Aláwo ni yóò padà ṣe ìtọ́jú àwọn aláìsàn ní Nàìjíríà, ayaafi —Mimiko

Aláwo ni yóò padà ṣe ìtọ́jú àwọn aláìsàn ní Nàìjíríà, ayaafi…..
—Mimiko

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ ,wọ́n ní èèyàn tó wẹjú lẹ̀rù ń bà.
Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ondo, Olusegun Mimiko ti ṣèkìlọ̀ pé pẹ̀lú bí àwọn onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó ṣe ń fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ lọ ilẹ̀ òkèrè le padà ṣe àkóbá ńlá fún ẹ̀ka ètò ìlera orílẹ̀ èdè yìí.

Mimiko sàsọyán rẹ̀ pé, tí Nàìjíríà kò bá tètè wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ àwọn dókítà tó ń fi orílẹ̀ èdè yìí sílẹ̀ ní lemọ́lemọ́ yìí, ó ṣeéṣe kí ọ̀rọ̀ náà bọ́ sódì tó bá máa fi tó ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá sí àsìkò yìí.

Ó ní ó ṣeni láàánú pé ìjọba ń fi owó kún owó ẹ̀kọ́ àwọn dókítà yìí, síbẹ̀ ní kété tí wọ́n bá ti gba ìwé ẹ̀rí wọn ni wọ́n ń mórílé ilẹ̀ òkèrè.

Níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde àkọ́kọ́ àwọn dókítà ilé ẹ̀kọ́ giga University of Medical Sciences, UNIMED tó wà ní ìlú Ondo, ìpínlẹ̀ Ondo ni Mimiko ti sọ̀rọ̀ yìí.

Ó ní òun ṣe àgbékalẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà nígbà tí òun wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà, lójúnà àti sàmójútó bí kò ṣe sí àwọn tó gbero iru nǹkan bẹ́ẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Gomìnà tẹ́lẹ̀ rí náà rọ ìjọba láti tètè dìde sí ọ̀rọ̀ yìí nítorí kìí ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n fọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá.

Bákan náà ló fi kun pé ìjọba nílò láti máa ṣe kóríyá fún àwọn dókítà kí wọ́n yé fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ mọ́.

Ó tẹ̀síwájú pé tí ìjọba bá ń pèsè àwọn ohun tó le fa kóríyá fún àwọn dókítà yìí, wọn ò ní máa wá ilẹ̀ ọlọ́ràá lọ sí ilẹ̀ òkèrè mọ́.

Mimiko ní ìjáfàra léwu lórí ọ̀rọ̀ náà nítorí bí a kò bá ṣọ́ra, ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn babaláwo ni àwọn aláìsàn yóò máa wá ìtọ́jú lọ tó bá yá.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here