Bi a ba d’ogun ọdun a pe, bi a d’ọgbọn osu a ko. Eto idibo ipo gomina waye jake jado ipinlẹ Ekiti ni oni ọjọ kọkanlelogun osu kẹfa ọdun 2026.
Inu ibo yii ni gomina Oyebanji ti lu awọn ẹgbẹ alatako rẹ ni alubami. Eyi mu ki Aarẹ orileede yii, Asiwaju Bola Ahmmed Tinubu ki Biodun Oyebanji ku oriire ipo gomina ni ẹẹkeji.
Bi esi ibo naa se lọ niyi nisalẹ.

Tinubu kí Oyebanji kú oríire
Orúkọ OYÈ àti orúkọ àwọn Ọba tí wọn wá Lori apere ni ÌPÍNLẸ Ọ̀SUN
Orúkọ OYÈ àti orúkọ àwọn Ọba tí wọn wá Lori apere ni ÌPÍNLẸ Ọ̀SUN
E se àfikún tí ẹ ba mọ nínú àwọn tí a kò mọ orúkọ.
1. OÒNI TÍ ÌLÚ ILÉ-IFẸ̀ – Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja II
2. ATAOJA TÍ Ọ̀ṢOGBO – Oba Jimoh Oyetunji Olanipekun, Larooye II
3. ỌWÁ OBOKUN TÍ ÌLÚ ÌJẸ̀ṢÀ – Oba Clement Adesuyi Haastrup
4. TIMI TÍ ÌLÚ ẸDẸ – Oba Munirudeen Adesola Lawal, Lamisa I
5. OLUWO TÍ ÌLÚ ÌWÓ – Oba Abdul Rasheed Akanbi, Telu I
6. ORANGUN TÍ ÌLÚ ÌLÁ-ÒRÀNGÚN – Oba Wahab Kayode Oyedotun
7. ARAGBIJÌ TÍ ÌLÚ IRAGBIJÌ – Oba Abdulrasheed Ayotunde Olabomi
8. AKINRUN TÍ ÌLÚ IKIRUN – kò ní ọba lọ́wọ́-lọ́wọ́
9. OLOKUKU TÍ ÌLÚ ÒKUKÙ – Oba Samuel Oyebode Oluronke II
10. OLOTAN TÍ ÌLÚ OTAN-ILE – ỌBA Sunday Olatokun
11. ALỌ́RỌ̀ TÍ ÌLÚ ÌLỌ́RỌ̀ÌJẸ̀ṢÀ- ỌBA Haastrup Adeola Ojo
12. ONISẸ TÍ ÌLÚ ÌṢẸ̀-ÌJẸ̀ṢÀ – ỌBA Mark Adeniyi Ajewole
13. ADOMINASI TÍ ÌLÚ IDOMINASI – Ọba Anthony Obafemi Obisanya
14. ONÍKÁJỌLÀ TÍ ÌLÚ KÁJỌLÀ –
15. OLÚ TÍ ÌLÚ WASINMI – Ọba sufian Adisa Sunday
16. AKIRÈ TÍ ÌLÚ ÌKIRÈ – ỌBA Tajudeen Olanrewaju Akintula 1
17. OLUNISA TÍ ÌLÚ INISA – Ọba Joseph Oladunjoye Oyedele
18. ÒGÚNSUWÀ TÍ ÌLÚ MODÁKẸ́KẸ́. Ọba Joseph Olubiyi Toriola
19. ỌLỌ́TAN TÍ ÌLÚ OTAN-AYEGBAJU – Oba Lukman Ojo Fadipe
20. ELEKO TÍ ÌLÚ EKO-ENDE – Oba Adekunle Waheed Babatunde
21. OLÚ TÍ ÌLÚ ALÁJÙẸ́ ẸDẸ – Oba Sulaimon Adebayo Olalekan
22. ALÁGBẸ́DẸ TÍ ÌLÚ AGBEYE – Oba Badmos Rafiu Omotoso
23. ỌLỌ́LÀ TÍ ÌLÚ Ọ̀LÀ-ÈJÌGBÒ – Oba Johnson Oyewale Ajiboye
24. ỌLỌ́SÙNTẸ̀DÓ TI ÌLÚ Ọ̀SÚNTẸ̀DỌ́-
25. OLÚ TÍ ÌLÚ ARÁRÀMÍ OWU –
26. OLÚ TÍ ÌLÚ AKIRIBOTO-ISALE
27. OLÚ TÍ ÌLÚ AKIRIBỌ́TỌ́ ÒKÈ- ọba Peter Oyewọ́
28. ỌWÁ TÍ ÌLÚ OGBAGBA-
29. ALÁPÒMÙ TÍ ÌLÚ APÒMÙ – ỌBA Kayode Adenekan Afolabi
30. OLUWO TÍ ÌLÚ ÌWÓ – ỌBA Abdul Rasheed Akanbi
31. OLÚFÌ TÍ ÌLÚ GBỌNGAN – ỌBA Dr Adetoyese oyeniyi
32. ALAYEGUN TÍ ÌLÚ ODE-OMU – ỌBA Bolarinwa Oladipupo
33. OLOWU KUTA – ỌBA Hameed Adekunle Makama oyelude
34. OLUNISA INISA – Ọba Joseph Oladunjoye Oyedele
35. OLULAMOKUN TÍ ÌLÚ YAKOOYO –
36. ALADA TÍ ÌLÚ ADA –
37. ARÁGBÌJÍ TÍ ÌLÚ ÌRÁGBÌJÍ
38. ẸLẸ́RÌN TÍ ÌLÚ ẸRIN Ọ̀SUN –
39. OLOBU TÍ ÌLÚ ILOBU –
40. ONÍFỌ́N TÍ IFỌ́N Ọ̀SUN –
Ìyàwó ilé tó parọ́ pé wọ́n jí òun gbé ti di rírí ní hotel pẹ̀lú àlè
Ìyàwó ilé tó parọ́ pé wọ́n jí òun gbé ti di rírí ní hotel pẹ̀lú àlè

Arabinrin abilekọ kan ti o pe orukọ ara rẹ ni Oluchi lati ipinlẹ Edo, lo wo sunsun pẹlu ale rẹ pe wọn ti ji oun gbe.
