Ọmọ ‘Yahoo’ márùndínlọ́gbọ̀n kó páńpẹ́ EFCC n’Ílọrin, akẹ́kọ̀ọ́ ló pọ̀ nínú wọn

Ọmọ ‘Yahoo’ márùndínlọ́gbọ̀n kó páńpẹ́ EFCC n’Ílọrin, akẹ́kọ̀ọ́ ló pọ̀ nínú wọn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí àwùjọ ṣe ń gé àwọn ọ̀dọ̀ wọ̀nyí lọ́wọ́ ni wọ́n ń bọ̀ọ̀ka, bó ṣe jẹ́ pé kò dín ní géńdé márùndínlọ́gbọ̀n (25), tọwọ́ àjọ tó ń gbógun ti ìwà jìbìtì àti ṣíṣe owó ìlú mọ́kumọ̀ku, Economic Financial and Crimes Commission (EFCC), bà láwọn ìgboro ìlú Ìlọrin, ní ìpínlẹ̀ Kwara, l’ọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 yìí. Wọ́n ní jìbìtì orí ẹ̀rọ ayélujára tí wọ́n ń pè ní ‘Yahoo Yahoo’ làwọn ọ̀dọ́ náà ń ṣe.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Alukoro EFCC, Ọ̀gbẹ́ni Dele Oyewọle, fi léde nílùú Ilọrin, ló tí sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn afurasí ọ̀daràn tí wọ́n mú náà ni wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga, ṣùgbọ́n kàkà kí wọ́n dojúkọ ẹ̀kọ́ wọn, ìwà gbájú-ẹ̀ ni wọ́n ń jù lórí íńtánẹ̀tì, ó ní àwọn inú ilé tí àwọn afurasí náà fara pamọ́ sí lọwọ́ ti tẹ̀ wọ́n.

Lásìkò tọ́wọ́ bá wọ́n, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gínní mẹ́fà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ fóònù ìgbàlódé, àwọn kọ̀ǹpútà àgbélétan, àtàwọn nǹkan mí-ìn tó lòdì sófin ni wọ́n bá níkàáwọ́ wọn.

EFCC, ẹ̀ka tìlú Ìlọrin tó ṣiṣẹ́ náà tí taari àwọn afurasí ọ̀daràn yìí sọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ fún ìwádìí tó lóòrìn, kí wọ́n lè fojú wọn balé-ẹjọ́ láìpẹ .

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here