Sanusi àti Bayero lórí oyè Emir Kano, nígun nígun lọ̀rọ̀ bóóde

Sanusi àti Bayero lórí oyè Emir Kano, nígun nígun lọ̀rọ̀ bóóde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Eruku ọ̀rọ̀ ń sọ lálá, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ di inú fu àyà fu bí ọ̀rọ̀ oyè Emir ìlú Kano ṣe gba ọ̀nà míì yọ lọ́jọ́ Àbamẹ́ta.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí Emir tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn, Muhammadu Sanusi II àti Emir tí wọ́n yọ nípò, Aminu Ado Bayero ṣe ń pe ara wọn ní ọba Kano.

Emir Sanusi II ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Kano, tó sì ti wà ní ààfin ìlú, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Emir tí ìjọba yọ nípò, Ado Bayero ti wà ní ààfin Nasarawa tó wà nínú ìlú Kano bákan náà.

Sanusi II tó wọ ààfin lórí ẹṣin pẹ̀lú họ̀bùrẹ́là lórí tó ṣàfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Emir Kano.
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Karùn-ún, 2024 ni gómìnà ìpínlẹ̀ Kano Abba Yusuf buwọ́lu òfin àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ náà.

Òfin tuntun náà pa ìdásílẹ̀ àwọn igun lọ́balọ́ba márùn-ún ìyẹ Kano, Bichi, Rano, Karaye àti Gaya tí Ganduje dá sílẹ̀ nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà.

Lẹ́yìn tó buwọ́lu òfin náà tán, gómìnà Yusuf kéde ìyànsípò Sanusi II padà gẹ́gẹ́ bí Emir Kano lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí Abdullahi Ganduje yọ́ nípò náà.

Ẹ̀wẹ̀, Bayero balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú Aminu Kano International Airport ní nǹkan bíi aago mẹ́rin àbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, tí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ sì lọ pàdé rẹ̀ tìlù tìfọn.

Nígbà tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń fèsì sí àṣẹ tí gómìnà Yusuf pa pé kí wọ́n fi kélé òfin gbé Emir Ado Bayero, wọ́n ní àṣẹ ilé ẹjọ́ tó ní kí ìjọba má tù ú àwọn lọ́balọ́ba náà ká ni àwọn máa tẹ̀lé.

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kano, Muhammad Hussain Gumel jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ri dájú pé ẹnikẹ́ni kò tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀, tó sì àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò máa ri dájú pé ààbò tó péye wà káàkiri ìlú Kano.

Ó ní òfin láà kalẹ̀ kedere pé ẹnikẹ́ni tó b’fẹ́ da omi àláfíà ìlú rú ni kí àwọn fojú rẹ̀ winá òfin, tí àwọn kò sì ní wo bí ẹni náà bá ṣe gàǹgà tó.

Gumel ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó bá ń gbèrò láti dá wàhálà sílẹ̀ lórí awuyewuye ìfaǹfà ọ̀rọ̀ oyè tó ń lọ ní ìlú náà pé kí wọ́n pa èrò náà rẹ́, kí wọ́n sì so agbéjẹ́ mọ́wọ́.

Ó ní ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ òfin bá bà pé ó da wáhàlá láàárín ìlú máa fi imú gbọ́ òórùn ara rẹ̀ àti pé gbogbo nǹkan ni àwọn ti ṣe láti ri pé àláfíà jọba ní ìlú náà.
Lẹ́yìn tí Emir tí wọ́n yọ nípò, Ado Bayero padà sí ìlú Kano ni àwọn kan ti ń fẹ̀sùn kàn pé olùbádámọ̀ràn ààrẹ Tinubu lórí ètò ààbò, Nuhu Ribadu ló ń ṣe àtìlẹyìn fún Bayero láti padà sí ìlú Kano.

Àmọ́ agbẹnusọ Ribadu, Zakari Mijinyawa ní irọ́ tò jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.

Mijinyawa tó sọ̀rọ̀ ní ìlú Abuja ń fèsì sí ẹ̀sùn tí igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Aminu Gwarzo fi kan Ribadu pé òun ló ní kí Bayero padà sí ìlú Kano.

Ṣáájú ni Gwarzo ti fẹ̀sùn kan Ribadu pé ó ń lo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti fi dúnkokò mọ́ àwọn èèyàn Kano, tó sì ní òfin tó de oè jíjẹ ní Kano jẹ́ èyí tó hàn gedegbe tí kò yẹ kí ará ìta dá sí rárá.

Agbẹnusọ Ribadu wá sọ àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé Ribadu kọ́ ló pèsè ọkọ̀ òfurufú tí Bayero fi padà sí Kano

Igbákejì ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Atiku Abubakar ní Emir tí wọ́n yọ nípò ní Kano, Ado Bayero kò ní padà sí Kano tí kò bá jẹ́ pé ó rí àtìlẹyìn ìjọba àpapọ̀.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí X rẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní èròńgbà láti fi da omi àláfíà ìlú Kano rú kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà àti pé bí ìjọba ṣe da àwọn ọmọ ogun sí ìgboro Kano lórí ọ̀rọ̀ oyè jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin orílẹ̀ èdè.

Atiku ní ìgbésẹ̀ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Kano láti mú àtúnṣe bá òfin tó de ọ̀rọ̀ oyè ní ìpínlẹ̀ náà, àti bí gómìnà ṣe dá Sanusi II padà bíi Emir jẹ́ àwọn nǹkan tó bá òfin mu.

Ó ní ó wá jẹ́ ohun fún òun pé Ado Bayero pẹ̀lú àtìlẹyìn ìjọba àpapọ̀ padà sí ààfin Nasarawa ìlú Kano nígbà tí Muhammadu Sanusi wà ní ààfin Gidan Dabo tó jẹ́ ojúlówó ààfinh gangan.

Ó ní ìjọba àpapọ̀ nílò láti rántí pé ìlú àláfíà ni Kano àti pé nígbà tí wọ́n yọ Sanusi lọ́sún 2020 kò sí wáhàlá kankan tó wáyé ní agbègbè náà, tí kò sì gbọdọ̀ sí wáhàlá kankan lásìkò yìí náà.

Bákan náà, ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria People’s Party (NNPP) ti ṣèkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ láti dènà pé àwọn fẹ́ kéde pé ìlú kò fararọ lórí ọ̀rọ̀ oyè Emir Kano.

Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà, Ladipo Johnson fi léde lọ́ja Àbámẹ́ta ní ìjọba ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ń lo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti fi tẹ ìfẹ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here