Awọn to ji oun gbe si n beere aadọta miliọnu naira (#50M) ki wọn to le fo oun silẹ.
Eyi lo mu ki gbogbo ẹbi ati ojulumọ maa dawo jọ lati le gba arabibrin naa silẹ.
Igba ti apa fẹ pin ni awọn ara ile bẹbẹ si ogun miliọnu naira (#20M) ti wọn si gba.
Oun ti ọka fi fo ni fifi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti. Owo ti pe, ki wọn gbe owo lọ ni awọn ọlọpaa pe ọkọ Oluchi pe awọn ti ri iyawo rẹ. Inu arakunrin naa dun de idi pẹlu ọkan ninu awọn ọmọ rẹ to wa ni orileede Canada.
Igba ti wọn de agọ ọlọpaa ni jẹbẹtẹ gbọmọ le wọn lọwọ nigba ti awọn ọlọpaa jẹwọ ibi ti wọn ti ka Oluchi.
Ko si orukọ buruku ti ọmọ to wa ni Canada ko pe iya rẹ tan. Eyi buru jọjọ.
Chibuzor wà lára àwọn tó gbẹ̀mí ara wọn nítorí Arsenal tó pàdánù ife ẹ̀yẹ
Chibuzor wà lára àwọn tó gbẹ̀mí ara wọn nítorí Arsenal tó pàdánù ife ẹ̀yẹ
Chibuzor wa lara awon ololufe iko agbaboolu Arsenal to padanu emi nitori pe Arsenal ko ri ife eye UCL gba.
Okan nin u awon ti won jo wo ife eye naa ni bi iko PSG se da ami ayo kan ti Arsenal gba wole pada ni gbogbo eya ara Chibuzor ti da ise sile. O ni ko moo un ti o n se mo titi ti o fi subu lule. O ni awon to wa nibe gbiyanju lati du emi re sugbon “aisan lo se e wo, a ko le ri t’olojo se”. Arakunrin yii je pe Olorun.
Ijoba ibile Aguata ti ipinle Anambra ni isele buruku yii ti sele, ki Eledua te e safefe rere.
Okunrin kiiran naa tun pokunso ni orileede yii leyin idije naa. Odomodekunrin naa je araawon ololufe iko agbaboolu Arsenal bakan naa. Awon kan ti ara ere boolu naa ni arun orisiirisii. O ma se o!
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Oyo fajú ro sí ìjinigbé arábìnrin Adelabu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni Ibadan
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Oyo fajú ro sí ìjinigbé arábìnrin Adelabu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni Ibadan
Ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) ni Ipinle Oyo ti benu ate lu ijinigbe Arabinrin Busayo Adelabu-JohnPaul ni ojo Weside ni Ibadan.
Nínú àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ Akọ̀wé Ìpínlẹ̀ wọn, Ọ̀gbẹ́ni Olawale Sadare, ní ọjọ́rú, ẹgbẹ́ òṣèlú APC rọ Gómìnà Seyi Makinde láti bá àwọn ilé iṣẹ́ ààbò àti àwọn olùníláárí ṣiṣẹ́ pọ̀ láti dín àìsí ààbò kù ní ìpínlẹ̀ náà.
A gbọ́ pé wọ́n jí Adelabu-JohnPaul gbé pẹ̀lú àwọn ìbejì rẹ̀, Paul àti Peter, ọmọ ọdún méjìlá ní Bolumole, Elewura-Challenge ní Ibadan.
