Bi o tile je pe ko si ohun ti oju ko ri ri, ituka igbeyawo alawada stand-up comedian, Basketmouth ati iyawo re, Elsie, si n se awon eniyan kan ni kayeefi.
Koda, won si n jarankan lori re lori ero ayelujara won.
Ogbontarigi aderinposonu, Bright Okpocha, ti gbogbo eniyan mo si Basketmouth, lo kede ipinya oun ati iyawo re, Elsie Okpocha, lojo die seyin.
Ajo oniroyin kan saaju ti fi iroyin lede pe Basketmouth se ajoyo ojo ibi Elsie nigba ti o pe omo odun merinle-ni-ogoji ni osu kesan 2022 sugbon ti o kuna lati se ajoyo ajodun igbeyawo won, eleyi ti won ma n se lodoodun ni osu kokanla.
Nigba ti o fi idi oro yii mule lori ayelujara lati kede bi won se tu igbeyawo won ka, Basketmouth ko o pe, “Bi o se dun mi to lati gbe oro mi wa si afefe, eleyi ko se e yera fun.
“Leyin opolopo ijomitoro oro, emi ati iyawo mi se ipinnu ti o le lati tu igbeyawo wa ka.
“Bi onikaluku wa se n tesiwaju, a o jo ma a sise papo lati le e fun awon omo wa ni ike, ife, itosona ati atileyin ti won niloo.
“A bebe pe ki e fi owo ara wo wa bi a o se la gbogbo eyi koja. E se,” ni ohun ti o.