Home Blog Page 24

John Utaka di Coach ní France

John Utaka di Coach ní France

Yínká Àlàbí

Orileede Faranse ti kede agbabọọlu Super Eagles Naijiria tẹlẹ, John Utaka gẹgẹ bi akọnimọọgba fun ti Montpelliers ni abala ti awọn obinrin. Utaka lo n gba ipo lọwọ Frdric Mendy to jẹ akọnimọọgba fun awọn ikọ naa tẹlẹ.
Agbabọọlu Super Eagles tẹlẹ naa yoo maa sisẹ pọ pẹlu Baptiste Merle labẹ akoso Dirẹkitọ agba, Jean-Louis Saez.
Isẹ gidi ni isẹ naa jẹ fun Utaka nitori pe oun nikan ni akọnimọọgba akọkọ ni abala awọn obinrin ni orileede France.
Lati igba ti Utaka ti siwọ bọọlu gbigba lọdun 2018 ni o ti pọkanpọ sidii akọnimọọgba. O gba iwe asẹ UEFA ni ọdun 2022. Ki o to gba isẹ ti awọn obinrin yii, oun ni akọnimọọgba awọn ọkunrin ti ko tii pe ọdun mọkandinlogun (Montpellier’s U19).
Wọn gbaa si isẹ awọn obinrin nitori bi wọn se n fidi rẹmi, koda ipo karun un ni wọn wa ni ori atẹ bọọlu nigba ti awọn obinrin PSG ati ti Lyon wa ni ipo kin-in-ni ati ipo keji.

Àjọ EFCC palẹ̀mọ́ àwọn afunrasi oníjìbìtì 93 ni ilé ìtura Obasanjo

Àjọ EFCC palẹ̀mọ́ àwọn afunrasi oníjìbìtì 93 ni ilé ìtura Obasanjo

Yínká Àlàbí

Awọn ọmọ onijibiti ori ayelujara ni awọn ajọ EFCC lọ fi ọwọ sinkun ofin ko ni ile itura Aarẹ tẹlẹ ri ni orileede yii, Oloye Olusegun Obasanjo to wa ni ilu Abeokuta, ipinlẹ Ogun. Ajọyọ kan lo n lọ ni ile itura naa ni ọjọ kẹwaa osu kẹjọ ọdun yii.
Ajọ naa palẹmọ awọn ti ko din ni metalelaadorun un (93) ninu wọn pẹlu ọkọ olowo iyebiye bii ogun ati awọn nnkan olowo nla miiran. Didun ibọn kikan-kikan se ẹru ba awon eniyan paapaa julọ awọn ọdọ agbegbe naa, eyi mu ki wọn maa sa asala fun emi won ninu fidio to jade lati agbegbe naa.
Bi oju ogun naa se le to, ori si ko awọn kan yọ nibẹ. Awọn kan de ibẹ, wọn ba ero rẹpẹtẹ ni eyi to mu ki wọn pada sile, awọn kan ni ariya naa su awọn ni awọn se kuro nibẹ ni nnkan bii aago kan aabọ ti awọn si n gbọ ni igbẹyin pe wọn ko awọn akẹgbẹ awọn ni idaji ọjọ naa.

Rògbòdìyàn tó fẹ́rẹ̀ já èrò sí ìhòhò ní pápákọ̀ òfurufú Murtala Muhammed ni Ikeja

Rògbòdìyàn tó fẹ́rẹ̀ já èrò sí ìhòhò ní pápákọ̀ òfurufú Murtala Muhammed ni Ikeja

Yínká Àlàbí

Yatọ si ohun to jọ ere ori itage Wasiu Ayinde lọsẹ to kọja, edeaiyede miiran tun waye laarin ero kan pẹlu awọn osisẹ baluu Ibom Air Flight. Baluu naa de lati ilu Uyo si Eko. Ninu fidio to n kaakiri ori ayelujara, osisẹbinrin Ibom Air ke gbajare si awọn ọkunrin pe obinrin to jẹ ero ninu baluu naa ni o n salaye nnkan fun ti o si bẹrẹ si gba oun leti. Koda o n ba awọn nnkan inu baluu naa jẹ.
Eyi mu ki awọn ọkunrin ti wọn jẹ osisẹ papakọ naa sare si ohun to n sẹlẹ. Nigba ti agbara wọn ko fẹ ka obinrin naa mọ ni ọga wọn pase ki wọn gbe e kuro ninu baluu naa.
Ibi ti wọn ti n gbe ni irun oge jabọ, bẹẹ si ni ẹwu to wọ naa ya ko to de isalẹ. Ero yii naa n pariwo pe se wọn mọ ohun ti osisẹbinrin naa se fun oun ki oun to sọọ di ija fun un. O ni afi ki wọn gbe fidio inu baluu naa jade fun agbejọro oun. Fidio yii lo tun n ja raninranin bi ina ọyẹ lori ẹrọ ayelujara.

