Àlàájì kan kú sínú mọ́tò rẹ̀ lásíkò tó kíù nílé epo kan n’Íbàdàn,

Àlàájì kan kú sínú mọ́tò rẹ̀ lásíkò tó kíù nílé epo kan n’Íbàdàn,

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ,àrìnfẹsẹ̀sí kìí ṣèrìn in kìlómítà.
Gbogbo èrò tó tò sílé epo kan ládùúgbò Olúyọ̀lé, n’Íbàdàn, láti ra epo bẹntiróòlù nìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ní kàyééfì pẹ̀lúl u bí ọ̀kan nínú àwọn awakọ̀ tó tò fún epo níbẹ̀ ṣe dédéd pa ojú dé, tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ sọdá sálákeji l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún tí a lòtán yìí 2022 .

Bí àwọn awakọ̀ yòókù ṣe tò fún epo láti ra bẹntiróòlù níléepo ni bàbá yìí jókòókó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ tí nọ́mbà rẹ̀ jẹ́ AKD 878 GP, tó n dúró dìgba tí yóó kan òun paàpá láti ra epo sínú mọ́tò rẹ̀.

Èrò tó pọ̀ níléepo ọ̀hún kò jẹ́ kí kinní ọ̀hún yá, n ni baba ti ko sẹni to mọ orúkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń pè ní Àlàájì nítorí bí ìmúra rẹ̀ ṣe jọ ti Mùsùlùmí yìí bá gbórí lé orí ṣíárìn ọkọ̀ rẹ̀, àwọn èèyàn sì rò pé ó ń sinmi ní tirẹ̀ ni, ṣé ó pẹ́ díẹ̀ tí wọ́n ti tò sórí ìlà níbẹ̀ nítorí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já epo síléepo ọ̀hún tán ni.

Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọkọ̀ tó wà níwájúu bẹ̀rẹ̀ sí í sún síwájú díẹ̀díẹ̀ lẹ́yìn àsìkò díẹ̀ tí gbogbo wọn ti wà lójú kan gbári , Àlàájì kò sún kúò lójú kan tó wà, àwọn tó wà lẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fọn fèrè mọ́tò o wọn “pin-in! Pin-n! Pin-in” láti pè é sákìíyèsí pé ààyè ti ṣí sílẹ̀ níwájú ẹ̀, ṣùgbọ́n bàbá ọ̀hún ò dá wọn lóhùn.

Gbogbo àwọn tó ń wo bàbá yìí bó ṣe jókòó tí kò mira lójú kan náà tó wà lọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í bí nínú, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn kan fi ń rọ̀jò èébú lé e lórí, tí òmí-ìn nínú wọn papàá sì ń gbé e ṣépè, ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, Àlàájì kò kọbi ara sí wọn.

Pẹ̀lú ìbínú làwọn kan fi sọ́ kalẹ̀ nínú un mọ́tò wọn láti jí bàbá tó gbórí lé ṣíárìn ọkọ̀ ṣùgbọ́n táwọn èèyàn rò pé ó ti sùn lọ yìí pé kó sọ oorun yòókù dìgbà tó bá délè, kó sún mọ́tò rẹ̀ síwájú jàre, ọjọ́ ń lọ. Wọ́n fi ọwọ́ gbá a pẹ́pẹ́, kò tún mira síbẹ̀, nígbà náà ni wọ́n tó ó mọ̀ pé kì í ṣe pé Àláájì ń sùn, baba oníbaba ti kú pátápátá ni.

Nígbà tó n fìdí ìròyìn yìí múlẹ̀, Alámòójútó iléepo ọ̀hún, Ọ̀gbẹ́ni Joseph sọ pé “Kàyééfì gbá à nìṣṣẹ̀lẹ̀ yẹn jẹ́ lójúj mi nítorí níṣe ni bàbá yẹn gbè orí lé ṣíárìn, tó gbẹ́sẹ̀ ọ̀tún ẹ̀ sórí i tọ́tù nínú mọ́tò tó ṣílẹ̀kùn ọkọ̀ sílẹ̀, tó sì fi ẹsẹ̀ kejì tilẹ̀, oorun lásán làwọn èèyàn kọ́kọ́ rò pé ó n sùn, láìmọ̀ pé ó ti kú”.

Alákòóso iléepo ọ́hún fìdí ẹ̀ múlẹ̀ síwájú pé àwọn ti fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwon agbófinró létí, wọ́n sì ti gbé òkú ọ̀hún lọ sí ààyè ìṣòkúlọ́jọ̀ títí tí wọn yóó fi rí àwọn ẹbí i rẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here