Home Blog Page 2

Kìí ṣe gómìnà ló máa yan ọba fún wa— Ọ̀tún Olúbàdàn

Kìí ṣe gómìnà ló máa yan ọba fún wa— Ọ̀tún Olúbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní ẹ̀là lọ̀rọ̀, bá ò bá làá, kì í yéni dáa dáa.
Pẹ̀lú Awuyewuye tó ń wáyé lórí ọ̀rọ̀ ta lọ́kàn láti gun orí ìtẹ́ Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn.
Olóyè Adéwọ̀lú Ládojà tó jẹ́ ọ̀tún Olúbàdàn ti fèsì sí ọ̀rọ̀ tí olóyè àgbà Ọba Ajíbólá sọ pé ara ọba Ọlákùlẹ́yìn tí oyè Olúbàdàn tọ́ sí kò le dáadáa.

Ó sọ pé àwọn onímọ̀ nípa ètò ìlera nìkan ni wọ́n ní ànfàní láti sọ nípa ìlera ẹníkẹni.

Ladoja ní amòfin ni ọba Ajibola, kìí ṣe onímọ̀ nípa ètò ìlera nítorí náà kò sí ohunkóhun tó se ara ọba Ọlákùlẹ́yìn, koko lara baba le.
Ó tún fi kún un pé ọba Ọlákùlẹ́yìn kìí ṣe ọmọ ọgbọ̀n ọdún, ẹni tó ju ọmọ ọgọ́rin ọdún lọ ni kò sì ṣeé ṣe kí ara rẹ̀ dà bíi ọmọ ogún ọdún.

Ó ní “arúgbó náà ti ṣoge rí àti pé ọmọ ológun ni bàbá nígbà tó wà ní èwe, ẹjẹ́ ká gbàgbé wípé ara Olúbàdàn kò yá .”

Ọ̀tún Olúbàdàn fi kún un pé “ láti ọdún 1983 ni ọba Olákùlẹ́yìn tí ń gun àkàsọ̀ yii bọ̀ láti joyè Olúbàdàn ṣùgbọ́n Ọlọ́run nìkan ló ń fi ọba jẹ.

“ Nítorí a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó wà ní ipò ọba Ọlákùlẹ́yìn yìí ṣùgbọ́n tí wọn kò dé ipò Olúbàdàn, tí Ọlọ́run bá kà wọ́n yẹ láti dé bẹ̀ kò sí ẹnikẹ́ni tí yóó díi lọ́nà èròńgbà rẹ̀.

“Ohun tí òfin ṣọ ni pé a gbọ́dọ̀ yan ọba tuntun láàrin ọgbọ̀n ọjọ́ nítorí ìdí rẹ̀ ni ìpàdé yóò fi wáyé ní ọ̀la.

“ Lẹ́yìn náà a máa lọ gbé orúkọ ẹni tí a bá yàn fún Gómìnà láti buwọ́lù, kìí ṣe Gómìnà ló máa yan ọba fún wa ṣùgbọ́n Gómìnà ní àṣẹ láti ní kí a lọ mú ẹlòmíràn wá tí ẹni tí a yàn kò bá yẹ lóyè .”

Ẹgbẹ́ òṣèré fòfin dé àwọn kan lẹ́yìn ikú Junior Pope

Ẹgbẹ́ òṣèré fòfin dé àwọn kan lẹ́yìn ikú Junior Pope

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn òṣèré ìyẹn Actors Guild of Nigeria (AGN), Emeka Rollas Ejezie ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òṣèré tíátà Obumneme Odonwodo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Junior Pope ti jáde láyé.

Rollas fìdí ìpapòdà Junior Pope múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí Facebook lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹrin.

Ṣáájú ni Rollas ti kọ́kọ́ kéde pé Junior Pope ṣì wà láyé lẹ́yìn tí ìròyìn ikú rẹ̀ gba orí ayélujára.

“Kò sí ohun tí Ọlọ́run kò lè ṣe. Junior Pope wà láyé. Ó ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn,” Rollas kọ sí ojú òpó ayélujára rẹ̀.