Danboskid ni o̩mo̩lé àkó̩kó tó kó̩kó̩ jáde lórí ètò BBNaija

Danboskid ni o̩mo̩lé àkó̩kó tó kó̩kó̩ jáde lórí ètò BBNaija

Mary Fágbohùn

O̩mo̩le E̩le̩gbo̩n Agba Niajiria abala 10, Danboskid, ti se o̩mo̩le ako̩ko̩ ti wo̩n yoo ja kuro lori eto naa.

Eyi waye leyin o̩se̩ meji to gbe ni ile E̩le̩gbo̩n Agba.

Awo̩n o̩mo̩le mejidinlo̩gbo̩n lo wa nibe̩.

Leyin ti won fi agbalejo Ebuka Obi-Uchendu fi nnkan to se̩le̩ laarin o̩se̩ han awo̩n oluworan, o si apo iwe kan o si kede oruko Danboskid.

Danboskid, e̩ni ti oruko̩ re̩ n je̩ Daniel Olatunji, je̩ o̩mo̩ o̩dun marundinlo̩gbo̩n.

Ebuka tun kede pe E̩le̩gbo̩n Agba yoo ma yo̩ awon meji jade le̩e̩kan naa bi eto ba se n lo̩.

UK yóò bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ọ̀daràn ránṣẹ́ sí orílẹ̀èdè won

UK yóò bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ọ̀daràn ránṣẹ́ sí orílẹ̀èdè won

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìdálùú ni ìṣèlú,
ìgbésẹ̀ tuntun kan ti wà nínú ètò tí orílè-èdè UK fẹ́ gbé báyìí, èyí sì ni fífi àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá ti dájọ́ fún lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ránṣẹ́ padà sí orílè-èdè àbínibí wọn.

Akọwe eto idajọ UK lo fidi eyi mulẹ.

Labẹ eto yii ti wọn ṣe fun England ati Wales, awọn ti ẹwọn wọn ba ni gbedeke igba ti wọn yoo lo, le ba ara wọn lorilẹede wọn lẹyẹ o sọka, wọn yoo si tun fi ofin de won lati ma wọ UK mọ laye.

Boya wọn yoo waa tẹsiwaju ninu ẹwọn naa niluu wọn o, tabi ijọba ibẹ yoo gboju kuro lọrọ awọn ṣẹṣẹ de to gbadajọ ẹwọn ni UK naa, Minisiri eto idajọ sọ fun akọroyin pe iyẹn ku sọwọ orilẹede wọn.

Itumọ eyi ni pe o ṣee ṣe kẹni to gbadajọ ẹwọn ni UK maa yan fanda bii alaiṣẹ to ba de ilu abinibi rẹ, ko ṣaa ti kuro lọdọọ tawọn ni.
Lọwọlọwọ, ida mejila ni awọn eeyan to jẹ ajoji ẹlẹwọn lorilẹde naa, ko si din ni £54,000 ti ijọba n na lori ibi ti wọn n fi wọn si bi ijọba ṣe ṣalaye.

Igbesẹ tuntun yii yoo ba UK din inawo ku, yoo si tun da aabo bo awọn eeyan to n sanwo ori lawujọ bi wọn ṣe sọ.

Awọn ti idajọ tiwọn ba jẹ ẹwọn gbere, awọn agbesunmọmi ati apaayan yoo lo abala idajọ ẹwọn wọn pari rẹ ni UK, ko too di pe wọn yoo ro o wo boya ki wọn fi wọn sọko siluu wọn.

Bi ofin yii ba bẹrẹ, o le kan awọn to wa lẹwọn lọwọlọwọ.

Eyi tumọ si pe ẹsẹkẹsẹ ni idapada sile ẹlẹwọn naa yoo bẹrẹ.

