọ́ orí àti iye ìgbà tí ènìyàn ti ṣe ìjọba rí gẹ́gẹ́ bí ohun ìdènà láti dupò Ààrẹ.

Nguesso tó i pé ọgọ́rin ọdún báyìí ṣì ń gbèrò láti díje dupò ààrẹ fún ìgbà karùn-ún.

Yoweri Museveni – Uganda

Ọdún mẹ́rìndínlógójì rèé tí Yoweri Museveni ti wà nípò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Uganda.

Museveni ni Ààrẹ Kẹsàn-án tó máa jẹ ní Uganda, tí wọ́n sì bi ní ọdún 1944 tó sì ti pé ọmọ ọdún méjìdínlọ́gọ́rin.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ, ìròyìn ní ìgbà rẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdàgbàsókè bá orílẹ̀ èdè rẹ̀ tí ìgbà rẹ̀ sì tu àwọn ènìyàn lára.

Fún àwọn ènìyàn Uganda, òun ni bàbá àti bàbábàbá wọn.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló máa ń pè é ní “Sevo” tí òun náà sì máa ń dàhún pẹ̀lú Bazukulu, èyí tó túmọ̀ sí ọmọọmọ ní èdè Uganda.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here