Tinubu gbóríyìn fún àwọn agbábọ́ọ̀lù ọ̀dọ́bìnrin U –

Tinubu gbóríyìn fún àwọn agbábọ́ọ̀lù ọ̀dọ́bìnrin U – 17 Naijiria

Mudasiru Alabi

Ife agbáyé ti awọn omọbìnrin tí kò tíì ju omọ odún mẹ́tàdínlógún lọ ti FIFA ọdún 2026 (2026 FIFA U-17 Women’s World Cup) tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Morocco, lẹ́yìn tí wọ́n lu orílẹ̀-èdè Brazil pẹ̀lú ayò mẹ́ta sí ọ̀kan (3-1) nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ sèmí-fínálì lọ́jọ́ Wẹside.
Eyi mu ki Aare Bola Tinubu gbe osuba rabade fun awon odobinrin naa. Aare ni ki won ri daju pe awon gbe ife eye Agbaye naa wale.
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Flamingos yóò bá orílẹ̀-èdè Japan fojú kojú nínú fínálì náà bí wọ́n ṣe ń wá ọ̀nà láti gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé, lẹ́yìn àṣeyọrí tó lárinrin tí wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ará Gúúsù Amẹ́ríkà (South Americans) náà.
Lẹ́yìn tí ìdajì àkọ́kọ́ parí láìsí ayò kankan, ẹgbẹ́ Flamingos ya àwọ̀n lẹ́nu ní ìṣẹ́jú karùndinlogọ́ta (55th minute) nípasẹ̀ Queen Joseph.
Nàìjíríà kò dẹwọ́ rárá láti tẹ̀síwájú nínú títẹ́ bọ́ọ̀lù mọ́ wọn lọ́wọ́, wọ́n sì tún fi kún ayò wọn. Awuwu Bashiru gba ayò kejì wọlé ní ìṣẹ́jú kọkànléláádọ́rin (71st minute) kí ó tó sọ ọ́ di méjì fún ara rẹ̀ nínú ìṣẹ́jú ọ́gọ́rin (80th minute) láti sọ ayò náà di mẹ́ta sí nǹkan (3-0). Brazil dín àmì-ayò náà kù ní kòpẹ́ kòpì sínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà nípasẹ̀ Greise ní ìṣẹ́jú kọkàndínlaadọ́rin (89th minute), sùgbọ́n ìyẹn kò tó láti dènà Nàìjíríà láti rí àyè tóótó fún fídíà fínálì náà gbé.
Lẹ́yìn àṣeyọrí ayò mẹ́ta sí ọ̀kan (3-1) tí wọ́n ṣe, ẹgbẹ́ Flamingos yóò kojú orílẹ̀-èdè Japan nínú fínálì pẹ̀lú èròńgbà láti gbé ife ẹ̀yẹ àgbáyé náà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe àṣeyori tó lárinrin ní sèmí-fínálì, Nàìjíríà yóò wá ọ̀nà láti mú agbára kun agbara lati iko Japan to duro laarin ife eye naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here