Ajé wọgbó! Iná ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá jẹ́ lọ́jà Ogunpa, n’Íbàdàn

Ajé wọgbó! Iná ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá jẹ́ lọ́jà Ogunpa, n’Íbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀pọ̀ dúkìá ti owó wọn tayọ mílíọ̀nù Náírà ló sègbé sínú ìjànbá iná tó wáyé lọ́jà Ogunpa, Lábọ-Owó, tó wà lágbègbè Àgbókojó, nílùú Ìbàdàn.

Òru mọ́jú ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejìdílógún oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 yìí, làwọn ará ọjà yìí ṣàdéédé rí i tí iná ọhún ti fẹjú kẹkẹ, láìmọ ohun tó ṣokùnfà ìjànbá náà.

Gbogbo akitiyan àwọn ará ọjà yìí láti pa iná ọhún kò tunrun títí tí ọpọlọpọ dúkìá fi jóná tán gbúrúgbúrú.

Lára àwọn ọhún tó jónà ni bẹ́ẹ̀dì, àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń tún ọkò ṣe àtàwọn nǹkan mí-ìn.

Alága ẹgbẹ́ àwọn mẹkálíìkì lọjà Ogunpa Labowo, Ọgbẹni Azeez Ibrahim, fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdájí ọjọ́ Jimọ làwọn tíṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sọ pé iná ọhún bẹ̀rẹ̀

Ó ní ó ṣeé ṣe kó jẹ́ iná tí àwọn ilé-iṣẹ́ amúnáwá mú dé lójijì ló fa sábàbí.

Ó wá rọ ìjọba láti ṣíjú àánú wo gbogbo àwọn tí dúkìá wọn sòfò látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Títí di bá a ṣe ń sọrọ yìí, làwọn tó pàdánù ọjà àti dúkìá wọ́n sínú ìjànbá ọ̀hún ṣì ń ṣírò iye owó wọn tó ṣofo sínú àjálù ọhún. Kí Edùmàrè Ó fòfò rẹ̀mí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here