Aare Bola Ahmmed Tinubu lo n salaye ni ilu Abuja nigba ti Olubadan ti ile Ibadan se abẹwo sii.
Olubadan fi ẹmi imoore han si Aarẹ nipa awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn gba silẹ ni ilu Ogbomoso.
Aarẹ ni ijọba ko san kọbọ lati gba awọn eniyan yii silẹ. O ni awọn si ti gbe gbẹrẹgi kana pẹlu wọn ti wọn ko ba jawọ ninu isẹ ibi naa.
Aarẹ Tinubu ni bi wọn ba se n ni ara ilu lara ni awọn maa ni awọn ẹbi ati ara wọn lara.
Ọba Rashidi Ladọja naa si kin Aarẹ lẹyin pe nnkan kan to le mu ki wọn siwọ naa niyẹn. Olubadan tun wa rọ ijọba apapọ lati fun okun eto aabo danindanin.
Tinubu lo ipade naa lati gbesẹ fun awọn Oba, o ni “ẹyin ọba naa ni lati gun awọn gomina ipinlẹ yin ni kẹsẹ ki wọn jẹ ki ọrọ aje rọ awọn ara ilu lọrun. Awọn gomina sun mọ ara ilu ju awa lọ”. Eyi ni Aarẹ salaye fun Olubadan nibi ipade naa.









