Ó sàn k’ọ́mọ mi lọ sílé ọkọ ju kí àwọn ajínigbé gbé e lọ lọ́fẹ̀ẹ́’

‘Ó sàn k’ọ́mọ mi lọ sílé ọkọ ju kí àwọn ajínigbé gbé e lọ lọ́fẹ̀ẹ́’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ìṣòro bá pé méjì lórí ẹ̀mí, ó ṣeéṣe kí ìkan rọjú.
Láti ìgbà tí ìròyìn ti gbòde pé Abẹnugan ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Niger fẹ́ fi àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ọgọ́rùn-ún lọ́kọ ni awuyewuye ti ń wáyé lórí ìròyìn náà.

Ìròyìn tó gbòde ni pé Abẹnugan ọ̀hún ṣe àgbékalẹ̀ ìgbéyàwó náà gẹ́gẹ́ bí àkànṣe iṣẹ́ fún ẹkùn tó ń ṣojú ní ilé aṣòfin.

Èyí jẹ́ kí mínísítà fọ́rọ̀ àwọn obìnrin ní Nàìjíríà, Uju Keedy-Ohanenye tutọ́ sókè fojú gbà á, tó sì ní òun máa wọ́ Abẹnugan ilé aṣòfin náà, Abdulmalik Sakin-Daji lọ sílé ẹjọ́ àti pé òun máa ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà fínífíní.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Karùn-ún 2024 ló yẹ kí ìgbéyàwó náà wáyé àmọ́ ìjọba ti ní kí wọ́n da dúró fún ìgbà kan náà.

Àwọn òbí àti alágbàtọ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin náà bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí wọ́n fi fẹ́ fi àwọn ọmọ wọn lọ́kọ pẹ̀lú bí ọjọ́ orí wọ́n ṣe kéré.
Arábìnrin Asamau Shehu tó ń gbé ní ìlú Gulbin Boka jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òbí tó fẹ́ fi ọmọ wọn lọ́kọ.

Ó ní òun kò mọ ọjọ́ orí òun àmọ́ ó dá òun lójú pé ọmọ òun ti pé ọdún méjìlélógún, tó sì ti tó ẹni tó lè lọ sílé ọkọ àti pé òun fọwọ́ sí ìgbéyàwó náà.

Ó ní ipò tí àwọn wà ló ṣokùnfà ìdí tí àwọn fi ṣe ìpinnu náà.

Asamau Shehu, tó jẹ́ opó ṣàlàyé pé àwọn agbébọn máa ń yọ àwọn lẹ́nu gidi gan ní ìlú àwọn, tí àwọn sì ń kojú ìṣòro tó pọ̀ gan.

Ó kọminú pé ìjọba kò ya sí ìṣòro àwọn.

Ó fi kun pé ó tẹ́ òun lọ́rùn kí ọmọ òun wà níbi tí òun yóò ti máa ri ní gbogbo ìgbà, tí òun yóò sì fi ọkàn balẹ̀ pé ọmọ òun wà láyé, sàn ju kí àwọn agbébọn wá ji gbé lọ sí ibi tí òun kò ní ti máa ri.

“Ìbejì ni ọmọ mi yìí, ọdún tó kọjá ni ìkejì rẹ̀ lọ sí ilé ọkọ tí a sì gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrin náírà (N80,000) gẹ́gẹ́ bí owó orí lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀.

“Ìdí tí mo fi ń fi àwọn ọmọbìnrin mi lọ́kọ báyìí ni pé nígbà tí àwọn agbébọn yawọ ilé wa, tí wọ́n pa ọkọ mi, kò sí ẹni tó ràn wá lọ́wọ́.

“Àsìkò òjò ni àwọn nǹkan yìí máa ń ṣẹlẹ̀ jùlọ, ìyà ń jẹ wá, ẹnìkankan kò sì ràn wá lọ́wọ́, nígbà míì, owó igi tí àwọn ọmọ yìí bá ṣẹ́ tà la ma fi jẹun.”

Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun àtàwọn opó mìíràn mọ̀ pé fífi àwọn ọmọ àwọn lọ́kọ kò ní tán ìṣòro àwọn, ó ní ó tẹ́ àwọn lọ́rùn nítorí àwọn mọ̀ pé àwọn ọmọ wà níbi tó ní ààbò.

Asamau Shehu ní nígbà tí àwọn gbọ́ pé Mínísítà ní kí wọ́n ṣe ìdádúrò ìgbéyàwó náà, inú òun àtàwọn ìyá àwọn ọmọbìnrin tó kù kò dùn rárá.

“Ní ìlú Gulbin Boka, àwọn obìnrin bíi tèmi pọ̀ rẹpẹtẹ. Nígbà tí wọ́n sọ fun wá pé ìgbéyàwó náà kò ní wáyé mọ́, ọjọ́ mẹ́ta ni mi ò fi rí oorun sùn àfi ìgbà tí wọ́n ní wọ́n tún máa ràn wá lọ́wọ́ lórí ìgbéyàwó náà.”

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó ṣe àgbékalẹ̀ ètò náà nítorí ọ̀pọ̀ ọmọ àwọn tó wà ní àhámọ́ àwọn agbébọn ló ṣì wà níbẹ̀ títí di àsìkò yìí.

Ó ní àwọn ọmọ tí àwọn agbébọn jígbé ní Mariga tó jẹ́ oríkò Gulbin Boka Kumbashi àtàwọn ìlú míì ló ṣì wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé, tí àwọn kò mọ nǹkan tí yoò ṣẹlẹ̀ sí wọn.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí pé àwọn kò rán àwọn ọmọ lọ sílé ẹ̀kọ́, Asamau ní kò sí ilé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àwọn kò sì ní ọgọ́rùn-ún náírà láti fún àwọn ọmọ àwọn láti fi ṣowó àpò àti pé tí àwọn bá rí ọgọ́rùn-ún náírà àwọn máa fi jẹun ni.

