Àwọn ọlọ́pàá fẹ̀hónúhàn pé wọn ò r’owó àjẹmọ́nú gbà

Àwọn ọlọ́pàá fẹ̀hónúhàn pé wọn ò r’owó àjẹmọ́nú gbà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn ọlọ́pàá tó ń gbógunti ìwà ọ̀daràn ní ẹ̀kùn ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti fẹ̀sùn kan pé, wọn kò san àwọn owó àjẹmọ́nú àwọn.

Àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún, ni àwọn tí wọ́n gbé láti ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan lọ sí ẹ̀kùn náà pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn láti lọ mójútó ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tó ń wáyé lẹ́kùn náà.

Wọ́n ní bí àwọn kò ṣe rí àwọn owó àjẹmọ́nú náà gbà ń ṣe àkóbá fún àwọn.

Ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá ọ̀hún tó bá oníròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé oṣù kẹjọ rèé tí wọ́n ti gbé òun lọ sí ẹ̀kùn náà láti lọ ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun láti kojú ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tó ń wáyé ní agbègbè náà.

Ó ní láti oṣù kẹjọ náà, owó àjẹmọ́nú oṣù méjì péré ni wọ́n san fún òun níbẹ̀, tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn sì ń gba ti wọn.

Ó ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni owó oṣù òun ń lọ dédé.

“Ìṣòro tí à ń kojú lórí àjẹmọ́nú wa tí a kò rí gbà kò kéré rárá nítorí owó oṣù wa nìkan ni à ń lò láti fi gbọ́ gbogbo bùkátà wa.

“Nínú owó oṣù yìí ni a ti ń jẹun, tọ́jú ìlera wa, ṣe ìtọ́jú àwọn nǹkan mìíràn tó bá yẹ.”

Ó wá rọ àwọn adarí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti mójútó sísan àwọn owó tó jẹ́ ẹ̀tọ́ wọn fún wọn nítorí ibi tó jìnà ni wọ́n ti gbé ọ̀pọ̀ wọn lọ sí ẹ̀kùn náà tó sì ti ń kó ìnira bá wọn.

Gbogbo ìgbìyànjú akọ̀ròyìn láti bá iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn yìí lo já sí pàbó nítorí bí agbẹnusọ ọlọ́pàá kò ṣe gbé ìpè rẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here