l’Osun, àwọn ọ̀dọ́ bínútán lórí ọ̀wọ́ngógó epo, iná mọ̀nàmọ́ná àti oúnjẹ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ó jọ pé ara ti kan àwọn ọ̀dọ́ yìí ju ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lọ báyìí pẹ̀lú bí ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ̀ kan tí wọ́n pè ní “Coalition Concern Youths” ti ṣe ìwọ́de lórí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ, iná mọ̀nàmọ́ná àti epo bẹnitiró.
Ìwọ́de ọ̀hún ló wáyé nílùú Osogbo níìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Orin tó gba ẹnu àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún ni pé, “ebi ń pa wá, kò sówó, kò sí ààbò lórí ẹ̀mí àti dúkìá mọ́ ní Nàìjíríà.”
Wọ́n tún ń kọrin pé “Olúwa fa ìjọba tó níwa lára yaa, kí O wó ìjọba ọ̀hún lulẹ̀ pátápátá.”
Owolabi Hassan,tó jẹ́ aṣíwájú àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún ti sọ pé àwọn fẹ́ kì ìjọba Bola Tinubu dá owó epo bẹnitiró àti owó iná mọ̀nàmọ́ná padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ kí ara lè rọ aráàlú.
Wọ́n tún sọ pé àwọn kò fẹ́ owó ìrànwọ́ tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ yà àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
Hassan tún tẹ̀síwájú pé, owóyàá ọ̀hún kò lè tàn ìsoro wọn rárá.
Ó ní àwọn fẹ́ kí ìjọba Bola Ahmed Tinubu ró àwọn ọ̀dọ́ lágbára nípa pípèsè isẹ́ fún wọn.
Hassan tún ṣàlàyé pé, ìyà tó n jẹ àwọn ọ̀dọ́ àti aráàlú ní Nàìjíríà ti peléke síi lásìkò ìjọba Bola Ahmed Tinubu.
Ajàáfẹ̀tọ́ ọmọnìyàn kan, Waheed Lawalda tó wà níbi ìwọde náà ní àwọn ọ̀dọ́ nìkan kṣ ni ọ̀rọ̀ ọ̀hún kan, bẹ́ẹ̀ ni kìí se ọ̀dọ́ nìkan ló yẹ kó ṣe ìwọ́de.
Waheed sọ pé “gbogbo wa ló yẹ kó se ìwọ́de lórí ìnira tó dojú kọ wá ní Nàìjíríà, kìí ṣe ọ̀dọ́ nìkan.
“Ọ̀nà àbáyọ tí àwa ọmọ Nàìjíríà ní ní kí gbogbo wá jáde fún ìwọde lórí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiró, iná mọ̀nàmọ́ná àti ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ.
Waheed Lawal wá rọ àwọn agbófinró láti máa pèsè ààbò fún àwọn olùwọ́de dípò kí wọ́n máa dá wọn dúró lásìkò ìwọ́de náà.