Ẹ ṣàmúlò àjọ̀dún àṣà yìí fún àgbénde ìwà ọmọlúàbí tí yóó bí àwùjọ ìfọ̀kànbalẹ̀–Mọ́gàjí Gbọ́lágadé

Ẹ ṣàmúlò àjọ̀dún àṣà yìí fún àgbénde ìwà ọmọlúàbí tí yóó bí àwùjọ ìfọ̀kànbalẹ̀–Mọ́gàjí Gbọ́lágadé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀lájú ó pójú ẹni ó fọ́, àìmọ̀kan lọ̀gá òpè.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ti fojú egbò tẹlẹ̀ tipẹ́ látàrí àìmọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ́ mọ́ àṣà àti ìṣe yorùbá. Àwọn tí ọ̀rọ̀ gbérù jù lásìkò yìí làwọn tó péraawọn lẹ́rú òyìnbó torí pé gbogbo ọ̀nà lòyìnbó fi kówọn lẹ́rú látàrí pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ ìgbàlódé, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ̀yìn sí àṣà àti ìṣe tó jọ mọ́ Orílẹ̀ wọn.Yorùbá gbà pé èèyàn tó sọ lé nù ,ó ti sọ àpò ìyà kọ́.
Ṣùgbọ́n lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, Akọ̀ròyìn Òwúrọ̀ ṣalábàápàdé ọmọ yorùbá àtàtà kan Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé Abíọ́dún Táíwò níbi àjọ̀dún Ọ̀sẹ̀ yorúbá tí ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì Adekunle Ajasin ṣe láti fìdí àṣà rinlẹ̀ síi bí i tìgbà ìwásẹ̀.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé tó jẹ́ Aṣojúdarí fún Fásitì Adekunle Ajasin ẹ̀ka tìlú ìbàdàn,èyí tó gbìlẹ̀ sí ọ̀gbà ilé-ẹ̀kọ́ olùkọ́ní Mufutau Lanihun sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ọ̀hún .
Ó ní gbígbé àṣà yorùbá lárugẹ yóó gbé àwọ ọ̀tun bá àwọn ìṣesí àjèjì tó n wọnú àṣà a wa.
Mọ́gàjí Abíọ́dún kò sàì gbóríyìn fún àwọn olúkọ̀ lẹ́ka ètò tó n kọ́ èdè yorùbá fún ìdúróṣinṣin wọn.
Ó tẹ̀síwájú pé, gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti n pè lòun ó ma jẹ́ wọn tóri pé ìtẹ̀síwájú ìṣe wọn yìí yóó so èso o re láti dá ìran yorùbá padà sípò iyì , ọlá,ògo tí ó ti nu àwùjọ yorùbá látàrí ìwà ọmọlúàbí tó kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ pòórá.
Ó wá kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé,kí gbogbo àwọn ẹ̀ka tó kú náà ló ànfàànì àjọ̀dún ọ̀sẹ̀ tó n lọ lọ́wọ́ yìí láti túbọ̀ tagbò ìwà ọmọlúàbí yíká ọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti pé èyí ni yóó mú ìfọ̀kànbalẹ̀ bá àwùjọ àti orílẹ̀ yìí lápapọ̀.
Lásìkó tó n gbẹnu gbogbo olùkọ́ ẹ̀ka èdè yorùbá sọ̀rọ̀, aṣojú ẹ̀ka náà Ọmọọba Ọlágúnóyé Nurudeen Adéwọlé gbóṣùbá káre fún Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé fún bó ṣe mú ọ̀rọ̀ ilé ẹ̀kọ́ Adekunle Ajasin ẹ̀ka tìlú ìbàdàn ní ṣinṣin.
Ó ní kò wọ́pọ̀ ìrúfẹ́ èèyàn tó káwè gboyè bíi tirẹ̀ tó tún mú ìwà ọmọlúàbí ní gbòógì.
Wọ́n panupọ̀ wúre fún Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbọ́lágadé pé kò ní-ín gbáyé lo kúkúrú ẹ̀mí àti pé ire orílẹ̀ yìí yóó ṣojú ẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here