*Kín Gan lo gbé nígbá ‘kú?*
Eyín ká
Ilé ẹ̀rín wó
Ẹyẹ lọ ìtẹ́ dòfo
Àtàǹpàkò ò símọ́
Ọwọ́ dìlagbà
Etí ò sí mọ́
Orí dàpólà igi
Èdè baba èdè,
Ìjìnlẹ̀ baba ìjìnlẹ̀
Yorùbá lọ!
Ṣàngbà fọ́!
Adérẹ̀mí kùn lọ bí oyin
Ọlọ́fàiná,ó di kọ̀ kọ̀ kọ̀
Omi nlá tú lọ lọ́rùn kèrèngbè
Ẹja ńlá wẹbú
Dẹran olúwẹri
Ìjì jà ó gbódó
Afẹ́fẹ́ ti gbẹ̀mí àtùpà
Erin sùn
Erin ò jí mọ́
Adérẹ̀mí Ọlọ́fàiná
Níbo nikú ká ọ mọ́ pa?
Afọ́fun gbému làlùmúntù yí
Iṣẹ́ kíṣẹ́ ló jẹ́
Àṣìlò àgbára lo lò
Adérẹ̀mí ò ì jíṣẹ́ parí
Tálágídíinú fi fẹ̀mí ẹ̀ pamọ́ sálákeji
Oníwàtútù onínúmímọ́
Òṣèèyàn lakùn bíìlẹ̀kẹ̀
Adérẹ̀mí ikú jẹ̀bi rẹ
Bó o bá dọ́run ṣèrántí rojọ́
Fìjìnlẹ̀ èdè fọhùn
Níwájú Ọba tí kìí gbáre fóníṣẹ́ẹbi
Bíkú ṣe já ọ lókún ẹ̀mí pàtì
Lójú agbami iṣẹ́ t’Ólú rán ọ sí gbogbo wa
B’Édùwà bá gbatótónu èyí
A jẹ́ pé kúrákútá ikú pin
Ikú gbèrè ìtìjú nù-un.
Gbogbo ẹgbẹ́ òṣèré
Gbogbo sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀
Gbogbo agbáṣàga
Bá a bá sùn ká mà dijú wọnú
Bá a bá tòògbé ká má mulẹ̀ oorun
Orí àìsùn la ó wà kánrin
Ó dìgbà táabá gbàdájọ́ òdodo lọ́wọ́ BABA