Ademola Adeleke ti o jẹ gomina ipinlẹ Ọsun koro oju si Aare Bola Tinubu nitori idibo gomina osu yii.
Gomina ni lẹyin ti ẹgbẹ Accord oun ti mu Aare Tinubu gẹgẹ bi oludije du ipo Aare ẹgbẹ wọn, ko ye ki ẹgbẹ oselu APC tun maa ba awon du ipo gomina mọ.
Gomina sekilọ pe “nnkan buruku ko gbọdọ sẹlẹ si awọn eniyan ipinlẹ Ọsun. Kin ni ẹgbẹ oselu APC tun n fẹ lẹyin ti a ti mu Aare Tinubu gẹgẹ bi oludije du ipo Aarẹ ẹgbẹ wa? Kin ni Oyetola tun n fẹ ti ọlọpaa fi pọ to bayii ni ipinlẹ Ọsun? Emi ni olori eto aabo (CSO) ipinlẹ Ọsun, mi o si beere fun awọn ọlọpaa to pọ to bayii. Awọn ajinigbe ati agbenipa kun ilu to ye ki awọn ọlọpaa lọ koju, ko yẹ ki o jẹ awọn ara ipinlẹ Ọsun.” O tun tẹ siwaju pe “eyin ara ipinlẹ Ọsun ni lati jade ni ọpọ yanturu lati dibo, ki ẹ si duro ti ibo yin.”
Ipolongo ibo yii wa lara awọn igba ti ọpọ eniyan maa ri gomina Adeleke loju agbo lai jo. Ijo jijo gbogbo igba ti jẹ ki awọn eniyan maa pe e ni “dancing governor “. Ina ti wa jo dori koko bayii. Gomina pa ijo ti, o ke gbajare, o si gba awọn ara ilu nimọran lati dibo fun un.









