Idande de si awọn ara ilu Woro ni ipinlẹ Kwara ati ti ipinlẹ Niger ni oni ọjọ karun-un, osu kẹjọ ọdun 2026.
Awọn eniyan yii ti wa ni igbekun awọn ajinigbe lati inu osu keji ọdun yii.
Ti eniyan ba gẹsin kọja ninu awọn ẹbi ati ara awọn to ri idande yii ko ni kọsẹ. Orin ọpẹ ati ogo fun Ọlọrun ni o gbẹnu gbogbo wọn.
Awọn eniyan to din meji ni ọgọsan-an ni awọn onisẹ ibi naa ko ni ipinlẹ Kwara nigba ti awọn to le ni ogoje lo ko sọwọ awọn ẹda buruku naa ni ipinlẹ Niger.
Awọn eniyan yii si wa labẹ itọju ki wọn to pada si ọdọ ẹbi wọn. Ipinlẹ mejeeji ti fẹmi imoore han si Aarẹ Bola Tinubu ati awọn ologun orileede yii. Ki aabo Ọlọrun maa daju lori wa.









