Ìbò 2027 máa rọrùn fún Tinubu ju ti 2023 lọ
Oludije du ipo gomina ni ipinlẹ Eko, Obafemi Hamzat labẹ ẹgbẹ oselu APC lo salaye yii.
Hamzat ni igbakeji gomina ni ipinlẹ Eko bayii. Oun ati gomina Babajide Sanwo-olu ti n sejọba Eko lati nnkan bii ọdun mẹjọ.
Hamzat n salaye lori ikanni TVC pe idibo ọdun to n bọ maa rọrun fun Aarẹ Bola Tinubu ju ti ọdun 2023 lọ.
O ni “l’ọdun 2023, ariwo ẹlẹyamẹya ati ẹlẹsinmẹsin pọ gan-an, paapaa julọ lori tikẹẹti Musulumi ati Musulumi”. O tesiwaju bayii pe ” awọn ọmọ Naijiria ti wa fi oju ara wọn rii bayii pe Aare Tinubu o ki n se ẹlẹyamẹya ati ẹlẹsinmẹsin. Ẹni to kaju rẹ lo maa n fi si isẹ”.
Alaye yii ni Obafemi Hamzat se lori ẹrẹ Tẹlifisọn naa.









