Ọ̀jọ̀gbọ́n Segun Aina fìtàn balẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá JAMB tuntun

Ọ̀jọ̀gbọ́n Segun Aina fìtàn balẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá JAMB tuntun

Ajọ idanwo ti o fẹrẹ lagbara ju fun awọn akẹkọọ ni ajọ JAMB (Joint Admissions and Matriculation Board). Ajọ yii lo n samojuto eto idanwo asewọle si Fasiti kaakiri orileede yii.
Ọjọgbọn Is-haq Oloyede lo ti n tukọ eto ẹkọ naa bọ lati bii ọdun mẹwaa sẹyin. Oloyede gba ipo ni ọjọ kẹsan-an, osu kẹjọ, ọdun 2016 lẹyin ti baba yii pari olori ile-ẹkọ Fasiti Ilorin laarin ọdun 2007 si 2012. Aarẹ orileede yii, Bola Ahmed Tinubu ti fọwọ si yiyan Ọjọgbọn Aina gẹgẹ bii ọga ajọ naa.
Inu osu keje ọdun yii ni Segun Aina to maa pe ẹni ogoji ọdun.Ikede naa waye lati ẹnu Bayo Onanuga to jẹ olu-bani-damọran pataki fun Aare.
Ọjọgbọn Aina jẹ onimọ rẹpẹtẹ ninu imọ erọ Kọmputa ni ilẹ yii ati ni oke okun. O ti ni iriri to pọ ninu imọ ẹrọ kọmputa lati bii ọdun mẹẹdogun bayii. Segun Aina tun fitan balẹ, oun lo tii maa kere lọjọ ori ju ninu awọn to ti n se olori fun ajọ JAMB lati igba ti wọn ti daa silẹ.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, osu keje ọdun yii ni Ọjọgbọn Is-haq Oloyede maa fẹyinti gẹgẹ bi olori ajọ naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here