Àwọn agbébọn n gbà tó 300,000 owó orí lọ́wọ́ wa nípìnlẹ̀ Niger’
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn olùgbé ní àwọn agbègbè kan níìpínlẹ̀ Niger ṣì ń sá kúrò ní ilé wọn, nítorí ìbẹ̀rù àwọn jàndùkú agbébọn tó ń bèèrè owó orí lọ́wọ́ wọn.
Ohun tí a gbọ́ ni pé àwọn ìlú bíi Dagon-dawa, Kurigi, Kangerawa, Mangoro, àti àwọn mìíràn ni ọ̀rọ̀ náà kàn.
Àwọn èèyàn kan ní àwọn ìlú náà sọ pé àwọn agbébọn ọ̀hún ń fi ipá mú àwọn láti san owó orí lórí oúnjẹ, ìgbòkè-gbodò ọkọ̀ àti àwọn nǹkan erè oko wọn.
Ẹnìkan tí ń gbé ní ìlú Dogon Dawa, ṣùgbọ́n tí a fi orúkọ bò ní àṣírí sọ pé àwọn àtìpó gbọdọ̀ sanwó fún àwọn agbébọn kí wọ́n ó tó lè kúrò nílùú.
“ Ọ̀rọ̀ náà ti burú púpọ̀ débi pé àwọn tó wà ní ibùdó ogúnléndé pàápàá ń san owó orí kí wọn ó tó lè fi àwọn ibùdó náà sílẹ̀ .”
Ó ní àwọn oníkúpani ẹ̀dá náà ti sọ àwọn ìlú ọ̀hún di ti wọn, tí wọ́n sì ń bá iṣẹ́ wọn lọ láì sí ìbẹrù.
Díẹ̀ lára àwọn aráàlú sọ fun akọròyìn pé owó tí àwọn agbébọn má ń bèèrè lọ́wọ́ ọkọ̀ tó bá kó àwọn tó ń kúrò nílùú wa láàrin ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìgbà sí ọ̀ọ́dúnrún Náírà. Nígbà mìíràn, wọ́n má ń kó ọkọ̀ mẹ́ta pọ̀, tí wọn ó sì bèèrè mílíọ̀nù kan Náírà lọ́wọ́ wọn.
“Ní ọjọ́ Àìkú tó kọjá, mílíọ̀nù mẹ́ta ààbọ̀ Náírà ni a kó ránṣẹ́ sí wọn, láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn ọkọ̀ kan tó kó dúkìá àwọn èèyàn. Ìdí ni pé àwọn agbébọn náà sọ pé wọn kò ní-ín kọjá, láì san owó náà.”
Ẹlòmíràn tún sọ fún akọ̀ròyìn pé “ọkọ̀ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tó kó oúnjẹ àti irè oko, ni wọ́n dá dúró tí wọ́n sì ń bèèrè ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba Náírà lórí ìkọ̀ọ̀kan wọ́n – á ṣì fún wọn.”