Kò s’óríléèèdè tó yọ ìsẹ́ àti òsì kúrò nílùú f’ọ́dún mẹ́ta – Ọbafemi George
Ọmọwe Obafemi George jẹ onimọ eto oselu lo n ṣe idanilẹkọọ lorisii ọna fun gbogbo araye nipa eto oselu.
O ni “oludije du ipo Aare kan l’ọdun 2023 ti gba awọn osise to le lẹgbẹrun mẹrin (4,000), o ni ki wọn kan maa ta ko gbogbo ohun ti Aare Bola Tinubu ba ti gbe jade. Awon yii ni wọn maa n pariwo laala lori ẹrọ ayelujara. Eyi ni ọpọ ti nnkan ko ki n tete ye maa n tẹle ti wọn maa ni aye ko si lẹyin Tinubu mọ.”
“Awọn olutele yii ti dagba lati ẹgbẹrun mẹrin si ẹgbẹrun mọkanla (11,000)”. “Ti a ko ba fẹ tan ara wa ko si orileede to kuro ninu isẹ ati osi laarin ọdun mẹta.” “Mo maa n sabaa bi ọpọ eniyan lori redio ati telifisọn ti wọn ba ti pe mi, ki wọn fun mi ni apẹẹrẹ orileede kan to kuro ninu isẹ ati osi laarin ọdun mẹta”.
Ara awọn igbekugbe ori ẹrọ ayelujara ni – “Resign now” waye ni ọdun kọkandinlọgbọn sẹyin (29 years ago) ninu iwe iroyin P M news, Value Of Naira, Can It Be Safed? Waye ni ọdun kẹrinlelọgbọn sẹyin (34years ago) ninu iwe iroyin Citizen Magazine, Death toll reached 80, tension mount in Abuja, waye ni ọdun kẹrindinlọgbọn sẹyin (26 years ago) ati bẹẹ bẹẹ lọ.”
Obafemi tun fi kun un pe awon banki agbaye bii IMF gan-an gba pe orileede Naijiria wa loju ọna. O ni loootọ ni oju ogun le fun ara ilu sugbon a nilo afarada nitori pe ko si ọgbọn miiran ju bi Aarẹ se n see yii lọ. O ni “o gba orileede China ni ogoji ọdun (40 years) lati yọ isẹ ati osi kuro nilu, o gba Singapore ni ọdun mejilelọgbọn (32 years) nigba to gba Dubai ni ogoji ọdun (40 years) ki wọn to rojutuu ilu wọn nigba to gba Rwanda to jẹ adulawọ tiwa ni ọdun mẹrinlelogun (24 years) ati bẹẹ bẹẹ lọ” gẹgẹ bi o se salaye.
O ni ọdun mẹta pere ni Tinubu tii lo lori aleefa ti gbogbo wa n reti ise iyanu. O gba gbogbo omo Naijiria niyanju lati ni afarada nitori pe ilu yii si maa dara.
O tẹ siwaju pe “ko tii si Aarẹ Naijiria to doju kọ isoro orileede yii bii Tinubu. O ni bayii ko si ipinlẹ ti a ko ti ni ri ọwọ Aarẹ yii bayii. A maa ri nipa akanse isẹ kan tabi omiran”.
Obafemi se akawe Lagos /Calabar coaster road, o se apẹẹrẹ ti ọna Badagry si ilẹ Hausa ati awọn ọna kaakiri orileede, owo iranwọ ileewe fun awọn akẹkọọ Fasiti, imuduro owo naira, riro awọn ijọba ibilẹ lagbara, sise ilopo mẹta owo fun ipinlẹ kọọkan ati bẹẹ bẹẹ lọ.









