Home Blog Page 25

Mo jé̩ àpe̩e̩re̩ e̩wà àti o̩po̩lo̩ tó dára’ — Uche Montana

‘Mo jé̩ àpe̩e̩re̩ e̩wà àti o̩po̩lo̩ tó dára’ — Uche Montana

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Uche Montana (ti a mo teleri si Uche Nwaefuna), ti so pe ki awon ti won n wa ‘aridaju’ pe ewa ati opolo si wa ma wa kiri mo ju odo oun lo.

Ninu iforo-wani-lenu-wo kan pelu Sunday Scoop, o wi pe, “O je ohun ti enikan ko le e jiyan re pe mo ni ebun bee ni mo si tun ni ewa. Itewogba jije obinrin mi kii se ohun to ye ko ti mi loju. Ise mi n soro fun mi, nitori mo n se daradara. Ise takuntakun, ifarajin ati aitasera fun mi ni idanimo ti o to si mi.”

Lori idi to fi se ayipada oruko re kuro ni ‘Nwaefuna’ si ‘Montana’, oserebinrin naa so pe, “Yiyi oruko mi pada je ipinnu fun ise mi. Mi o kii se eni to ni ipa lori elomiran tabi osere nikan, mo tun je eni to ni okowo lokan. Lati odun die seyin, mo sakiyesi pe awon afenifere mi, akegbe mi, ile ise kaakiri agbaye, ati awon ti won fe ba mi dowopo n ri bi nnkan ti ko rorun lati pe oruko idile baba mi, ‘Nwaefuna’. Nitori naa, ayipada. Montana je oruko baba mi pelu. Kii se ohun ti mo dede gbe kale.”

Nigba ti won bii leere boya ipa kan wa ti eru n ba a lati ko, Montana wi pe, “Mi o ro pe o ni ipa kan ti mo n beru lati ko. Akopo osere lekunrere ni pe ko tewogba gba eyikeyi ipa lati ko. Ipenija le e wa nigba miran, sugbon a o le e ri eniyan bii osere tiata to dara laise pe o ni igboya lati lo imoose re. Mo feran ipenija pupo.”

 

Ìdí tí mo fi se ìfiló̩lè̩ èròjà atárase — Bisola Aiyeola

Ìdí tí mo fi se ìfiló̩lè̩ èròjà atárase — Bisola Aiyeola

Mary Fágbohùn

Osere tiata, olorin ati atokun eto mohunmaworan, Bisola Aiyeola, ti se ifilole eroja atarase re ti o pe ni, Brown Girls Magic, ati ile itaja tuntun.

Nigba to fi eroja tuntun mereerin naa lede nibi ayeye ti olusakoso re, The Temple Company gbe kale, ni Lekki, Eko, laarin ose, Aiyeola so pe oun n wa lati da imuyangan pada si odo awon to ni awo naa (ti won ko dudu, ti won ko si pupa lopo).

O wi pe, “Awon eroja naa ni won se pelu ife, ti won si gbe jade ni South Korea. Won se e fun awon eniyan ti ko dudu ju ti won ko si pupo lopo to je Afrika ati awon ti kii se Afrika bakan naa. A pe e ni Brown Girls Magic (idan omobinrin ti ko pupa ti ko si dudu ju), nitori idan wa ninu gbogbo wa. Mo fe ki gbogbo wa tewo gba idan to wa ninu wa, ki a si mu awo ara wa yangan.”

Nigba to n seranti ohun ru ife to ni si okowo naa soke, o wi pe, “Ni 2018, o so si mi lokan pe a o ni awon eroja to n daabobo ara lowo oorun lopo. Mo mo pe a nilo lati wa nnkan ti yoo di alafo naa, ki a si mu ki eroja atarase wa larowoto gbogbo wa.”

Awon alejo nibi eto naa ni obinrin akoko ni ipinle Eko teleri, Abimbola Fashola; Oga Agba egbe ni ile ise The Temple Company, Idris Olorunnimbe; ati awon osere tiata bii— Sharon Ooja, Bimbo Ademoye, Adesua Etomi, Omowunmi Dada, Ini Dima-Okojie; ati awon ilumooka miran bii, Banky W ati Dorathy Bachor.