Ni akọsilẹ oṣu Kin-in-ni ọdun 2024, o to ẹlẹwọn ẹgbẹrun mẹwaa le ni irinwo, (10,400) ti wọn wa lẹwọn ilẹ okeere.

Akọwe idajọ, Shabana Mahmood, sọ pe awọn yoo juwe ile fun awọn ajoji ẹlẹwọn, bi wọn ba lufin bawọn ṣe gba wọn tọwọtẹṣẹ, tabi ti wọn tun lufin eyikeyi.

NDLEA mú Daddy G.O ní ṣọ́ọ̀ṣi Eko, wọ́n ló gbé òògùn olóró wọ Nàìjíríà

NDLEA mú Daddy G.O ní ṣọ́ọ̀ṣi Eko, wọ́n ló gbé òògùn olóró wọ Nàìjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọlọ́run nìkan ló mọ ẹni tó ń ṣe ti Ẹ̀ lọ̀rọ̀ dà báyìí ní bí àjọ tó ń gbógun ti gbígbé oògùn olóró lórílẹ̀-èdè yìí, ”National Drug Law Enforcement Agency” (NDLEA) ti nawọ́ gan olórí ìjọ kan nílùú Èkó, Pasitọ Adefolusho Olasele, fún ẹ̀sùn gbígbé oògùn olóró láti Ghana wọ Nàìjíríà.

”The Turn of Mercy Church” ni wọn pe orukọ ṣọọṣi ti Pasitọ Adefolusho Olasele jẹ oludasilẹ rẹ naa.

Femi Babafemi, Agbẹnusọ NDLEA, lo kede eyi ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ ọdun 2025.

Atẹjade naa ṣalaye, pe Pasitọ Olasele tawọn eeyan tun mọ si Abbas Ajakaiye, ti ko oogun to lodi sofin wọ Naijiria lati Ghana lọpọ igba.

O fi kun un pe o ti to bii oṣu meloo kan ti Oludasilẹ ijọ tọwọ ṣẹṣẹ ba yii ti n sa kiri kọwọ ofin ma ba a tẹ ẹ.

Ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ ọdun 2025 ni wọn pada mu un ni ṣọọṣi rẹ to wa ni Okun Ajah, lagbegbe Lekki, ipinlẹ Eko.
Nigba to n ṣalaye kikun nipa oogun oloro ti Pasitọ Adefolusho Olasele, n ko wọle ati bi ọwọ ṣe pada tẹ ẹ, Agbẹnusọ NDLEA, Babafemi, sọ pe:
” Lẹyin ọpọ oṣu to ti n sa lọ silẹ okeere kọwọ ma ba a tẹ, Oludasilẹ ijọ The Turn of Mercy Church, Prophet Adefolusho Aanu Olasele (alias Abbas Ajakaiye) ti bọ sọwọ ofin fun kiko oogun oloro to lodi sofin wọ Naijiria.

” Ni ṣọọṣi rẹ to wa ni Okun Ajah, Ojuna Ogombo, Lekki, nipinlẹ Eko ni a ti mu un lọjọ kẹta oṣu Kẹjọ, 2025.

” Awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA to ti n duro de e lati aarọ pe ko pari isin ọjọ naa kawọn le mu un ni wọn pada mu Adefolusho nirolẹ, bo ṣe n jade lati inu ọgba ile ijọsin rẹ.

“Eemeji lo ti sa lọ si Ghana, lati oṣu Kẹfa ti awọn ọtẹlẹmuyẹ ti n ṣọ ọ, lẹyin ti wọn gba oogun oloro Loud ìṣí meji ti wọn lo ko de lati Ghana.

“Bakan naa ni a tun ri i pe o lọwọ si omiran ti a mọ si cannabis.

” Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa ọdun 2025 ni a kọkọ gba oogun oloro ti iwọn rẹ to igba kilo (200kg) lọwọ rẹ ni Okun Ajah, nigba ti ọkọ to gbe iwọn ẹẹdẹgbẹrin (700kg) egbogi kan naa tun ha lọjọ kẹfa, oṣu Keje 2025.”

Atẹjade NDLEA sọ pe Pasitọ Adefolusho jẹwọ pe oun n ko egbogi oloro wọ Naijiria lati Ghana, ati pe ori omi ni ọkọ to n gbe e wa maa n gba.

Wọn lo tun jẹwọ pe oun ti sa kuro ni Naijiria lọ si Ghana, lẹyin ti oun bọ mọ ajọ yii lọwọ lẹẹmeji.

