Agbẹjọ́rò wọ́ Adelabu lọ sílé ẹjọ́ fún pínpín iná mọ̀nàmọ́ná sí ìsọ́rí

Agbẹjọ́rò wọ́ Adelabu lọ sílé ẹjọ́ fún pínpín iná mọ̀nàmọ́ná sí ìsọ́rí

Fẹmi Akínṣọlá
Ohun tó kojú sí ẹnìkan, ẹyìn ló k sí elòmíràn.
Agbẹjọ́rò ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kan tó fi ìlú Eko ṣe ibùjókòó, Kabir Akingbolu ti wọ́ mínísítà fétò ohun àmúṣagbára, Adebayo Adelabu àtàwọn méjì míì lọ sílé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ohun tí agbẹjọ́rò náà ń fẹ̀sùn kan Adelabu àtàwọn tó pè lẹ́jọ́ ni pé wọ́n ń tẹ ẹ̀tọ́ òun lójú mọ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe pín iná mọ̀nàmọ́ná sí ìsọ̀rí oríṣìí márùn-ún.

Ó ní kí ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé kí wọ́n máa fún gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà ní iná mọ̀nàmọ́ná bákan náà nítorí pé orí kò ju orí lọ.

Nínú ìwé ìpẹ̀jọ́ tó gbé lọ sí ilé ẹjọ́ ní ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹrin, ọdún 2024, Akingbolu ní pínpín iná mọ̀nàmọ́ná sí ìsọ̀rí oríṣìí márùn-ún pẹ̀lú àsìkò tí àwọn èèyàn yóò fi máa lo iná tó yàtọ̀ síra wọn jẹ́ ohun tí kò dára rárá, tí kò sì bá òfin mu àti títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀.
Àwọn mìíràn tí Akingbolu tún pé lẹ́jọ́ ni àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná Nàìjíríà, Nigeria Electricity Regulatory Commission (NERC) àti Ikeja Electricity Distribution Company (IKEDC).

Ó fẹ̀sùn kan àwọn tó pè lẹ́jọ́ náà pé pínpín àwọn àwọn sí ìsọ̀rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lòdì sí ìwé òfin Nàìjíríà tí kò fi ààyè gba ẹnikẹ́ni láti dẹ́yẹ sí èèyàn.

Ó fi kun pé wọ́n tàpá sí òfin orí kẹrin, abala kejìlélógójì ìwé òfin Nàìjíríà ti tọdún 1999.

Ìgbésẹ̀ Akingbolu yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí iléeṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná kéde ní ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹrin ọdún 2024 pé àwọn ti fi kún owó iná mọ̀nàmọ́ná àti pé àwọn ti pín bí àwọn yóò ṣe máa pèsè iná fún àwọn ènìyàn sí ìsọ̀rí A, B, C, D àti E.

Ó ní àwọn tí àwọn iléeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná náà ń fún ní iná wàkátì méjì sí mẹ́rin lójúmọ́ ni wọ́n ti sọ sínú ìyà pàápàá lásìkò yìí tí ooru àmújù ń bá Nàìjíríà àti gbogbo àgbàyé fínra lórí àyípadà ojú ọjọ́.

Akingbolu ní kìí ṣe ohun tó wu etí gbọ́ pé àwọn kan yóò máa lo iná mọ̀nàmọ́ná fún ogún wàkátì lójúmọ́ nígbà tí àwọn kan kò ní ní ju iná wàkátì mẹ́rin lọ.

Ó wá rọ ilé ẹjọ́ láti pa á láṣẹ́ fún NERC láti ìgbésẹ̀ náà padà kí wọ́n sì máa fún gbogbo ènìyàn ní iná bákan náà àti iye àsìkò kan náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here