Àmọ́ nínú àtẹ̀jáde tuntun tó fi sórí Facebook, Rollas ní ìdùnnú tó wọ òun lẹ́wù nígbà tí Junior Pope gbé apá ló jẹ́ kí òun fi ìkéde náà síta.

Ó ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún àwọn pé ayọ̀ àwọn kò pé tí àwọn tún fi gba ìròyìn ìbànújẹ́ mìíràn.

“Ìdùnnú ló mú mi kọ́kọ́ fi ìkéde mi síta nígbà tó mi ọwọ́. Ilé ìwòsàn méjì ni wọ́n ti gbìyànjú láti jí Junior Pope àmọ́ pàbó ló já sí.”

“A ti padà pàdánù rẹ̀.”

Ó ṣàlàyé pé àwọn ti rí òkú ọ̀gbẹ́ni Friday àmọ́ àwọn ṣì ń wá àwọn èèyàn mẹ́ta mìíràn.

Ṣáájú ni ìròyìn ti gba orí ayélujára pé ọkọ̀ ojú omi tí Junior Pope wọ̀ rì sínú odò River Niger nígbà tí òun àtàwọn míì ń bọ̀ láti oko eré.

Lẹ́yìn náà ni ìròyìn míì tún gba orí ayélujára pé nígbà tí wọ́n gbé Junior Pope mọ́ṣúárì ni àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ní ẹ̀mí ṣì wà lára Junior Pope.

Yàtọ̀ sí Junior Pope, àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́rin ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá náà, tí wọ́n sì ti rí òkú èèyàn kan láàárín wọn.

Ẹgbẹ́ AGN gbé ìgbésẹ̀
Ẹgbẹ́ àwọn òṣèré, AGN ní àwọn ti fòfin dè ṣíṣe eré ní etí odò tàbí lórí omi látara ìjàm̀bá tó wáyé náà.

Bákan náà ni wọ́n sọ pé kí wọ́n má ya eré fíìmù kankan ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kọkànlá, oṣù Kẹrin láti fi ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn.

AGN ní àwọn ti fòfin dè fíìmù “Another Side of Life”. Fíìmù yìí ni Junior Pope àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lọ yá ní ìpínlẹ̀ Delta kí wọ́n tó ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn.

Àtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ fi léde tún fi kún pé òṣèré kankan kò gbọdọ̀ bá Adamma Luke ṣiṣẹ́ títí di ìgbà kan ná. Adamma Luke ni ó ni eré tí àwọn Junior Pope lọ ṣe.

Wọ́n gbàdúrà kí Ọlọ́run tẹ́ àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sí afẹ́fẹ́ rere bí wọ́n ṣe ń wá òkú àwọn tó ṣì nínú odò tí wọ́n rì sí.

Ní ọjọ́ tí ìjàm̀bá okọ̀ ojú omi náà wáyé ni Junior Pope fi fídíò kan sórí ayélujára nípa bí àwọn òṣèré ṣe máa ń fi ẹ̀mí ara wọn wéwu láti wá oúnjẹ oòjọ́ wọn.

Fídíò náà ń ṣàfihàn bí Junior Pope àtàwọn yòókù rẹ̀ ṣe wà nínú ọkọ̀ ojú omi lórí odò River Niger láì wọ aṣọ ààbò.

Ó ń sọ nínú fídíò náà pé òun ní ọmọ mẹ́ta, òun sì ni yóò tọ́jú wọn, tí òun máa rè wọ́n dàgbà.

Níbẹ̀ ló ti ń bẹ awakọ̀ ojú omi náà pé kó ṣe jẹ́jẹ́ nítorí òun nìkan ni àwọn òbí òun bí.

Makinde gbarata pé òṣìṣẹ́ wọléwọ̀de lu àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú pópó Ọ̀yọ́ ní àlùbami

Makinde gbarata pé òṣìṣẹ́ wọléwọ̀de lu àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú pópó Ọ̀yọ́ ní àlùbami

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn òṣìṣẹ́ iléeẹẹ́ tó ń rí sí ètò ìwọlé àti ìjáde ní Nàìjíríà ìyẹn National Imigration Service tẹ̀ka Zone F ṣe ṣèkọlù sí òṣìṣẹ́ tó ń mójútó ètò ìrìnnà ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (OYRTMA).

