Wike fi Aisha Yesufu tó kùnà láti jáwé olúborí ìbò senetọ NDC ṣe yẹ̀yẹ́

Minisita fun olu-ilu orileede yii ni Abuja, Alagba Nyesom Wike fi arabinrin Aisha Yesufu se yẹyẹ.
O ni “eremọde ati ẹfẹ ori ayelujara ni o pe eto ibo.” “Pẹlu gbogbo ẹnu rẹ, o wa lọ kuna sọwọ ẹgbẹ oselu ti ko lorukọ. Ẹgbẹ oselu ti kii se APC, bẹẹ ni kii se PDP, NDC lasan-lasan.”
Wike tun fi kun un pe “ọrọ oselu kii se oyinbo sisọ lori ẹrọ ayelujara tabi tẹlifisọn lasan, oselu ilẹ yii nilo ọpọlọ pipe yatọ si ariwo lasan.”
Arabinrin Aisha Yesufu ni awọn alakoso ẹgbẹ naa ni ko leto nitori pe wọn ko tẹle alaalẹ ajọ eleto idibo ilẹ wa.
Aisha padanu eto ibo lati se Sẹneto lati ẹkun Abuja sugbọn kadara ko see loore.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here