Gbọ́ àgbọ́yé ìdí tí CBN fi fòfin de Opay, Palmpay àtàwọn míì láti sí akoto owó fáwọn oníbàárà tuntun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní bí kò bá nídìí, obìnrin kìí jẹ kúmólú.
Níṣe ni àwọn oníbàárà àwọn ilé ìfowópamọ́ kan ń kó ọkàn sókè bí ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN, ṣe kéde pé kí àwọn ilé ìfowópamọ́ orí ayélujára má gba oníbàárà tuntun mọ́.
Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ orí ayélujára kan tí wọn kò fẹ́ kí àwọn oníròyìn dárúkọ wọn fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn.
Àwọn ilé iṣẹ́ bíi Opay, Kuda Bank, Palmpay àti Moniepoint ni ọ̀rọ̀ náà kàn, tí wọn kò ní ní àǹfàní láti gba àwọn oníbàárà tuntun láàyè láti ṣí akoto owó pẹ̀lú wọn fún ìgbà kan ná.
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ Nàìjíríà ti òfin tuntun CBN náà lẹ́yìn.
Kí ló dé tí CBN fi kéde ìgbésẹ̀ yìí?
Ìwádìí ní ìgbèsẹ́ CBN yìí kò ṣẹ̀yìn tó ń wáyé látàrí bí wọ́n ṣe ń tọná wádìí àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn kan kò máa lò wọ́n láti ṣowó ìlú mọ́kumọ̀ku.
Gbogbo àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí òfin, ni wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn oníbàárà tó ní akoto owó pẹ̀lú wọn.
Èyí ni ìwádìí tí CBN ti ń ṣe láti mọ̀ bóyá àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí ń ni àkọ́ọ́lẹ̀ tó péye nípa àwọn oníbàárà tó ń ní akoto owó pẹ̀lú wọn.
Láti bíi oṣù mélòó kan ni CBN ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí náà pàápàá lórí ọ̀rọ̀ pé àwọn kan ń lo àwọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti máa fi gbé owó tùùlù jáde.
Bákan náà ni àwọn kan ń fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ń lo àwọn akoto owó awọn ilé ìfowópamọ́ yìí láti fi ṣe àtìlẹyìn fún àwọn agbéṣùmọ̀mí.
Ṣáájú ni ìròyìn sọ pé CBN ti ránṣẹ́ pe àwọn adarí àwọn ilé ìfowápamọ́ náà sí ìlú Abuja lórí ọ̀rọ̀ níní àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn oníbàárà wọn.
Iléeṣẹ́ Opay nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi sórí X ní àwọn kò gba oníbàárà tuntun mọ́ láti fi ṣe àtìlẹyìn fún ìjọba lórí ìwádìí tí wọ́n ń ṣe.
Wọ́n ní gbogbo àwọn tó ti ní akoto owó pẹ̀lú àwọn tẹ́lẹ̀ kò ní ìṣòro kankan gẹ́gẹ́ bí CBN ṣe kéde rẹ̀ àti pé gbogbo àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn oníbàárà àwọn tó ti wà pẹ̀lú àwọn ni ààbò tó péye wà fún.