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde tó korò ojú sí ìkọlù náà ní yóò bá agbẹjọ́rò àgbà ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ tako àwọn tó ṣe ìkọlù sí òṣìṣẹ́ náà.

Makinde ní òun máa ri dájú pé àwọn gbé ìgbésẹ̀ òfin láti fi rí ìdájọ́ òdodo gbà.

Ṣáájú ni ìròyìn gbòde pé àwọn òṣìṣẹ́ Immigration kan ni wọ́n fìyà àìtọ́ jẹ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ OYRTMA nítorí tí wọ́n dáwọn dúró nígbà tí wọ́n gba ọ̀nà tí kò tọ́.
Ní agbègbè afárá Onipepeye Bridge Underpass lọ́nà Old Ife Road, Ibadan ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, tí àwọn òṣìṣẹ́ Immigration ọ̀hún lu àwọn òṣìṣẹ́ OYRTMA bí ejò àìjẹ látàrí pé wọ́n fi kélé òfin gbé wọn.

Gómìnà Makinde, nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sáwọn òṣìṣẹ́ OYRTMA tí wọ́n fìyà jẹ náà lọ́jọ́ Ajé ní ìwà àìtọ́ ni àwọn òṣìṣẹ́ Immigration náà hù àti pé àwọn kò ní fi àyè gba irú rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rárá.

Ó ní ohun tí òun fẹ́ kí wọ́n mọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún ni bíbọ̀wọ̀ fún òfin àti ìlànà, títẹ̀lé òfin ìrìnnà láì ipò tàbí ọlá ṣe.

Ó ní kò sí ẹni tó kọjá òfin àti pé ìjọba má gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí ìkọlù náà.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé jíjẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ kò túmọ̀ sí pé kò yẹ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún òfin tàbí ga ju àwọn ènìyàn yòókù lọ láwùjọ.

“A máa kọ̀wé ránṣẹ́ Sáwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ Immigration nítorí a kò lè gba èyí ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.”

Makinde tún ṣe àbẹ̀wò sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ Immigration ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tó wà ní Agodi Gate, Ibadan níbi tó ti bá ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà látu ri dájú ìbáṣepọ̀ tó lóòrìn wà láàárín àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò gbogbo ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó sọ fún ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà, Abdurasheed Ademola pé kí wọ́n ri dájú àwọn òsìṣẹ́ tó ṣe ìkọlù náà fojú winá òfin àti pé irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ kò wáyé lọ́jọ́ iwájú.

Portable olórin Zazu jèrè agárán, Benz bóṣe ṣòwò èébú lára Bobrisky

Portable olórin Zazu jèrè agárán, Benz bóṣe ṣòwò èébú lára Bobrisky

Fẹ́mi Akínṣọlá

Onírúrurí àwòràn ní ojú n rí báyìí bó ṣe jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ ayé súnmọ́.Ọ̀kan tó súnmọ́ ni bi akọrin Zazu, Habeeb Okikiọla (Portable) ṣe sáré wọ ilé orin tó sì po orin pọ̀ tako Bobrisky, ọkùnrin tó n ṣe bíi obìnrin, ti fún un lánfààní mọ́tò ayọ́kẹ́lẹ́ Benz báyìí.

Fúnra Portable ló sọ èyí di mímọ̀ lásìkò tó wà lóko eré kan pẹlú Ẹniọla Ajao, òṣèrébìnrin tó ṣe sinimá Àjàkájú tó dá awuyewuye sílẹ̀ láìpẹ yìí.

Portable ti wọ́n tún ń pè ní Ìdààmú àdúgbò, sọ pé, ‘’ Nítorí Ẹniọla Ajao ni. Fíìmù rẹ̀, Àjàkájú, dá wàhálà sílẹ̀, èmi dẹ gba mọto Benz nítorí mo sọ wàhálà náà d’orin.’’
Ẹniọla Ajao ló ṣàfihàn sinimá rẹ̀ tó sì pe Bobrisky (Idris Okunẹyẹ Ọlanrewaju) síbẹ̀ .