Wọ́n sọ pé àwọn ọlọ́pàá kan ló jí àwọn ènìyàn náà gbé, wọ́n sì sọ pé wọ́n ti tẹ̀lé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n gbé àwọn ènìyàn náà láti ilé wọn kí wọ́n tó fi wọ́n lu ọkọ̀ náà ní agogo méje ààbọ̀ òwúrọ̀.
Ẹgbẹ́ APC kéde pé àwọn ọ̀ràn jíjínigbé ń pọ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ náà, wọ́n ní “àwọn ènìyàn ń dààmú sí i nípa ọ̀ràn jíjínigbé.”
Ó tọ́ka sí ọ̀ràn jíjí àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ kan àti àwọn olùkọ́ wọn gbé ní Ìpínlẹ̀ Ìjọ́ba Oriire ní ìpínlẹ̀ náà tí a kò tí ì yanjú rẹ̀.
“Èyí jẹ́ ní àfikún sí àwọn òṣìṣẹ́ méjì ti Cocoa Research Institute of Nigeria (CRIN) ní agbègbè Idi-Ayunre ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Oluyole ní ìpínlẹ̀ Oyo tí wọ́n kọ́kọ́ jí gbé.
“A lo ọna yii lati rawọ si awọn alaṣẹ ti o yẹ ni ipele ijọba apapọ, ipinlẹ ati agbegbe lati wo eto aabo ipinlẹ Oyo ni pataki.”
Wike fi Aisha Yesufu tó kùnà láti jáwé olúborí ìbò senetọ NDC ṣe yẹ̀yẹ́
Minisita fun olu-ilu orileede yii ni Abuja, Alagba Nyesom Wike fi arabinrin Aisha Yesufu se yẹyẹ.
O ni “eremọde ati ẹfẹ ori ayelujara ni o pe eto ibo.” “Pẹlu gbogbo ẹnu rẹ, o wa lọ kuna sọwọ ẹgbẹ oselu ti ko lorukọ. Ẹgbẹ oselu ti kii se APC, bẹẹ ni kii se PDP, NDC lasan-lasan.”
Wike tun fi kun un pe “ọrọ oselu kii se oyinbo sisọ lori ẹrọ ayelujara tabi tẹlifisọn lasan, oselu ilẹ yii nilo ọpọlọ pipe yatọ si ariwo lasan.”
Arabinrin Aisha Yesufu ni awọn alakoso ẹgbẹ naa ni ko leto nitori pe wọn ko tẹle alaalẹ ajọ eleto idibo ilẹ wa.
Aisha padanu eto ibo lati se Sẹneto lati ẹkun Abuja sugbọn kadara ko see loore.
Gbajumo sorosoro, Oluṣọla Arikẹ jawe olubori gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ ADC fun ipo aṣoju-ṣofin Alimọṣọ, Eko
Gbajumo sorosoro, Oluṣọla Arikẹ Ayekootọ jawe olubori gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ ADC fun ipo aṣoju-ṣofin ẹkun idibo Alimọṣọ, nipinlẹ Eko
Idunnu lo ṣubu layọ fun gbajumọ sọrọsọrọ, to tun jẹ agba oniroyin nni, Ọnarebu Oluṣọla Arikẹ, tọpọ awọn eeyan mọ si Ayekootọ, lori bo ṣe jawe olubori gẹgẹ bii oludije fẹgbẹ oṣelu ADC, tipinlẹ Eko, fun ipo aṣoju-ṣofin, ni ẹkun idibo Alimọṣọ, ninu ibo to n bọ lọdun 2027.
Nibi ibo abẹle ẹgbẹ naa to waye lọsẹ to kọja yii ni akọni obinrin oloṣelu yii ti fẹyin ẹni ti wọn jọ jade dupo ọhun iyẹn Ọnarebu Mojeed Anjọlaiya janlẹ patapata.
Bo tllẹ jẹ pe ọpọ igbese lo ti waye ninu ẹgbẹ ADC lori ẹni ti yoo ṣoju wọn fun ipo aṣoju ṣofin ọhun, ko too di pe awọn mejeeji pade lori papa ti Arikẹ si fẹyin ọkunrin naa janlẹ.
Gẹgẹ bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC agbegbe Alimọṣọ, ṣe wi lọjọ ti wọn dibo ọhun, wọn ni awọn mọ ọn mọ ṣatilẹyin fun Arikẹ Oluṣọla gẹgẹ bi oludije nitori awọn mọ pe o kun ju osuwọn
Wọn ṣapejuwe ẹ bii ẹni to ni iriri lati le ṣe aṣoju wọn to ba delu Abuja, ti yoo si fi ran awọn Alimọṣọ lọwọ.