 

Àwo̩n ènìyàn ń jowú e̩rù àyà mi – Hope Effiong

Àwo̩n ènìyàn ń jowú e̩rù àyà mi – Hope Effiong

Nini omu nla le e je ibukun tabi epe. Fun Hope Effiong iriri naa ko dara rara.

Gbajumo orekelewa ti Olorun bukun pelu ago ara, to wa lati ipinle Cross River, so pe nigba miran inu oun maa n dun ati nigba miran, inu oun ko ni dun lori bi awon kan se n da a lejo fun bi o se ri.

Nigba to n salaye iriri re pelu NollyNow lori WhatsApp, akekoo Cross River University Of Technology (CRUTECH) eni odun marundinlogbon naa, so pe ko wu oun lori bi awon ore oun se n fi esun sise idi ati omu titobi kan oun. Oun naa n fi bu won pe won n jowu oun ni, o fikun un pe “Pupo ninu awon ore mi nigba miran maa n ro pe mo fe gba orekunrin won. Awon kan tile fi bu mi pe mo lo se omu nla ni.”

Won bii leere boya yoo se ise abe lati mu ki omu naa dinku, arewa Instagram naa pariwo pe, “Olorun ma je, mi o le e se iru nnkan bee.”Gege bi o se so, “Nigba ti o ba ti rewa ti o si ni ago ara ti o duro daradara ju ti awon ore re lo, o pon dandan ki won jowu re.”

 

 

Ìrònú dorí àgbà kodò’ Emefiele búsẹ́kú ní kóòtù,

Ìrònú dorí àgbà kodò’ Emefiele búsẹ́kú ní kóòtù,

Ọrẹ Òtítọ́jù

Yooba bọ̀, wọ́n lọrọ tó bá mú kí àgbàlagbà máa làágùn yọbọ lábẹ́ òrùlé, ẹkùn làgbà ọ̀hún ń sun, àmọ́ ní ti ọrọ̀ Ọgá àgbà bánkì àpapọ̀ ilẹ̀ wa, CBN, ti wọ́n yọ nípò, Godwin Emefiele, to si n káwọ́ pọ̀nyìn rojọ lórí àwọn ẹsùn kan tí wọ́n fi kàn án, ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà kọjá kí àgbàlagbà máa làágùn o, níṣe ni bàbá ọ̀hún bú sẹ́kún kíkorò ní kóòtù, tó ń wa ẹkùn mu bíi kà-à-sí nǹkan.

Iṣẹlẹ to ṣeeyan laaanu yii waye l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ kẹtàdínlógún, oṣù Kẹjọ yìí, lásìkò ti wọn tún fojú Emefiele balé-ẹjọ́ gíga ilú Abuja, lolu-ilu ilẹ wa, amọ ti ẹjọ rẹ ko le tẹsiwaju, ti ireti ati atotonu Emefiele lati kuro lahaamọ awọn agbofinro tun ja si pabo. Niṣe ladajọ ni ọsẹ to n bọ, iyẹn Ọjọruu, ọjọ́ kẹtadinlogun, oṣù Kẹjọ yìí, ni kí wọ́n tún mú olujẹjọ yìí wá síwájú òun, ó ní kí wọ́n ṣì dá a padà sakolo àwọn ẹṣọ́ ọtẹlẹmuyẹ àpapọ̀ ilẹ̀ wa, Department of State Service (DSS). Bí Emefiele ṣe gbọ́ àṣẹ tadajọ pa yìí lọkunrin náà dorikodo, ó bu sẹkun gbaragada ni.

Ohun to mu ki idena ba igbẹjọ rẹ lori awọn ẹsun tuntun tijọba ṣẹṣẹ fi kan an, eyi to da lori igbimọ-pọ lati huwa ibajẹ, kiko owo jẹ ni koto ọba, ṣiṣẹ owo ilu mọkumọku ati iwa jibiti lilu, ti ẹjọ naa ko fi tẹsiwaju ni pe ọkan lara awọn ti wọn jọ fẹsun iwa ọdaran yii kan, Sa’adatu Yaro, ko le yọju si kootu. Emefiele, Yaro ati ileeṣẹ kan bayii nijọba ni wọn lọwọ ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn naa.