Níbi ètò náà ni wọ́n ti ní Bobrisky ni ìmuúra rẹ̀ gba ipò Kìn-ín-ní nínú àwọn obìnrin tó wà lóde náà.

Èyí ló di wàhálà, tó dohun tí àwọn òṣèré bíi Dayọ Amusa àti Fẹmi Adebayọ ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára.

Bákan náà lọpọ èèyàn koro ojú sí bí wọ́n ṣe fún Bob to jẹ́ ọkùnrin lami-ẹyẹ obìnrin, nígbà tí àwọn elétò náà mọ pé akọ tó ń múra bíi obìnrin ni.

Ẹniọla Ajao tó ni eré ọ̀hún pàápàá kabaamọ pé òun fún Bobrisky lámì ẹ̀yẹ àti mílíọ̀nù kan náírà tó tẹlé ami-ẹyẹ náà.

Ó sunkún lórí ayélujára, ó sì tọrọ àforíjìn lọwọ́ àwọn èèyàn.

Bí wàhálà náà ṣe ń lọ lọwọ́ ni Bobrsisky náà ń sọ pé àwọn obìnrin kò rọgbọn ẹ̀ dá, àfi kí wọ́n gba òun sáàrin wọn.

Ó lóun ti ṣe ìdí, òun ṣe ọyàn, òun sì ti yọ nǹkan ọkùnrin kúrò lábẹ́ òun, ti obìnrin ló wà níbẹ̀ .

Ikú! Ìràwọ̀ òṣèrè e tíátà kan tún ti wọ̀ọ̀kùn òjijì

Ikú! Ìràwọ̀ òṣèrè e tíátà kan tún ti wọ̀ọ̀kùn òjijì

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àrùn la rí wò, a ò rí ti ọlọ́jọ́ ṣe.
Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn òṣèré tíátà ilẹ̀ wa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìdelẹ̀bọ̀, Adejumọkẹ Aderounmu, arẹwà òṣèrébìnrin tó kópa “Esther” nínú eré àtìgbàdégbà tí Funkẹ Akindele ṣe, tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Jenifa Diary, ti jáde láyé, lẹ́ni ogójì (40) ọdún!

Ọkan ninu awọn mọlẹbi oṣere ọhun, Adeọla Aderounmu, lo kede iku rẹ lori ayelujara laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin ta a wa yii.
Oun ti a gbọ ni pe, ko tii sẹni to mọ pato ohun to ṣokunfa iku ojiji fun oṣere naa. Lori ọkan lara awọn ikanni ayelujara nibi ti wọn ti kede iku awẹlẹwa yii, ni wọn kọ ọ si pe: “Ọkan ninu awọn mọlẹbi irawọ oṣere to fakọyọ ninu ere atigbadegba Jenifa Diary, Jumọkẹ Aderounmu, ti kede pe onitiata to n goke agba bọ yii ti ku. A o tii mọ hulẹhulẹ nipa iku rẹ. Ki Ẹlẹdaa rẹ fun ẹmi ẹ lalaafia.”

Nigba aye rẹ, Jumọkẹ Aderounmu wa lara awọn oṣere-binrin ti wọn forukọ rẹ silẹ lati gba ẹbun oṣere to fakọyọ ju lọ lọdun 2013, nibi ayẹyẹ International Film Festival, to waye niluu Dallas, lorileede Amẹrika.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 1984 ni Adejumọkẹ dele aye, o si jade laye lọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin ọdun yii, nileewosan aladaani kan, ti wọn ko darukọ rẹ.

Ọmọ bibi ilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun ni, ibẹ lo si ti bẹrẹ ere tiata lẹyin to pari ẹkọ fasiti rẹ, amọ ọdun 2016 to kopa to jọju ninu ere Jenifa Dayari ni irawọ rẹ bẹrẹ si i tan.

