Boko Haram gbẹ̀mí èèyàn mẹ́jọ, jí ọgọ́jọ míràn gbé lọ nínú ìkọlù tuntun

Boko Haram gbẹ̀mí èèyàn mẹ́jọ, jí ọgọ́jọ míràn gbé lọ nínú ìkọlù tuntun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó jọ pé ojúmọ́ kan ìjàngbọ̀n kan lọ̀rọ̀ àwọn àgbébọn jínigbé wọ̀nyí bọ́rọ̀ ṣe di bóòlọ o yà fún mi ní ìlú Kuchi, ìjọba ìbílẹ̀ Munya ní ìpínlẹ̀ Niger bí àwọn tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram ṣe jí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn gbé.

Kò dín ní èèyàn ọgọ́jọ tí àwọn ajínigbé náà jí gbé.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Munya, Aminu Na-jume sọ fún àkọ̀ròyìn pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sá kúrò nínú ìlú, tí wọ́n sì fi ilé wọn sílẹ̀.

Ó ní àwọn ilé aṣàtìpò oríṣiríṣi ni awọn ti gbé kalẹ̀ lẹ́nu ìgbà tí ìkọlù náà wáyé àti pé irú ìkọlù bẹ́ẹ̀ kò ì tíì wáyé ní agbègbè àwọn rí.

Èèyàn mẹ́jọ ni àwọn agbébọn ọ̀hún dá ẹ̀mí wọn légbodò, tí wọ́n sì tún jí èèyàn ọgọ́jọ (160) gbé lọ.

Bákan náà ni wọ́n já àwọn ṣọ́ọ̀bù, tí wọ́n kó oúnjẹ atàwọn ohun èèlò mìíràn gẹ́gẹ́ bí alága náà ṣe sọ.

“Nígbà tí àwọn agbébọn náà dé, nǹkan bíi wákàtí méjì ni wọ́n fi se Indomie tí wọ́n jẹ ní ṣọ́ọ̀bù ẹni tó ń ta tíì, wọ́n mu tíì, wọ́n yáná láti fi pa òtútù nítorí inú òjò ni wọ́n wá.

“Lẹ́yìn náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní já ṣọ́ọ̀bù àwọn èèyàn, wọ́n kó ọtí ẹlẹ́rìndòdò, oúnjẹ, bisikíìtì àti ìrẹsì.”

Aminu Na-jume tún ṣàlàyé pé àwọn obìnrin, ọmọdé àtàwọn arúgbó, tó fi mọ́ olórí àwọn Hausa tó wà ní ìlú náà tó ń ṣàárẹ̀ wà lára àwọn 160 tí àwọn agbébọn náà jí gbé.

Ó fi kun pé bí àwọn agbébọn náà ṣe hùwà àti irú àwọn nǹkan ìjà olóró tó wà lọ́wọ́ wọ9n fi hàn pé wọ́n kìí ṣe agbébọn kékeré rárá.

Ó ní àwọn agbébọn náà mú àsíá ikọ̀ Boko Haram dání, tí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn náà sì jọ ti Boko Haram.

Àwọn èèyàn ìlú Kuchi rọ ìjọba àpapọ̀ àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti bá àwọn wá ojútùú sí bí àwọn agbébọn ṣe ń ṣèkọlù sí agbègbè wọn ní gbogbo ìgbà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here