Lara ẹsun ti wọn we mọ Emefiele lẹsẹ ni pe o fi owo ilu ṣe jẹ-ki-n-jẹ pẹlu Yaro, ti wọn ni ọga agba kan loun ni tiẹ nileeṣẹ kan ti wọn fi wọ obitibiti owo jade lasunwọn banki apapọ loṣu kẹrin, ọdun 2016, wọn lowo ọhun n lọ bii biliọnu meje Naira (N6.9b).

Bi wọn ṣe kawe ẹsun yii atawọn mi-in si Emefiele leti tan, ni adajọ beere pe awọn olujẹjọ gbogbo da, wọn ni Emefiele nikan lawọn ri mu wa, niṣe ni Adajọ Hamza Muazu bẹrẹ si i kọwe wẹrẹwẹrẹ kan, lẹyin naa lo kede pe igbẹjọ ko le tẹsiwaju, tori ẹsẹ olujẹjọ ko pe, lo ba paṣẹ ki wọn da Emefiele pada sibi ti wọn ti mu un wa.

Gbogbo alaye ti lọọya rẹ fẹẹ ṣe lati bẹbẹ iyọnda aaye tabi beeli fun onibaara rẹ ni ko ṣee ṣe, tori bi adajọ ṣe paṣẹ tan ni wọn pariwo, “kọọtu”, ti adajọ naa si dide lori aga wọle lọ.

Bóyá ti pé o kéré tán, Emefiele yóò tún lo ọsẹ kan gbáko sí lákolo àwọn DSS yìí ló pa bàbá náà nígbe ni o, bóyá tí igbẹjọ tí kò sì lè tẹ̀síwájú ni, a ò mọ, àmọ́ àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní àròkàn ní í fa ẹkún àsun-ì-dá wá.

Ẹ ó rántí pé ó ti lé lósù kan báyìí tí Emefiele ti ń pààrà kóòtù, tí kò sì tí lè fàtàrí lé pílò nínú ilé rẹ̀, àkàtà àwọn DSS ló ń bá dé kóòtù, ibẹ̀ náà ló sì ń padà sí, lórí àwọn ẹsùn ọlọkan-o-jọkan tí wọ́n fi kan ọgá àgbà àwọn báńkì ilẹ̀ wa náà, Central Bank of Nigeria.

Ìjọba àpapọ buwọ́lu N5bn owó ìrànwọ́ “palliative” fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti Abuja

Ìjọba àpapọ buwọ́lu N5bn owó ìrànwọ́ “palliative” fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti Abuja

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ orílẹ-èdè Nàìjíríà ti buwọ́lù iye owó bílíọ̀nù márùn náírà fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó fi mọ́ olú ìlú orílẹ-èdè yìí ìyẹn ìlú Abùjá.

Ìjọba ní kí wọ́n fi owó yìí ra oúnjẹ láti pín fún àwọn tí kò rọ́wọ́ họrí ní gbogbo ìpínlẹ̀ kówá wọn.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Babangana Zulum lo fi èyí léde ní ilé Ààrẹ nílùú Abùjá ní kété tí ìgbìmọ̀ aláṣẹ fún ètò ọ̀rọ̀ ajé parí ìpàdé níbẹ̀.

Lafikun sí ọrọ̀ owó yìí, Zulum ṣàlàyé pé ìjọba àpapọ̀ tún ṣe àgbékalẹ̀ àpò ìrẹsì tó kún ọkọ̀ akẹ́rù márùn fún gbogbo àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì.

Gómìnà Zulum ṣe é ní àlàyé wípé gbogbo Gómìnà kọ̀ọ̀kan ló gba àṣẹ láti ra àpò ìrẹsì ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ọ̀rún, àpò àgbàdo ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì àti ajílẹ̀.

Ó ní ìjọba fún wọn ní ìdá méjìléláàdọ́ta gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn owó àmọ́ ìdá méjìdíláàdọ́ta tó kù jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi owóyàá.

Ò̩pò̩ obìnrin tó ń gba May nímò̩ràn kò nílé aláyò̩ – Pete Edochie

Ò̩pò̩ obìnrin tó ń gba May nímò̩ràn kò nílé aláyò̩ – Pete Edochie

Mary Fágbohùn

Ogbontarigi osere tiata, Pete Edochie, ti so pe pupo ninu awon obinrin to n gba iyawo omokunrin re, May Edochie, nimoran ni won ko nile alayo.