Bakan naa lo kopa Yejide ninu ere elede oyinbo ti wọn pe akọle rẹ ni Dazzling Mirage, o si wa ninu awọn to fakọyọ ninu Industreet ati Alakada 2.

Àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ arò àti ìbánikẹ́dùn nípa ikú òṣèrébìnrin ọ̀hún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé fọ́tò àti fídíò rẹ̀ kan sójú òpó ayélujára wọn láti fihàn pé ìpapòdà a rẹ̀ jẹ́ ìbànújẹ́.

Wọ́n ti yọ Igbákejì Gómìnà Edo, Philip Shuaib, nípò

Wọ́n ti yọ Igbákejì Gómìnà Edo, Philip Shuaib, nípò

Ọrẹ Òtítọ́jù
A fi bí àlá ojú oorun lọ̀rọ̀ dà bí Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Edo ti fòùntẹ̀ jan àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ tó gbọ́ àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Ọgbẹni Philip Shuaibu, bí wọn ti yọ ọkùnrin ọhún kúò nípò fódá.

Awọn aṣofin naa dori ipinnu yii lasiko ijokoo wọn laaarọ ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Ṣaaju ni wọn ti kọwe awọn ẹsun kan ta ko Shuaibu, ti kọmiṣanna feto idajọ ipinlẹ naa si yan igbimọ ẹlẹni meje kan, eyi ti Adajọ-fẹyinti S. A. Omonua, jẹ alaga rẹ.

Lara awọn ẹsun ti wọn ka si ọkunrin naa lẹsẹ ni pe o tu awọn aṣiri ijọba kan ti ko yẹ ko tu sita, wọn si tun lo ṣe awọn owo kan baṣubaṣu lọfiisi rẹ.

Amọ gẹgẹ bi Omonua ṣe sọ lasiko to n jabọ iwadii ati aba wọn fawọn aṣofin naa lọjọ Ẹti, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin yii, o ni awọn kọwe si igbakeji gomina ọhun lati waa sọ awijare rẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an, ṣugbọn Philip Shuaibu ko yọju, ko si ran aṣoju kankan wa.

Adajọ naa ni: “Koda, titi di oni yii, a tun mọ-ọn-mọ sun ijokoo wa siwaju lati fun Shuaibu lanfaani ‘waa-wi-tẹnu-ẹ’ sibẹ, niṣe lo dagunla patapata.

Ṣaaju asiko yii ni agbẹjọro fun igbakeji gomina ọhun, Amofin agba Ọjọgbọn Ọladoyin Awoyale, ti kọwe pe onibaara oun ko ni i le ba wọn kopa kankan ninu ijokoo igbẹjọ naa latari aṣẹ ile-ẹjọ giga apapọ ilu Abuja kan to kede pe ki gbogbo awọn tọrọ naa kan ṣi ṣe afaro lori ẹsun ọhun na. Wọn ni ki ijokoo iyọnipo kankan ma ti i waye, Awoyale si rọ igbimọ naa lati bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ giga yii titi di ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin yii, ti igbẹjọ yoo tẹsiwaju ni kootu, amọ wọn ko ṣe bẹẹ.

Ọjọ Mọnde ọhun lawọn aṣofin fountẹ jan abọ iwadii, ti wọn si buwọ lu iyọnipo Shuaibu.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọpọ oṣu sẹyin ni lọgbọlọgbọ ti n lọ labẹnu laarin Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki, ati igbakeji rẹ latari awọn aigbọra-ẹni-ye kan.

Ina ija naa tubọ gbilẹ nigba ti igbakeji gomina kede pe oun yoo dije-dupo gomina ninu eto idibo to n bọ loṣu Kọkanla, ọdun yii, amọ ọga rẹ kọ lati ṣatilẹyin fun un.

Látìgbà náà ni ẹ̀kọ ò ti ṣojú mímu láàrin wọn, bí èkúté àti ológbò ni ìṣesí wọn látìgbà yìí wá.

Tinubu ní láti dá owó iná mọ̀nàmọ́ná padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ –Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re.

Tinubu ní láti dá owó iná mọ̀nàmọ́ná padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ –Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re.

