Emi ati AMVCA ko tii ni nnkan kan papo bayii – Ibrahim Chatta 

Mi ò nífẹ̀ẹ́ sí AMVCA – Ibrahim Chatta

Mary Fágbohùn

Oṣere Nollywood Ibrahim Chatta ti sọro lori bi ko se tii gba ami eye ti Africa Magic Viewers’ Choice Awards (AMVCA)

O ni oun ko tii ni nnkan kan se pelu won, nipa pe oun ko tie kopa ninu idije naa.

O so gbangba pe oun ko si ohun to kan ounAMVCA,  bi o tile je pe won yan an fun  ọkan ninu awọn ẹka ti o ga julọ ti ayeye naa.

Chatta, eni ti won yan gege bi Osere Asiwaju to dara ju nitori ipa to ko ninu House of GAA lo padanu ami eye naa si owo osere tiata Femi Adebayo, eni to kopa ninu Seven Doors.

Ami eye AMVCA ikokanla iru re naa lo waye ni ale ojo Abameta, ni ipinle Eko.

Nigba ti o n soro lori eto Curiosity Made Me Ask, ti Isbae U gbalejo rẹ, Chatta so awọn ero rẹ nipa bi won se se asayan fun ẹbun naa.

Nigba ti agbalejo naa beere lọwọ rẹ, “Ṣe iwọ yoo sọ pe iwọ ko ni iwọn to dara fun iṣẹ rẹ ni? Nigba ti o ba de ile, gbadura pe ki o jawe olubori fun ami eye AMVCA,” oṣere naa dahun nirọrun, “Mi o nifẹẹ sii.”

Chatta tesiwaju pe, “Mi o le gbadura fun nnkan ti mi o nifẹẹ si. Nigba kugba ti mo ba nifẹẹ lati lọ si AMVCA, maa ṣe fiimu kan, maa si fi fiimu naa silẹ. Ki a le ṣe ayẹwo mi, ki wọn le ṣayẹwo boya mo yẹ fun ami-eye naa tabi rara. Ṣugbọn mi o fun wọn ni fiimu kankan ti won le e yan mi lati inu re.”