Pete so eyi ninu iforo-wani-lenu-wo to se laipe pelu atokun eto, Chude Jideonwo.

Nigba to n soro nipa awuyewuye ninu igbeyawo omokunrin re, Yul Edochie fun igba akoko, Pete so pe o je ohun to le lati ro May pe oun ko mo si ipinnu igbeyawo eleekeji ti Yul.

“Ogooro awon obinrin lo ti gba May nimoran ni ona aito. Won n gbiyanju boya won le e ja asopo to wa laarin oun ati oko re.

“Pupo ninu awon obinrin yi ni ko nile alayo, won o ni. Sugbon leekan sii, o mo pe nnkan wonyi sele ati pe o je ohun to le lati parowa fun un pe mi o mo si,” ni o so.

E ranti pe Yul ni osu kerin odun 2022, ninu atejade kan lori Instagram re kede igbeyawo re keji pelu osere tiata Judy Austin.

Saint Obi bè̩rè̩ ìrìnàjò ilé ìke̩yìn

Saint Obi bè̩rè̩ ìrìnàjò ilé ìke̩yìn

Iyoku oloogbe osere tiata, Obinna Nwafor, ti a n pe ni Saint Obi, yoo wo ka ile sun ni agboole re ni Umuezealaeze, Alaenyi Ogwa ni ipinle Imo, ni awon idile re kede.

Ninu atejade ikede oku ti NollyNow ri, osere oloogbe naa bere irinajo ile ikeyin ni ojo Eti, ojo kokanla osu kejo, 2023, pelu isin titan imole, ni gbagede Civic Centre, Victoria Island, Eko.

Ara St Obi ni won yoo te ni ojo Eti, ojo kejidinlogun osu kejo, ni orile ede re.

E ranti pe awon idile naa seleri lati kede eto isinku oloogbe naa leyin awuyewuye to waye latari irohin Mr Zik Zulu Okafor, eyi to salaye awon isele to se okunfa iku St Obi.

St Obi jade laye ni ojo Aiku, ojo keje osu karun-un, odun 2023, leyin ti o ja fitafita pelu aisan olojo pipe.

Osere naa sese ko lo si ile arabinrin re ni Jos, nigba to se alabapade iku airotele to de ba.

A pínyà lé̩yìn o̩dún méjì’ — Òsèré tíátà, Pat Attah fìdí ìbásepò̩ pè̩lú Genevieve múlè̩

A pínyà lé̩yìn o̩dún méjì’ — Òsèré tíátà, Pat Attah fìdí ìbásepò̩ pè̩lú Genevieve múlè̩

Mary Fágbohùn

Gbajumo osere tiata, Patrick Uchenna Attah, ti a mo si Pat Attah, ti safihan pe ibasepo laarin oun pelu osere tiata Genevieve Nnaji to odun meji saaju ki won to pinya.

Attah so eyi ninu iforo-wani-lenu-wo laipe yi pelu olootu eto, MecksoncrownBTV.

Gege bi Attah se so, ibasepo re pelu Genevieve je ohun to munadoko.

O ni ipinnu lati pinya je ohun ti won ko le e ye ati pe o waye lakoko ti o to.

Osere tiata naa wi pe, “Nnkan wa laarin wa. O si munadoko, sugbon a pinya nitori awon idi kan.

“Iyen ko tumo si wi pe ibasepo wa ko munadoko. A fe ara wa fun bii odun meji abi nnkan,” ni o so.

Nigba ti won bii leere boya ibasepo naa je nnkan asiri, Attah wi pe, “Rara, kii se nnkan asiri. A jo mu ara wa lokunkundun a si jo n lo kaakiri.”

Ohun tó se ìmísí orin mi jẹ́ “Iṣẹ́ Ìyanu” — Ada Ehi

Ohun tó se ìmísí orin mi jẹ́ “Iṣẹ́ Ìyanu” — Ada Ehi

 

Mary Fágbohùn

 

Ilumooka olorin ihinrere Ada Ogochukwu Ehi ti a mo pelu oruko itage, Ada Ehi, ti safihan orisun imisi orin re tuntun “(Iyanu Miran) Another Miracle,” pe oun ri gba lati ara ero to so si oun lokan.

 

Olugbafe eye akorinsile ati iya omo meji naa, so pe orin naa je oro atenumo igbagbo oun ati idahun oun si ibeere aye.

 

Gege bi o se so, “Ohun to se imisi orin naa ni ero ati asaro okan mi. Awon nnkan yi ni mo n ro loorekoore ati idahun mi si ibeere aye lojoojumo, oun lo se imisi orin naa. O je oro igbagbo mi si ibeere aye ati ipo ti o le.”

 

Lori bo se pe to fun un lati mu orin naa wa, o salaye pe, “Kii se oun to ya kankan ninu yara igborinsile. Dena Mwana wa fun RockFest ni odun 2022 o si duro nitori a mo pe a jo fe sise papo lori orin kan ati pe ki a si seda nnkan to duro fun asa awa mejeeji.

 

“Nitori naa, a lo si yara igborinsile, mo pe agborinjade, Preach Zagi, eni to je onijita mi a si jo wa iro ilu lati ri adun naa. O je akoko iyin, bo ti le je pe a o ti ni oro orin.

 

“Nitori naa, leyin to kuro, a bere si ni sise lori oro orin lori asaro okan ati emi mi ojoojumo”.

 

O so pe inu oun dun fun anfaani ti Olorun fun un lati sise pelu Dena lori orin naa bi o se ni afojusun lati ko opolopo orin pelu re.

 

 

 

Gómìnà Èkìtì pàṣẹ kí kọmísánnà rẹ̀ tuntun kan ó lọ̀ọ́ sinmi ná

Gómìnà Èkìtì pàṣẹ kí kọmísánnà rẹ̀ tuntun kan ó lọ̀ọ́ sinmi ná

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Biọdun Oyebanji, ti ní kí kọmiṣanna fún ọrọ̀ oyè jíjẹ ni ipinlẹ náà, Ọlaiya Atibioke, lọ máa sinmi nílé ná.

Ẹsùn àfojúdi ni wọ́n ní Gómìnà fi kan ọkùnrin náà, nítorí bó ṣe kúrò níbi ètò kan tí wọ́n ń ṣe láì gbaaye.

Olùdámọ̀ràn Gómìnà lórí ètò ìròyìn, Yinka Oyebọde, tó fi ọrọ̀ náà léde sọ pé ìpàdé apejẹ kan ni wọ́n ṣe, Gómìnà pàápàá sì wà níbẹ̀ títí tó fi wá sópin, ṣùgbọ́n Atibioke fi ibẹ̀ sílẹ̀ láì tọrọ ààyè.

Ninu atẹjade naa lo ti ni, “Gomina ti fofin de Atibioke, latari bo ṣe kuro nibi eto apejẹ ọlọjọ mẹta ti wọn ṣe fawọn igbimọ ijọba ipinlẹ Ekiti, atawọn akọwe agba ni gbọngan nla Bishop Adetiloye, Trade Fair Complex, Ado-Ekiti, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Loju-ẹsẹ nibẹ lo si ti paṣẹ pe ko lọọ rọọkun nile fun odidi ọsẹ meji”.

Lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ti eto naa ti bẹrẹ ni gomina ti wa nikalẹ titi to fi wa sopin.

Ṣaaju ọjọ ti eto naa yoo bẹrẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni wọn ni Gomina Oyebanji yan awọn kọmiṣanna mọkandinlogun mi-in atawọn oludamọran mẹtala. Ọkan lara awọn kọmiṣanna tuntun ọhun ni Atibioke.

Wọ ni nigba to di nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ ti eto naa yoo pari, wọn ke si awọn kọmiṣanna atawọn akọwe agba nileeṣẹ ijọba to wa nibẹ lati wa maa fọwọ siwee lori bi eto naa ṣe lọ si. Aṣiri ọrọ tu nigba ti wọn pe orukọ Atibioke, ti ko sẹni to gbọ idahun rẹ.

Pẹ̀lú ìbínú ni wọ́n ní gómìnà fi he ẹ̀rọ amóhùndún-gbẹ̀mù, tó bèèrè kọmíṣọ́nnà ọ̀hún, ṣùgbọ́n tí kò gbúròó rẹ̀. Níbẹ̀ ni wọ́n ní gómìnà tí pàṣẹ pé kó lọ̀ọ́ dúró sílé fódidi ọ̀sẹ̀ méjì gbáko.