Gbọ́láhàn Quseem

Ẹgbẹ́ tó n s’ojụ́ àwọn ọmọ Yorùbá ni Nàìjíríà, Afẹnifẹre, ti korò ojú sí àfikún owó iná mọ̀nàmọ́ná tí ìjọba Ààrẹ Bólá Tinubu ṣe fáráààlú ní lọ́ọ́lọ́ yii.

Wọn ni ki Aarẹ da owo naa pada si bo ṣe wa tẹlẹ.Atẹjade kan ti Afẹnifẹre fi sita, eyi ti agbẹnusọ wọn, Jare Ajayi, buwọ lu lo sọ eyi di mimọ.

Afẹnifẹre ṣalaye pe ileeṣẹ apinnaka, Nigerian Electricity Distribution Company (NERC) n fi aikunju oṣuwọn tiwọn ni awọn ọmọ àti olugbe Naijiria lara pẹlu afikun owó ‘nà naa.

“Ọmọ Nàìjíríà ń jìyà yíyọ tí ‘wó ìrànwọ́ órí epo, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni wọn ó tún jìyà iná mọ̀nàmọ́ná”

Afẹnifẹre ṣalaye pe nigba t’ ijọba yọ owọ iranwọ rẹ kuro lori owo epo, araalu ti ko mọwọ-mẹsẹ lo n jiya rẹ bayii.

“Araalu to fẹẹ lo ohun tawọn to n sanwo gọbọi lori ina ba ṣe ni yoo jiya afikun owo ina yii, gẹgẹ bo ṣe ri lori owó e ìrànwọ́ epo t’ ijọba yọ.

‘’Awọn ileeṣẹ yoo fikun ohun ti wọn ba n pese sita, awọn eeyan to fẹẹ ra ni inira yoo si ba.

‘’ Ina ti araalu o ri lo tẹ ẹ tun n fowo kun. NERC kan fẹẹ k’awọn eeyan Naijiria maa jiya aikunju oṣuwọn ileeṣẹ tiwọn ni.

‘’ Kaka ki wọn ronu ọna mi-in ti wọn le fi din owo ti wọn fi n pese ina ku, wọn ro pe kawọn kuku ṣafikun owo faraalu lo daa.

‘’Awọn eeyan tẹ ẹ ro pe afikun yii kan nikan kọ ni yoo koju inira rẹ, ilọpọ marun-un ọmọ Naijiria to n lo ohun ti wọn n pese ni.

’Ẹ ò lẹ́tọ̀ọ́ àti yẹ fóònù aráàlú wò lójú òpópónà’’ –Ọ̀gá Ọ̀lọ́pàá

‘’Ẹ ò lẹ́tọ̀ọ́ àti yẹ fóònù aráàlú wò lójú òpópónà’’ –Ọ̀gá Ọ̀lọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní kokoko là á ránfá adití, Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ wa, ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Edo, ti ṣe é léèwọ̀ fáwọn agbófinró wọn láti máa yẹ fóònù aráàlú wò, pàápàá jù lọ àwọn ọlọ́pàá tó ń dúró nírònà láti yẹ mọ́tò àti èrò tó ń lọ wò, àtàwọn tó ń ṣe pàtúróòlù kiri ìgboro.
Lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Kẹrin, ọdún yìí, ni SP Chidi Nwabuzor, tí í ṣe alukooro ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà fi àtẹ̀jáde yìí síta lórúkọ kọmíṣánnà ìpínlẹ̀ Edo.

kọmíṣánnà ìpínlẹ̀ Edo, CP Funshọ Adegboye, ni Nwabuzor ṣàlàyé pé ó ti gba àwọn agbófinró ìpínlẹ̀ náà níyànjú láti má ṣe gbìdánwò pé won yóò máa tú fóònù onífóònù wò gẹ́gẹ́ bíi àṣẹ tó ti òkè, láti ọ̀dọ̀ ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, wá.

Nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún ló ti ní, “Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Edo, CP Funshọ Adegboye, ti tún mẹ́nuba àṣẹ tí ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá nílẹ̀ Nàìjíríà, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, pa lórí bí wọ́n ṣe fòfin de títú fóònù aráàlú wò láì jẹ́ pé ilé-ẹjọ́ pa á láṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ látàrí ìwádìí ”.

