Èèmọ wọ̀ọ́lu! Ìbálòpọ̀ akọ sákọ làwọn arákùnrin wọ̀nyí yàn lááyò.
Ọrẹ Òtìtọ́jù
Bí òpin ayé bá ti súnmọ́lé, gbogbo n tó sèèmọ̀ lojú yóó má rí, bí etí ṣe n gbọ́ ọ èyí náà ló bí ìròyìn òpín ayé yìí ní bí àwọn géndé mọ́kànlá kan, tí gbogbo wọ́n jẹ́ ara ikọ̀ ajínigbé kan, tí kò sákolo àwọn ọlọ́paa ìpínlẹ̀ Eko báyii, agbègbè táwọn olówó pọ sí jù ni Lẹkki lọwọ́ ti bà wọ́n, wọ́n se àpatẹnujẹ́wọ́ pé iṣẹ́ mẹ́ta táwọn yán láàyò, lójoojúmọ́ ni ìfipá bá ọkùnrin ẹlẹ́gbẹ́ àwọn láṣepọ̀, lílọ́nilọ́wọ́gbà àti ìjínigbé gbowó tó jọjú.
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un yii lawọn afurasi ọdaran naa ka boroboro fawọn agbofinro lolu-ileeṣẹ ọlọpaa Eko to wa lagbegbe Ikẹja.
Wọn jẹwọ pe ni tawọn o, ko sohun to kan awọn pẹlu obinrin, obinrin ki i wọ awọn loju, awọn ki i si i ṣe akọlu si wọn, amọ awọn ọkunrin to san-angun, to duroo re, to si ri jajẹ lawọn maa n foju si lara lati ṣe ni ṣuta.
Ọkọọkan awọn afurasi yii ṣalaye bi wọn ṣe wa ara wọn kan, ti wọn si da ẹgbẹ abẹya-kan-naa-lo-pọ silẹ, ati bi wọn ṣe n ṣiṣẹ buruku wọn.
Wọn jẹwọ pe nigba ti ọkunrin kan ba ti ko sakolo awọn, awọn maa ba tọhun laṣepọ lati iho idi rẹ, gbogbo erekere ati ibalopọ ọran naa lawọn yoo si ka silẹ ninu kamẹra tabi foonu, eyi lawọn maa lo lati fi gba owo nla lọwọ irufẹ ẹni to ṣagbako wọn bẹẹ, tawọn yoo si tun maa dunkooko mọ ọn lẹyin tawọn ba ti tu tọhun silẹ tan.
CSP Kẹhinde Oni, ti i ṣe ọga ọlọpaa to lewaju ikọ awọn agbofinro akanṣe kan, eyi ti Kọmiṣanna wọn l’Ekoo, CP Fayọade Adegoke Mustapha, da silẹ laipẹ yii ṣalaye pe, “ọkunrin lo daran lọwọ awọn afurasi oniṣekuṣe ẹda wọnyi. O ni niṣe ni wọn maa n fipa mu ẹnikẹni to ba lugbadi wọn lọ si eyikeyii ninu awọn ile olowo nla ti wọn n gbe lawọn agbegbe bii Lẹkki, Ajah, Badore, ki wọn too foju onitọhun ri mabo, wọn aa ba a sun lọran-an-yan, wọn yoo si gba dukia ati owo nla lọwọ ẹ.
O ni niṣe ni wọn maa n dibọn pe ejẹnti lawọn, iṣẹ abaniwale, tabi kiateka lawọn n ṣe, ipolowo yii lori ẹrọ ayelujara ni wọn fi n tan awọn ọkunrin titi ti ẹni to nilo iranlọwọ wọn, ti ko si fura, yoo fi ko sakolo wọn.
Ọkan ninu awọn afurasi yii, Joel Esama, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, to n ṣiṣẹ okoowo POS ni Jakande Estate, ni Lẹkki, sọ pe ọmọ bibi ipinlẹ Edo loun, ileewe sẹkọndiri loun lọ, oun ko si ṣetan nibẹ toun fi wa s’Ekoo, toun si n ṣiṣẹ alase ni otẹẹli kan. Oun maa n ṣe ọṣẹ olomi (liquid soap) ta lawọn otẹẹli, oun si tun n ṣe okoowo POS tawọn ẹlẹgbẹ oun maa n lo lati lu awọn ti wọn ba ja lole ni jibiti. O jẹwọ pe ọkunrin kan to n jẹ Edet lo fọna iṣẹ buruku naa han oun toun fi dara pọ mọ wọn.
O ni, “Ohun ta a saaba maa n ṣe ni pe a o tan ẹnikẹni to ba ko sakolo wa wọ ọkan ninu awọn ile ta a rẹnti, to ba ti wọn yara, awa meji la maa fipa mu un lati ba a laṣepọ, iho idi la maa n ba ṣe kinni, ni gbogbo asiko ta a ba n ṣe e, awọn yooku wa aa rọ wọle lati yara keji, wọn aa si bẹrẹ si i ya fidio loriṣiiriṣii,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Ṣa, iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii.