Ronaldo fẹ̀hìntì níbi bọ́ọ̀lù gbígbá fún Portugal ní ẹni ọdún 41
Mudasiru Alabi
Cristiano Ronaldo ti fẹ̀yinti kúrò nínú bọ́ọ̀lù gbígbá fún orílẹ̀-èdè rẹ̀ lẹ́yìn aawo tí ó wáyé láàárín òun àti ọ̀gá àwọn agbábọ́ọ̀lù Portugal, Jorge Jesus.
Agbábọ́ọ̀lù ọmọ ọdún mọ́kànlélógójì (41-year-old) náà ni aláyò tó pọ̀ jù lọ àti adarí fún orílẹ̀-èdè Portugal, níbi tí ó ti gba ayò mẹ́rindinlaadojo (146 goals) nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìgbà igba àti mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (234 appearances), ó sì gba ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ Yúróòpù (European Championship) ní ọdún 2016.
Sùgbọ́n ó fi ibùdó ìdánwò àwọn ará Portugal sílẹ̀ nígbà ìsinmi bọ́ọ̀lù àgbáyé tó kọjá lẹ́yìn tí kò rí àyè gbá rárá nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n ti borí orílẹ̀-èdè Norway pẹ̀lú ayò méjì sí ọ̀kan (2-1) nínú ìdíje Nations League.
Ìpinnu Ronaldo yìí wáyé láìpẹ́ lẹ́yìn tí won da duro fun osu kan gbako (30-day suspension) tí ajọ tó n sèjánu bọ́ọ̀lù ní orílẹ̀-èdè rẹ̀ fún un nítorí bí ó ṣe hùwà padà sí ọ̀ràn náà. Ní báyìí, ó ti pinnu láti gbé bọ́ọ̀lù rẹ̀ kọ́ sára ògiri.









