Olórí ìjọ àti àwọn márùn-ún míràn rí wẹ̀wọ̀n l’Óndó

Olórí ìjọ àti àwọn márùn-ún míràn rí wẹ̀wọ̀n l’Óndó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìjàngbọ́n kìí bímọ re.
Ilé-ẹjọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ Òǹdó kan, tó fìlú Àkúrẹ́ ṣe ibùjókòó , ló ti rán àwọn mẹfa kan lẹwọn ọdún méjì fún dída omi àlàáfíà ìlú Ayetoro níjọba ìbílẹ̀ Ìlàjẹ ní ìpínlẹ̀ náà rú.

Àwọn mẹfa náà ni Oluwambe Ojagbohunmi, tó jẹ́ olórí ìjọ The Holy Apostles’ Church, Aiyetoro, tó sì tún pera rẹ̀ ní adarí ìlú náà, Victor Akinluwa, Isaac Ikuyelorimi, Lawrence Lemamu, George Eyekole àti Segun Okenla.

Àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà náà ni ọlọ́pàá mú ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kínní, ọdún 2018 lórí ẹsùn pé àwọn ni wọ́n wà nídìí rògbòdìyàn tó bẹ sílẹ̀ nílùú Ayetoro lé yìí tó fa ìpalára fáwọn kan, tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì bàjẹ́.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ igbẹjo, ẹsùn mẹwàá ni agbẹjọro olupẹjo, Babatunde Falodun kà sí wọn lẹsẹ nileẹjọ tó fi mọ́ ìwà ipá, ìdàlúrú, ìdigunjalè àti bíba dúkìá onídúkìá jẹ́.

Gẹ́gẹ́ bí Falodun ṣe wí, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yìí ló tako àlàkalẹ̀ abala kọkanleaadọtalenirinwo nínú òfin ọdaràn, ìdì kẹtadinlogoji, apá kìíní, nínú òfin ìpínlẹ̀ Òǹdó ti ọdún 2026.

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn náà, George Eyekole, ni wọ́n fi ẹsùn ìgbìyànjú láti paniyan kàn nítorí ó yìnbọn mọ́ ọkùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Olu Obolo, tí eléyìun sì tako àlàkalẹ̀ abala okòólélọ́ọ̀dúnrún nínú òfin ọ̀daràn, ìdì kẹtàdínlógójì, apá kìíní, nínú òfin ìpínlẹ̀ Òǹdó ti ọdún 2026.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀daràn náà wí pé àwọn kò jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn ti wọ́n fi kan wọ́n, ilé-ẹjọ́ dẹ̀bi rù wọ́n lórí mẹ́ta nínú àwọn ẹsùn náà tó níí ṣe pẹ̀lú bíba dúkìá jẹ́.

Nínú ìdájọ́ rẹ̀, Onídájọ́ David Kolawole wí pé àwọn ọ̀daràn náà jẹ̀bi bíba dúkìá onídúkìá jẹ́, ó sì ní kí wọ́n lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì gbára àbí kí wọ́n sanwó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà.

Bákan náà ló ní kí oníkálùkù wọn ó san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún náírà gẹ́gẹ́ bíi owó gbà má bínú fún àwọn dúkìá tí wọ́n bàjẹ́.

Ẹ̀wẹ̀, Eyekole ni kò níí ní ànfààní láti san owó ìtanràn tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ fẹ́ san ní bí adájọ́ tún ṣe fún-un ní ọdún márùn míràn pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára nítorí ìgbìyànjú láti pànìyàn lákòókò làásìgbò náà.

Gbogbo àwọn ọ̀daràn náà ni Onídàájọ́ Kolawole ní kí wọn tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn láti gba àlàáfíà láàyè nínú ìlú náà.

Kolawole fi kún-un pé, àwọn ọdaràn náà ni yóò forí fá ti ìdàrúdàpọ̀ kankan bá tún wáyé nínú ìlú ọ̀hún lẹ́yìn tí wọ́n bá sanwó ìtanràn tí wọ́n sì padà sáàrin ìlú, àti pé owó ìtanràn náà ni yóó di dídápadà fún wọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here