Ó fi kun pé tí mínísítà bá fẹ́ ran àwọn lọ́wọ́, ó ní ó yẹ kó wá bá àwọn tún ilé ẹ̀kọ́ àwọn ṣe, kò sí ri dájú pé wọ́n ń pèsè ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nítorí àwọn ọmọ tì kó ní òbí pọ̀ ní ìlú àwọn.

Bákan náà ló rọ ìjọba láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn opó táwọn agbébọn pa ọkọ wọn ní ìlú náà nítorí ọ̀pọ̀ wọn ló ti ń ta ilé àti ọ̀nà wọn láti fi jẹun.

Mínísítà fọ́rọ̀ obìnrin ní Nàìjíríà, Uju Kennedy-Ohanenye ti kéde fífún àwọn ọmọbìnrin ọgọ́rùn-ún tí Abẹnugan ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Niger fi lọ́kọ ní ẹ̀bùn àti ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ṣáájú ètò ìgbéyàwó wọn.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Karùn-ún ni ìgbéyàwó ọ̀hún wáyé.

Abẹnugan ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Niger, Abdulmalik Sarkindaji ló ṣe agbátẹrù ìgbéyàwó fún àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ọgọ́rùn-ún ọ̀hún tí kò ní òbí láyé mọ́.

Ṣáájú ni Mínísítà náà ti lòdì sí ìgbéyàwó ọlọ́pọ̀ èrò ọ̀hún, pé ó lòdì sí ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé.

Kennedy-Ohanenye tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní Abuja nígbà náà ní òun ti kọ̀wé ránṣẹ́ sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti ṣe ìdádúrò ìgbéyàwó náà.

Àmọ́ nígbà tó ń fèsì, Abẹnugan náà ní Mínísítà náà ń dá sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti àṣà tí kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀.

Ó ní Mínísítà náà kò ṣe ìwádìí láti mọ ìdí tí àwọn fẹ́ fi gbé ìgbésẹ̀ náà àti ìṣòro tí àwọn ọmọbìnrin náà ń kojú léyìí tó ṣokùnfà ìdí tí àwọn fẹ́ fi wọ́n lọ́kọ.

Bákan náà ni ìgbìmọ̀ àwọn Alfa àti Imam ti Abẹnugan náà lẹ́yìn tí gbogbo wọn sì ṣèkìlọ̀ fún Mínísítà náà àti pé ìgbéyàwó náà yóò tẹ̀síwájú.

Ṣùgbọ́n ní báyìí, Mínísítà náà ti wá rán olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, Adaji Usman lọ sí ìpínlẹ̀ Niger láti kéde ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ náà, tó sì tún fún wọn ní aṣọ àti oúnjẹ.

Ní ààfin Emir ìlú Kotangora, Mohammed Muazu ni Mínísítà náà ti kéde àwọn ẹ̀bùn náà.

Bákan náà ló fún àwọn ọmọbìnrin náà ní maáṣìnì POS mẹ́wàá, aṣọ ọgọ́rùn-ún àti báàgì ìrẹsì oní 10kg 350.

Ó ní ẹni tó bá ṣetán láti kẹ́kọ̀ọ́ dé ìpele ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ni àwọn máa ṣe àtìlẹyìn fún.

Emir Kotangora náà fún àwọn ọmọbìnrin náà ní maáṣìnì ìránṣọ kọ̀ọ̀kan.

Mínísítà fọ́rọ̀ obìnrin ọ̀hún tún ní kí wọ́n ṣí akoto owó báǹkì fún àwọn ọmọbìnrin náà tí òun yóò máa san owó sí fún oṣù mẹ́fà gẹ́gẹ́ bí ìrànlọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá dé ilé ọkọ wọn tán.

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun kò ní èròńgbà láti dá ìgbéyàwó náà dúró tẹ́lẹ̀ bíkòṣe pé òun fẹ́ ṣe ìwádìí láti mọ̀ bóyá àwọn ọmọbìnrin náà tí tó láti lọ sílé ọkọ.

Ó ní àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ló ṣi òun gbọ́ tí èdè àìyedè fi fẹ́ wáyé láàárín òun àti Abẹnugan ilé aṣòfin náà.

Ó sọ pé gbogbo òbí ló máa ń wù láti sin ọmọ wọn lọ sílé ọkọ nígbà tí àsìkò rẹ̀ bá ti tó.

Nígbà tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Abẹnugan náà fún ọ̀nà tí wọ́n gbà láti parí èdè àìyedè ọ̀hún àti pé òun máa ṣe àmójútó àwọn ọmọbìnrin náà nígbà tí wọ́n bá dé ilé ọkọ wọn tán láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n ṣe àmúlò àwọn ohun èlò tí wọ́n fún wọn dáadáa.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Abẹnugan ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Niger tó ṣe agbátẹrù ìgbéyàwó náà ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún òun pé àwọn kan ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ìgbéyàwó náà.

Ó ní inú òun dùn báyìí pé gbogbo ayé ti rí pé àwọn ọmọbìnrin ọ̀hún ti tó láti lọ sílé ọkọ àti pé kò sí ẹni tó mú wọn ní dandan.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Mínísítà fún àtìlẹyìn tó ṣe fún àwọn ìyàwó tuntun náà, tó sì ṣàlàyé pé gbogbo àyẹ̀wò tó yẹ kí àwọn ọmọbìnrin náà ṣe ni àwọn ti ṣe fún wọn

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here