Ìyàwó ilé tó parọ́ pé wọ́n jí òun gbé ti di rírí ní hotel pẹ̀lú àlè

Arabinrin abilekọ kan ti o pe orukọ ara rẹ ni Oluchi lati ipinlẹ Edo, lo wo sunsun pẹlu ale rẹ pe wọn ti ji oun gbe.
Awọn to ji oun gbe si n beere aadọta miliọnu naira (#50M) ki wọn to le fo oun silẹ.
Eyi lo mu ki gbogbo ẹbi ati ojulumọ maa dawo jọ lati le gba arabibrin naa silẹ.
Igba ti apa fẹ pin ni awọn ara ile bẹbẹ si ogun miliọnu naira (#20M) ti wọn si gba.
Oun ti ọka fi fo ni fifi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti. Owo ti pe, ki wọn gbe owo lọ ni awọn ọlọpaa pe ọkọ Oluchi pe awọn ti ri iyawo rẹ. Inu arakunrin naa dun de idi pẹlu ọkan ninu awọn ọmọ rẹ to wa ni orileede Canada.
Igba ti wọn de agọ ọlọpaa ni jẹbẹtẹ gbọmọ le wọn lọwọ nigba ti awọn ọlọpaa jẹwọ ibi ti wọn ti ka Oluchi.
Ko si orukọ buruku ti ọmọ to wa ni Canada ko pe iya rẹ tan. Eyi buru jọjọ.