Nwabuzor ní ìkìlọ̀ ńlá ni Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo ṣe fáwọn ọmọ abẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe pa gbogbo ọ̀gá ọlọ́pàá agbègbè àti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan láṣẹ láti òkè wá, àti pé èyíkéyìí nínú wọn tí kò bá dẹ̀yìn nínú ìwà tí kò bófin iṣẹ́ yìí mu yóò dá ara rẹ̀ lẹ́bi.

Tẹ́ ò bá gbàgbé, ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ níyì tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá yóó máa pé aráàlú sí àkíyèsí pé ọlọ́pàá kankan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti dá wọn dúró nírònà láti máa yẹ fóònù wọn wò.

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ti kìlọ fáwọn agbófinró náà láìmọye ìgbà pé dúkìá àdáni èèyàn ni fóònù, wọ́n kò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàdédé dá èèyàn dúró kí wọ́n máa tú gbogbo orí fóònù wọn wò. Ọlọ́pàá tó bá dá a làṣà tí ọwọ́ bá tẹ ẹ, ìyá tó tọ ni yóó jẹ́ labẹ òfin.

Àṣírí tú! Ọwọ́ tẹ ayédèrú EFCC, aráàlú ló n lù ní jìbìtì n’Ìlọrin

Àṣírí tú! Ọwọ́ tẹ ayédèrú EFCC, aráàlú ló n lù ní jìbìtì n’Ìlọrin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹni bá ṣe n tẹ́nìkan ò ṣe rí, ojú rẹ̀ yóó rí n tẹ́nìkan ò rí rí.
Akóló àjọ tó ń gbogun ti iwa ìbajẹ àti ṣiṣe owo ilu mọ́ku-mọ̀ku nílẹ̀ wa, ‘Economic And Financial Crimes Commision’ (EFCC), ẹ̀ka tìlú Ìlọrin, ni afurasí kan, Akọgun Rasheed Usman, wà báyìí. Ẹ̀sùn lílu àwọ aráàlú ní jìbìtì pẹ̀lú ìlérí pé òun yóó bá wọn gba béèlì àwọn ọmọ Yahoo méjì tó wà láhàámọ́ EFCC, tó sì n pe ara rẹ̀ ní ojúlówó òṣìṣẹ́ EFCC ni wọ́n torí ẹ̀ mú un. Ìwà tó hù yìí ni wọ́n ló ta ko ìwé òfin ilẹ̀ wa.

Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrin, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí, ni ọwọ́ EFCC tẹ Usman, lórí ẹsùn jiìbìtì lílù tí wọ́n fi kàn án ọ̀hún.

Oun tí a gbọ́ ni pé ọmọkùnrin tó ń gbé nílùú Babanla, níjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́lódùn, ní ìpínlẹ̀ Kwara, yìí ló ń pe ara rẹ̀ ní ojúlówó EFCC, tó sì gba ẹgbẹrun lọnà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Náírà (500,000), lọ́wọ́ obìnrin kan, Khadizah Abdul,

gẹ́gẹ́ bíi owó tí yóò fi gba béèlì àwọn ọmọ ìyá náà méjì tó wà lákàtà àjọ ọ̀hún, èyí tí wọ́n fẹ̀sùn lílu jìbìtì lórí ayélujára kàn sílẹ̀, kó tóó di pé ọwọ́ tẹ̀ ẹ́ báyìí.

Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Usman gbowó náà tán lọ́wọ́ ìyá wọn ni kò rí àwọn ọmọ náà tú sílẹ̀, tó sì tún ń bèèrè fún ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba Náírà gẹ́gẹ́ bíi àfikún owó tó ti gbà tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ Khadizah, lẹ́yìn-ò-rẹyìn ni àṣírí ọ̀rọ̀ náà padà tú pé ayédèrú EFCC ni. Iléèwòsàn Jẹ́nẹ́rà ìlú Ìlọrin, tó wà lágbègbè Taiwo-Òkè, ni ọwọ́ ti tẹ̀ .

