Sanwo-olu bá ẹbí Olu Jacobs sè’dárò

Sanwo-olu bá ẹbí Olu Jacobs sè’dárò

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-olu ti ba Joke Silva to jẹ iyawo oloogbe Olu Jacobs sedaro ọkọ rẹ to dagbere faye.
Gomina fi ọrọ ibanikẹdun yii ransẹ si ẹbi Oludotun Bayegun Jacobs ti gbogbo eniyan mọ si Olu Jacobs lati ọdọ olubani-damọralori iroyin, Ọgbẹni Gboyega Akọsilẹ.
Sanwo-olu ni orukọ agba osere naa ko le tete parẹ lorileede yii ati ni oke okun. O ni awọn ere akọnilọgbọn pọ ninu ere oloogbe naa.
Gomina ni Olu Jacobs kopa ninu ọpọlọpọ ere bii aadọta ọdun.
Olu Jacobs dagbere fun aye ni ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here