Lóòótọ́ ni mo fi iṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀, àmọ́ mo ti di Olùṣọ́ àgùntàn fún gbogbo ìlú Ogbomoso – Ọba Ghandi

Lóòótọ́ ni mo fi iṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀, àmọ́ mo ti di Olùṣọ́ àgùntàn fún gbogbo ìlú Ogbomoso – Ọba Ghandi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé n tí Ọlọ́run bá ti kọ mọ́ ẹ̀dá, dandan ni kó wá sí ìmúṣẹ.
Ṣọun tuntun nílẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́, Ọba Ghandi Afọlabi Laoye, Orumagẹgẹ III, ti ní bótilẹ̀ jẹ́ pé òun ti fi iṣẹ́ Pásítọ̀ sílẹ̀ ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ìjọ ìràpadà, RCCG, tó tóbi jùlọ lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, òun ti di Olùṣọ́ Àgùntàn fún gbogbo ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ báyìí.

Ọba Laoye fi ọ̀rọ̀ yìí léde lẹ́yìn tí ó gba ọ̀pá àṣẹ láti ọwọ́ Gómìnà Ṣeyi Makinde níbi ayẹyẹ ìgbọ̀pá àṣẹ tó wáyé ní pápá ìṣeré Ṣọ̀ún ti ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́.

Ó ní Ọba tí òun jẹ kìí ṣe fún àwọn ẹlẹ́sìn Kírísítẹ̀nì nìkan, bíkòṣe Mùsùlùmí, àwọn Ẹlẹ́sìn àbáláyé àti gbogbo ẹni tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan.

Ṣọ̀ún tuntun ní bótiwù kí ẹ̀dá làkàkà tó, Ọlọ́run nìkan ló lè fini jẹ ọba.

Ó pàrọwà sí àwọn tí wọ́n jọ du ipò náà pé kí wọ́n gbaàgbé ọ̀rọ̀ àná, kí wọ́n sì sowọ́pọ̀ láti gbé ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́ dé ibi gíga.

Ọba Laoye ní gbogbo ìmọ àti ìrírí tí òun ní nípasẹ̀ iṣẹ́ Pásítọ̀ àti okoòwò nílùú Amẹ́ríkà ni òun yóò papọ̀ láti mú ìlú Ògbómọ̀ṣọ́ gun òkè àgbà.

Ó ní òun yóó ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìdàgbàsókè ọlọ́dún márùndínlọ́gbọ̀n fún ilẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́ láti di ìlú tó ṣee mú yangàn jù báyìí lọ.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Gọmina Ṣeyi Makinde lóríi bí ó ti fi ọmọnìyàn ṣe láti mú kí ìfẹ́ Olódùmarè ṣẹ lórí ìyànsípò òun gẹ́gẹ́ bíi Ṣọun ìkọkànlélégún nílẹ̀ Ògbómọ̀ṣọ́

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here