Bákan náà ni wọ́n ló tún ń parọ́ pé òṣìṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ olùkọ́ni àgbà nílùú Òró, ní ìpínlẹ̀ Kwara, Kwara State College of Education), lòun.

Àjọ náàa ní lẹ́yìn táwọn bá parí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwádìí làwọn yóò fojú Usman ba ilé-ẹjọ́.

Ọlákùlẹ́hìn! Olúbàdàn tuntun yọjú kúlẹ́, àìlera Ọ̀ba kìí ṣe t’ọlọ́jọ́–Aṣípa

Ọlákùlẹ́hìn! Olúbàdàn tuntun yọjú kúlẹ́, àìlera Ọ̀ba kìí ṣe t’ọlọ́jọ́–Aṣípa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní a kìí mọ ìyá
Ọṣọ́ ju Ọṣọ́ ,nífèsì ọ̀rọ̀ Aṣípa ilẹ̀ Ìbàdàn lórí ipò ìlera Ọba Ọlákùlẹ́hìn Owólabí,a jẹ́ pé ó ṣeéṣé kí ètò ìgbéṣẹ̀ yíyan Olúbàdàn tuntun ó yá báyìí, bí Àgbà oyè tí ipò Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn sún kàn, Ọba Ọlákùlẹ́hìn Owólabí ti ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn Ọba ìlú Ìbàdàn .

Lára àwọn Ọba tó ṣèpàdé pọ̀ pẹ̀lú Ọba Ọlákùlẹ́hìn Owólabí ni Òsì Olúbàdàn, Ọba Eddy Oyewole, Osi Balógun Olúbàdàn, Ọba Lateef Adebimpe, Ashipa Olúbàdàn, Abiodun Kola-Daisi; Asipa Balógun Olúbàdàn àti Ọba Kola Adegbola.

Nígbà tí ó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, Òsì Balógun Olúbàdàn, Ọba lateef Adebimpe ní, “ ó ti pẹ́ tó ti rẹ bàbá wa nípa ọ̀rọ̀ ogbó, ìyẹn ni kò
jẹ́ kí wọ́n lè bá wa ṣe ìpàdé pọ̀ .”

Oba lateef tẹ̀síwájú pé “ìgbà tí ati rí wọn ti pẹ, ó sì di dandan ká ṣe gbogbo ìpalẹmọ ìwúyè wọn, ẹni tí a ó ṣe ìwúyè fún, a gbọdọ̀ ríi, ìyẹn ló gbé wa wá.

“A sì rí pé ara Ọba Ọlákùlẹ́hìn Owólabí dá pérépéré .”

Òsì Balógun Olúbàdàn tẹ̀síwájú pé ètò ti tò láti gbà ìlú kí ètò ìwúyè Olúbàdàn titun sì bẹ̀rẹ̀.

Ìpàdé yìí ni yóó jẹ ìpàdé ìkejì tí Ọba Owólabí Ọlákùlẹ́hìn yóò ṣe pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ Olúbàdàn tí ilẹ̀ Ibaydan lẹyìn tí Ọba Mahood Lekan Balógun papòdà.

Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, Ọba Ọlákùlẹ́hìn kò tí ì fojú kan ẹnìkan kan láti ìgbà tí Ọba Mahood Lekan Balógun, tó tún jẹ́ Olúbàdàn kejìlélógójì ti papòdà.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ló ń fojú sọ́nà láti rí Ọba Owólabí Ọlákùlẹ́hìn níta gbangba.

Ìgbésẹ̀ yìí sì ni yóó fòpin sí ọ̀pọ̀ àhesọ ọ̀rọ̀ tó ti n wáyé lórí ìyànsípò àgbà oyè náà sí ipò Olúbàdàn tilẹ̀ Ìbàdàn.
Bí ìgbẹ́sẹ̀ yíyàn Olúbàdàn tuntun bá ṣe jẹ́, Ìròyìn Òwúrọ̀ kò ní-ín jẹ́ kétí ẹ̀yin aráàlú ó di síi.