Àṣàyàn inú ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ lọ́dún tuntun nìyí

Àṣàyàn inú ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ lọ́dún tuntun nìyí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Orílẹ̀ yìí, Bola Ahmed Tinubu ti kí àwọn ọmọ Nàìjíríà kú ọdún tuntun bí àwọn orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ṣe ń kí ọdún 2024 káàbọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kú ọdún tuntun èyí tí Tinubu ti bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kìíní, oṣù Kìíní ọdún 2024, ló ti ní inú òun dùn láti bá àwọn ọmọ Nàìjíríà yọ̀ pé wọ́n tún rí ọdún tuntun.

Tinubu ṣe ìgbéléwọ̀n àwọn ìgbésẹ̀ àtàwọn ìrìnàjò tó ti rìn láti ìgbà tó ti wà lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà.

Ó ní ohun tó fojú hàn ni pé onírúurú àwọn ìpèníjà ló wáyé lọ́dún 2023, àmọ́ ó tún kún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé.
Ó wòye pé ṣíṣe ètò ìdìbò àti pípáàrọ̀ ìjọba láì sí wàhálà tàbí títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ èyí tó ṣo ìjọba àwaarawa di ọdún mẹ́rìnlélógún ní Nàìjíríà jẹ́ ohun ìwúrí tó wáyé lọ́dún 2023.

Ó fi kun pé láti ìgbà tí òun ti gba ipò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ ni òun ti ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí òun sì ń sa ipá òun pé ìlọ̀síwájú àti ìdàgbàsókè tó fojú hàn gbọ́dọ̀ bá Nàìjíríà ní èyí tó ṣokùnfà tí òun fi ṣe àwọn ìpinnu kan.

Tinubu tẹ̀síwájú pé gbogbo àwọn ìpèníjà tí àwọn ènìyàn ń kojú ni òun ń gbọ́, tí òun sì mọ̀, pàápàá lórí ọ̀wọ́n gógó tó bá gbogbo ọjà.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ti wá mẹ́nuba àwọn ìgbèsẹ́ ti ìjọba rẹ̀ ń gbé láti mú àyípadà ọ̀tun bá àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́dún 2024.

Àwọn kókó márùn-ún ti Tinubu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nìyí;
*Iná mọ̀nàmọ́ná*
Tinubu ní lásìkò tí òun rin ìrìnàjò lọ sí orílẹ̀ èdè Dubai láti kópa níbi àpérò COP28 ni òun tí ní àjọsọ pẹ̀lú Chancellor orílẹ̀ èdè Germany, Olaf Schol tí àwọn sì ti fẹnukò lórí bí wọ́n ṣe máa lo ìmọ̀ ẹ̀rọ Siemens Energy Power wọlé èyí tó máa pèsè iná tó dúró ire sí ilé mùtúmùwà.

Ó ní láti ọdún 2018 ni ètò náà ti bẹ̀rẹ̀ tí àwọn sì ti fi orí rẹ̀ gún ibìkan báyìí.

Ó fi kun pé iṣẹ́ ti ń lọ káàkiri Nàìjíríà láti ri pé wọn ri àwọn òpó àtàwọn ohun èlò mìíràn tí yóò mú ètò nàá kẹ́sẹ járí.

“Ìjọba mi mọ̀ pé kò sí àyípadà ètò ọrọ̀ ajé kan tó dára tó le wáyé láìsí iná mọ̀nàmọ́ná tó dúró ire.”

*Ètò ààbò*
Tinubu ní àwọn mọ̀ pé ìpèníjà ètò ààbò kò ì tíì kásẹ̀ ní Nàìjíríà àmọ́ àwọn ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti lè ri dájú pé àwọn ọmọ Nàìjíríà lè dijú tí wọ́n bá ń sùn.

Ó ní ààbò ẹ̀mí àti dúkìá jẹ́ ohun tó jẹ ìjọba òun lógún gidigidi tí àwọn sì ń sa gbogbo ipá àwọn láti ri pé ààbò tó péye wà fún gbogbo ènìyàn.

Ó fi kun pé ìjọba ti ń ṣiṣẹ́ lábẹ́lẹ̀ láti yọ àwọn kan kúrò nínú ìgbèkùn àwọn ajínigbé ṣùgbọ́n àwọn kò tíì lè fọwọ́ sọ̀yà pé ìpèníjà ètò ààbò ti kásẹ̀ kúrò pátápátá.

*Ẹbu ìfọpo (Refinery)*
Ààrẹ tún ṣàlàyé ètò fífọ eporọ̀bì ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2024 tí a mú yìí.

Ó ní iléeṣẹ́ ìfọpo ti ìjọba tó wà ní Port Harcourt àti ti aládàni ti Dangote máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni pẹrẹu lọ́dún 2024.

*Ìpèsè oúnjẹ*
Ààrẹ Tinubu fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìjọba ti ń jára mọ́ ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti pèsè ilẹ̀ tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta éékà fún ọ̀gbìn àgbàdo, ìrẹsì, álíkámà (wheat) àtàwọn oúnjẹ mìíràn kí oúnjẹ le pọ̀ lọ́pọ̀ yanturu fún àwọn ènìyàn.

Ó ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ yìí pẹ̀lú eékà ilẹ̀ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà nínú oṣù Kejìlá ọdún 2023 ní ìpínlẹ̀ Jigawa lábẹ́ ètò National Wheat Development Programme.

*Ìdókoòwò*
Ààrẹ tún ṣàlàyé pé ìjọba ti ṣetán láti rí dájú pé àtúntò àti àtúnṣe bá ètò owó orí gbígbà láti ri dájú pé àwọn ènìyàn lè dókoòwò bí wọ́n ṣe fẹ́ ní Nàìjíríà.

Ó ní gbogbo ìrìnàjò tí òun bá rìn, ni òun máa ń sọ fún àwọn olùdókòwò pé ààyè ṣí sílẹ̀ ní Nàìjíríà láti gbé okoòwò wọn wá lójúnà àti pèsè iṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu.

Ó ní ìjọba òun kò ní fi ààyè gba ohunkóhun tó bá le gbégi dínà tí àwọn olùdókòwò kò fi ní gbé okoòwò wọ Nàìjíríà.

Tinubu parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò láti fọwọ́sowọ́pọ̀ láti gbé orílẹ̀ èdè yìí dé èbúté ògo.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here