Hèèmọ̀! Déọ̀rẹ́bà ẹni ọgọ́taọdúndíkan yà pa èèyàn méjì,nílùú Ìbàdàn

Hèèmọ̀! Déọ̀rẹ́bà ẹni ọgọ́taọdúndíkan yà pa èèyàn méjì,nílùú Ìbàdàn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé ẹni orí bá kó yọ nìkan ló bọ́ nínú ewu èyí ló bí ìṣẹ̀lẹ̀ abámì kan tó rán èèyàn méjì s’ọ́run,nígbà tí ẹnìkan farapa yánayàna.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló wáyé ní ojú-ọ̀nà Ọ̀jọ́ọ̀- sí Iwo Road nílùú Ìbàdàn.
Ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú yìí ló ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́rú ní nnkan bí aago méjìlá ọ̀sán, léyìí tó ya ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó wà lágbègbè ọ̀hún lẹ́nu.
Àwọn èèyàn tó kú ọ̀hún ni ọjọ́ orí wọn wà láàrin ọdún méjìlélógún sí ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lá gbọ́n pé wọ́n n rìn lọ níbi tí awakọ̀ náà ti kọ lù wọ́n.
Àwọn kan tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ pé, wíwakọ̀ nílànà àìbìkítà ló mú kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà la ẹ̀mí lọ.
Ojú ẹsẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
ti détí ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ni wọ́n ti tawọ́ gán dẹ́rẹ́bà tó pààyàn méjì ọ̀hún.
Ìròyìn òwúrọ̀ gbọ́ pé ẹnìkẹta tó farapa ti n gba ìwòsàn lọ́wọ́ nílé ìwòsàn kan tí wọn ò dáákọ.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó n ṣe
ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣojú wọn ní
bàì bàì ni wọ́n ti n pè fún ìdájọ́ òdodo kò lè jẹ́ ẹ̀kọ́ fún gbogbo ẹni bá n wakọ̀ àìbìkítà lójú pópó.

Alukoro fún ilééṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Adewale Osifeso ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ tó sì fi dá aráàlú lójú pé ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kò ní dọwọ́ bo ọ̀rọ̀ náà, àti pé etí wọn kò ní di sí bó bá ṣe n lọ.

Ìròyìn òwúrò̩ tòní

Ìròyìn òwúrò̩ tòní

Láàrín ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun àti Gbenga Daniel ariwo ńlá sọ

Láàrín ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun àti Gbenga Daniel ariwo ńlá sọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn àgbà sọ pé ẹni à n nà kan kìí dákẹ́ bí bẹ́ ẹ̀ kọ́ tara rẹ̀ yóó bá dákẹ́ ní ọ̀rọ̀ gómìnà tẹ́lẹ̀ tó tún jẹ sẹnetọ tó ń sojú ẹkù ìdìbò ìlà oòrùn ìpínlè ọhun rí bí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ń ké sí I pé ohun tí òfin sọ nípa àwọn dúkìá rẹ tí wọ́n fẹ wó ni kó tẹ̀lé dípò kó máa wá ojú àánú kiri.

Kayode Akinmade, to jẹ agbẹnusọ gomina Dapo Abiodun lo sọ bẹẹ nigba to n sọrọ lori ile Daniel to wa ni Asọludẹrọ ati ile itura rẹ, Conference Hotel ti wọn fẹ dawo.

Ṣaaju ni gomina tẹlẹ ri naa, Gbenga Daniel, ti kọkọ ke gbajare lori awọn dukia ọhun ti ijọba to wa lode fẹ wo labẹ aṣia aato ipinlẹ naa ti wọn kọ lọdun 2022.

Daniel sọ pe gbogbo ohun to yẹ ki oun ṣe lọdọ ijọba loun ṣe ki oun to kọ awọn dukia naa ati pe ko si eyikeyi ninu rẹ ti oun kọ lai kọkọ gba aṣẹ ijọba.

O sọ siwaju si pe igbesẹ ijọba lati wo ile oun to wa ni Ṣagamu ati ile itura Conference Hotel lọwọ oṣelu ninu.

Amọ nigba to n sọrọ, Akinmade sọ pe gbogbo awọn to kọ ile si agbegbe ti Daniel kọ tirẹ si ni wọn fun ni iwe, ṣugbọn kaka ki gomina tẹlẹ ọhun mu iwe iforukọsilẹ ile rẹ lọ si ọọfisi ti wọn yoo ti ṣayẹwo rẹ, nṣe lo n ba orukọ ijọba jẹ.

