A sì wà lórí Ìpinu N615,000 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ – Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìgbìmọ̀ onígun mẹ́ta tó n dúùnádúrà lórí owó osù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́ lorilẹede Nàìjíríà, tun tí fẹnu kò láti jókòó ṣe ìpàdé pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ lónìí ọjọ́ ìṣẹ́gun.
Etim Okon tíì ṣe igbákejì ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ TUC ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn NAN nílùú Abuja.
Níbi ìpàdé tó wáyé ṣáájú ni ìjọba àpapọ̀ ti kéde pé ẹgbẹ̀rún méjìdínláàdọ́ta Náírà ni òun lágbára láti san bíi owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́.
Èyí sì lo mú káwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ náà bínú jáde níbi ìpàdé náà pẹ̀lú àlàyé pé owó náà tàbùkù àwọn òṣìṣẹ́, tí wọn kò sì fi ẹnu ìjíròrò wọn kò síbi kan.
Àmọ́ Okon tí wá kéde pé ìjọba àpapọ̀ tí tọrọ àforíjì lórí ìkéde rẹ̀ náà, tí àwọn sí ti fẹnu kò láti ṣe ìpàdé mìíràn ni ọjọ́ ìṣẹ́gun, tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò sì péjú síbi ìpàdé náà.
“A ti béèrè N615,000 bíi owó oṣù tó kéré jùlọ fún òṣìṣẹ́ lọ́dọ̀ ìjọba níbi ìpàdé tó kọjá náà, ká tó bínú jáde, ìjọba kò sì tíì tako ìbéèrè wá.
A kàn tako N48,000 owó oṣù tó kéré jùlọ tíjọba gbé kalẹ̀ nítorí wọn kò ṣàlàyé fún wa bí wọn ṣe ṣírò owó ọ̀hún tó fi kú sí ìyè yìí.
Wọn kò bá wà ro owó ọkọ̀, iléègbé, oúnjẹ, owónàá àtìgbàdégbà, owó iná, ìlera, ètò ẹ̀kọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ wá rọ ìjọba láti kéde owó oṣù tó kéré jùlọ fún òṣìṣẹ́ to fẹ́ san pẹ̀lú àlàyé bó se ṣírò owó ọ̀hún, tó fi kú sí ìyè bẹ́ẹ̀.