Akẹ́kọ̀ọ́ péréte (0.4%) ló gba máàkì tó lé ní 300 nínú ìdánwò JAMB ọdún yìí.
Ọlámíde Motúnráyọ̀
Àjọ tó ń rí sí ìdánwò àṣewọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Nàíjíríà, JAMB ti kéde èsì ìdánwò ọdún 2024 tí àwọn
akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lẹ́nu lọ́lọ́ yìí.
Ọ̀gá àgbà àjọ náà, Ishaq Olóyédé, ló fi ìkéde náà síta ní olú ọ́ọ́fìsì àjọ ọ̀hún nílùú Àbújá. Gẹ́gẹ́ bíi ohun tó sọ, Ó ní 1.4 mílíọ̀nù ni àpapọ̀ iye àwọn tó ṣe ìdánwò náà.
Ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 ni ìdánwò náà bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n sì parí rẹ̀ lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin kan náà.
Nínú àwọn 1,989,668 tó forúkọsílẹ̀ fún ìdánwò JAMB ọdún yìí, 80,810 ni iye àwọn tó kùnà láti yọjú sí gbàgede ìdánwò, tí àwọn 1,904,189 sì ṣe ìdánwò ọ̀hún.
Olóyédé ní “nínú àwọn 1,842,464 tó ṣe ìdánwò, ìdá 0.4% péré ló gba máàkì tó lé ní 300 nígbà tí ìdá
24% gba máàkì tó lé ní 200″. Ó fi kun pé ìdá 76% àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ló gba máàkì tí iye rẹ̀ kò tó 200. Ó ní àjọ àwọn yóò kéde orúkọ àwọn tí máàkì wọn pọ̀ jùlọ nínú ìdánwò ọ̀hún.
Olóyédé sọ pé obìnrin 982,393, tó jẹ́ ìdá 50.6% ló ṣe ìdánwò náà nígbà tí àwọn ọkùnrin jẹ́ ìdá 49.4% tó ṣé idanwo ọ̀hún. Àtúpalẹ̀ èsì ìdánwò náà fi hàn síwájú si pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ obìnrin pọ̀ ju àwọn akékòó ọkùnrin lọ tó ṣe JAMB lọ́dún 2024 yìí. Ó ní èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ láti bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn tí iye obìnrin tó ṣe ìdánwò JAMB yóò pọ̀ju ọkùnrin lọ.