O ni “ijọba ipinlẹ Ogun ko gbogun ti Gbenga Daniel rara.

“Ohun to ṣẹlẹ ni pe, ninu igbiyanju rẹ lati mu itẹsiwaju ba ipinlẹ Ogun, Gomina Dapo Abiodun ti bẹrẹ si n kọ awọn ile igbalode, bẹẹ lo n ṣatunsẹ sawọn ilu kekeke atawọn agbegbe nla.

“Agbegbe Ibara GRA lo ti bẹrẹ iṣẹ naa niluu Abeokuta, iṣẹ ọhun yoo si tun de Sagamu atawọn GRA to wa ni Ijebu-Ode.

“Iṣẹ ọhun pe fun ki a ṣe ayẹwo awọn ile to wa lawọn agbegbe yii ki a le mọ boya wọn gba asẹ ijọba, ọrọ naa kan awọn ile gbigbe, ile ẹkọ, ile iwosan atawọn ile itaja.”

Akinmade sọ siwaju si pe “inu Sagamu GRA ni ile Otunba Gbenga Daniel wa, yatọ si ile rẹ, ijọba tun fun awọn onilẹ mii lagbegbe naa ni iwe.”

Akinmade pari ọrọ rẹ pe ohun kan to ku fun Daniel lati ṣe ni lati mu iwe iforukọsilẹ ile rẹ lọ si ọọfisi ijọba to n bojuto ọrọ naa lati yanju ọrọ to n run nilẹ.

O sọ pe igbesẹ awọn ko lọwọ oṣelu ninu bo tilẹ jẹ pe Daniel gbagbọ pe wọn mọọmọ n gbogun ti oun nitori oṣelu ni.

Tinubu, Oyetola kò yan adíje dupò ọmọ oyè kan ní pọ̀sìn— Ọ̀gá àgbà àjọ NIWA

Tinubu, Oyetola kò yan adíje dupò ọmọ oyè kan ní pọ̀sìn— Ọ̀gá àgbà àjọ NIWA

Fẹ́mi Akínṣọlá

Nígbaradì fún ìbò abẹ́nú ní ìpínlẹ̀Osun ,Ọ̀gá Àgbà fún ètò tó nííṣé àkóṣo erékùsù (NIWA), Asiwaju Bola Oyebamiji, ti tako àhesọ kan pé Ààrẹ Bola Tinubu àti Mínísítà fún ìfòkun dohun àmúṣọrọ̀, Adegboyega Oyetola, ti yan ẹnìkan pàtó fún ìdìbò ọdún 2026 .
Ọ̀rọ̀ yìí ló ṣàlàyé lásíkò ìfarakínra pẹ̀lú àwọn èèyàn lfedayọ níjọba ìbílẹ̀ odò ọ̀tìn.
Oyebamiji sọ pé irọ́ gbuu ni ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ọ̀hún kí àwọn èèyàn má ṣe kọbi ara sí i.
Ó ní Ààrẹ̀ Bọla Tinubu kò fi ìgbà kankan sọ bẹ̀ẹ́ .Ó ní èyí tí àwọn n ṣe báyìí ni kí àwọn èèyàn lè túbọ̀ mọ àwọn lórí èrònà àwọn ní ìpalẹmọ́ fún ìbò gómìnà lọ́dún 2026.
Ó ní inú òhun dùn fún bí àwọn èèyàn ṣe tú jáde láti wá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí
wọ́n ní tí wọ́n fi tẹ́tí balẹ̀ gbọ́ òhun.
Abiodun Idowu, Alága fún àwọn ìjọba ìbílẹ̀ lórílẹ̀ èdè yìí tó n jà fún ìdápadà àwọn alàga ìbílẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Oyebamiji ,nìgbà tí Kọmísánà ètò ìròyìn tẹ́lè ní ìpílẹ̀ ọ̀hún Arabìnrin Funke Egbemode sọ pé àwọn èèyàn ìjọba ìbílẹ̀ Odò-Òtìn ti dúró tán láti tẹ̀lé Oyebamiji pẹ̀lú èròngbà rẹ̀ díje dúpò gẹ́gẹ́ bí gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọṣun lọ́dún 2026.