Ìyà di méjì, ọ̀daràn ń pa ọlọ́pàá, àjọ PENCOM tó ń rí sí owó ìfẹ̀yìntì náà ń f’ebi pa wọ́n

Ìyà di méjì, ọ̀daràn ń pa ọlọ́pàá, àjọ PENCOM tó ń rí sí owó ìfẹ̀yìntì náà ń f’ebi pa wọ́n

Fẹ́mi Akínṣọlá

Awọn ọlọpaa to ti fẹyinti ninu isẹ ijọba ti pariwo sita si ijọba apapọ ati ile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja lati wa wọrọkọ fi sadaa lori bi ajọ to ń mojuto ọrọ to jẹ mọ owo ifẹyinti awọn ọlọpaa se n fi ebi pa awọn.

Awọn ọlọpaa to ti fẹyinti ọhun ni wọn ko iwọde wọn lọ si ile igbimọ aṣofin agba l’Abuja lati rawọ ẹbẹ si wọn nipa sise ofin ti yoo yọ awọn oṣiṣẹfẹyinti ọlọpaa kuro ni ajọ PENCOM to n mojuto owo ifẹyinti awọn osisẹ lorilẹ ede Naijiria.

Wọn ni ki ijọba ṣe ofin ti yoo da ajọ ti yoo maa mojuto ọrọ owo ifẹyinti awọn ọlọpaa nikan silẹ.

Diẹ lara awọn ọlọpaa to ti fẹyinti naa sọ pe bi ogun ẹgbẹrun naira ni lawọn maa n sabaa n gba losu, nigba miran awọn kii gba owo kankan rara.

Igbakeji alaga igbimọ nile igbimọ asofin agba fun awọn ọlọpaa to fẹyinti , Sẹnẹtọ Yinusa Akintunde lati ipinlẹ Ọyọ naa sọ pe eleyii ki i se akọkọ ti wọn kọkọ maa fi ehonu wọn han lori igbesẹ yii.

O ni ”ẹtọ awọn ọlọpaa to fẹyinti yii ni wọn n beere fun, ki wọn lee maa ri owo ifẹyinti wọn gba lasiko, kii se pe igba to ba yẹ ki wọn maa jẹun lo jẹ pe igba yẹn ni iṣoro yoo tun de ba wọn”.

O tẹsiwaju pe ẹẹmeji laarin ọsẹ to kọja ni ile igbimọ asofin mejeeji se ipade pọ lori ọrọ wọn.

Awọn yoo si gbe igbesẹ lati wa ojutuu si ọrọ naa laipẹ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here