Ọnarebu Arike Oluṣọla ti waa fẹmi imoore ẹ han sawọn eeyan agbegbe Alimọṣọ lori bi. wọn se dibo fun un
Bẹẹ lo tun dupẹ lọwọ awọn oloye atawọn agbaagba ẹgbẹ ADC fun oore ọfẹ ti wọn fun oun lati gba tikẹẹti ọhun.
O wa mu da wọn loju pe oun ko ni doju ti wọn, ati pe wọn ko ni kabamọ igbagbọ ti wọn ni si oun.
Arikẹ tun lo akoko naa lati rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC lati jọ ṣiṣẹ pọ nitori agbajọ ọwọ la fi n sọya, ki wọn jẹ kawọn jọ ṣiṣẹ pọ lati ri i pe ẹgbẹ wọn jawe olubori lati ipo aarẹ, aṣofin agba, aṣoju-ṣofin, gomina ati ọmọ ile igbimọ aṣofin.
O sọ pe, o da oun loju pe ẹgbẹ oun ni yoo jawe olubori ninu ibo ọdun 2027. O ni ki APC maa palẹ ẹru wọn mo, ADC ti de lati gbajọba lọwọ wọn.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Segun Aina fìtàn balẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá JAMB tuntun
Ọ̀jọ̀gbọ́n Segun Aina fìtàn balẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá JAMB tuntun
Ajọ idanwo ti o fẹrẹ lagbara ju fun awọn akẹkọọ ni ajọ JAMB (Joint Admissions and Matriculation Board). Ajọ yii lo n samojuto eto idanwo asewọle si Fasiti kaakiri orileede yii.
Ọjọgbọn Is-haq Oloyede lo ti n tukọ eto ẹkọ naa bọ lati bii ọdun mẹwaa sẹyin. Oloyede gba ipo ni ọjọ kẹsan-an, osu kẹjọ, ọdun 2016 lẹyin ti baba yii pari olori ile-ẹkọ Fasiti Ilorin laarin ọdun 2007 si 2012. Aarẹ orileede yii, Bola Ahmed Tinubu ti fọwọ si yiyan Ọjọgbọn Aina gẹgẹ bii ọga ajọ naa.
Inu osu keje ọdun yii ni Segun Aina to maa pe ẹni ogoji ọdun.Ikede naa waye lati ẹnu Bayo Onanuga to jẹ olu-bani-damọran pataki fun Aare.
Ọjọgbọn Aina jẹ onimọ rẹpẹtẹ ninu imọ erọ Kọmputa ni ilẹ yii ati ni oke okun. O ti ni iriri to pọ ninu imọ ẹrọ kọmputa lati bii ọdun mẹẹdogun bayii. Segun Aina tun fitan balẹ, oun lo tii maa kere lọjọ ori ju ninu awọn to ti n se olori fun ajọ JAMB lati igba ti wọn ti daa silẹ.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, osu keje ọdun yii ni Ọjọgbọn Is-haq Oloyede maa fẹyinti gẹgẹ bi olori ajọ naa.
Ẹ̀rín d’owó fún Albert àti ẹbí i rẹ̀
Nnkan ko sẹnu re ninu ẹbi ọdọmọdekunrin Albert gẹgẹ bi itan ayelujara se gbe e.
Wọn ni ọrọ ileewe gan-an ko si ninu ero ẹbi Albert nigba ti ko sowo.
Bi oju ogun se wa le to naa nigba naa, wọn ni ẹrin Albert o ni isẹ ati osi ninu. Ẹrin naa ko ni adọgbọn-rin ninu. O maa n rin-in bi Eledua se da ọmọ naa.
Bi ere bi awada ni enikan gba ẹrin naa silẹ ti o si bẹrẹ si ni rin titi to fi sọ ẹbi Albert di oloriire.
Ọ̀rẹ́ ò kì ń y’ọ̀rẹ́, Adẹrupọkọ bá Papilolo s’àjọyọ̀ ọjọ́ọ̀bí 88
Yoruba bọ, wọn ni “ọrẹ o ki n y’ọrẹ…” ni eyi to mu ki Alagba Adẹrupọkọ gbera pẹlu agba oserebinrin Toyin Adegbola lati ba Papilolo s’ajọyọ ọjọọbi.
Ayọ Ogunshina ti gbogbo eniyan mọ si Papilolo pe ẹni ọdun mejidinlaadọrun-un (88) loke eepẹ.
Saka lara baba yi tun se.
Mẹta ni awọn baba yii ni nnkan bi ọgbọn ọdun s’ogoji ọdun sẹyin, wọn si gbajọba adẹrinposonu nigba naa. Awọn mẹtẹẹta naa ni Jacob, Aderupoko ati Papilolo yii. Ti wọn ba ti de ori telifisọn, ẹrin arintakiti ni ni igba naa su
gbọn iku ti ọwọ Jacob lawo.
















