Osere fiimu pataki, Opeyemi Ayeola, ti so pe ninu idanwo oniwe mewaa ti opo eniyan n pe ni WAEC, oun ko paasi Ede Yoruba, bi o tile je pe o se daadaa ninu awon ise miiran.
Nigba ti onifiimu naa n soro lori bi kadara ati Olorun se je ko ni aseyori ninu ise fiimu lo so oro yii.
Nigba ti ile ise Radio Lagos gba a lalejo lori eto OJUTAYE, Opeyemi Ayeola so hulehule bi o se bere ise fiimu, awon ise to ti se, aseyori to ti ni ati awon wahala to ti la koja.
O ni oun ati awon obi oun ko rokan pe ere fiimu ni oun maa se la laye oun.
O ni koda bi magiiki lo ri nigba ti won ko ni ki oun kopa ninu ere PAPA AJASCO.
Opeyemi Ayeola salaye pe ninu ise ere onise, Olorun o maa n duro ti eniyan, sugbon ikora eni nijanu naa se pataki.
O ni gege bi obinrin, ko si ki okunrin ma maa sufee pe eniyan, sugbon eni oro ba kan lo gbodo mo ohun to n se.
IROYIN YI WA LATI INU IWE IROYIN IROYIN OWURO TO TI JADE TELE…