Ìdí tí ọjọ́ kìíní oṣù Karùn-ún fi jẹ́ ọjọ́ àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lágbàáyé

Ìdí tí ọjọ́ kìíní oṣù Karùn-ún fi jẹ́ ọjọ́ àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́ lágbàáyé

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Ọjọ́ àkọ́kọ́, ọjọ́ kìíní nínú oṣù Karùn-ún ni wọ́n yà sọ́tọ̀ láti mọrírì ìgbìyànjú àti ìlàkàkà àwọn òṣìṣẹ́ káàkiri àgbáyé.

Lọ́dọọdún, tí ọjọ́ yìí bá pé, ìfẹ̀hònúhàn máa ń wáyé káàkiri àgbáyé . Àwọn aṣojú oṣiṣẹ gbogbo máa bèèrè ìtọjú tó péye, àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ máa ń dá sí i. Àwọn ajàfẹ̀tọ́ọ̀ ọmọnìyàn àtàwọn tí wọ́n ń fẹ́ ayípadà ló máa ń lọ́wọ́ sí àyájọ yìí nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀ẹ̀rẹ̀.

Orílè-èdè Amẹ́ríkà ní wọn ti ń fẹ̀hónúhàn jù lórí àwọn òṣìṣẹ́, ọjọ́ Mọ́ńdè àkọ́kọ́ nínú oṣù kẹsàn-án ni wọ́n máa ń ṣe tiwọn. Ní ọdún 1886, àwọn aṣojú òṣìṣẹ́ l’Ámẹ́ríkà bẹ̀rẹ ìyanṣẹ́lódì, wọ́n ń bèèrè fún wákàtí mẹ́jọ lójúmọ́ láti ṣiṣẹ́. Wọ́n ṣe èyí ní ìbámu pẹ̀lú àtúntọ̀ tí òyìnbó Gẹ̀ẹ́sì kan, Robert Owen, gbé kalẹ̀. Robert ló gbé ètò iṣẹ́ àti ìsinmi lẹ́yìn iṣẹ́ kalẹ̀, ó pè é ní Wákàtí mẹ́jọ iṣẹ́, mẹ́jọ ìdárayá àti mẹ́jọ ìsinmi (“eight hours’ labour, eight hours’ recreation, eight hours’ rest”). Ṣé nígbà náà, iṣẹ́ laago ń ṣe kú ni, kò sì sí ààyè ìsinmi rárá ní àwọn iléeṣẹ́ gbogbo.

Ìyanṣẹ́lódì tó lágbára jùlọ, wáyé lọ́jọ́ àkọ́kọ́ oṣù karùn
-ún, kò sì dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì òṣìṣẹ́ (40,000 workers) tí wọ́n kóra wọn jọ láti daṣẹ́ sílẹ̀. Ní gbogbo ìgbà náà, Chicago ni òkun ọrọ̀ ajé Amẹ́ríkà, ibẹ̀ sì ni àwọn oníléeṣẹ́ pọ̀ sí jùlọ. Ìdaṣẹ́sílẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ náà kò wáá tu irun kan lára àwọn tó gbà wọ́n ṣíṣẹ́, wọn kò dá wọn lóhùn. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ẹgbẹ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ mì-ín tún darapọ̀ mọ́ ìdáṣẹ sílẹ̀ náà.

Ó padà di ìfẹ̀hònúhàn ti ó wáyé, tí ẹnìkan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà táwọn ọlọ́pàá ṣíná ìbọn bolẹ̀, èèyàn púpọ sì farapa. Ìfìyàjẹni àwọn ọlọ́pàá yìí ló mú àwọn olórí òṣìṣẹ́ ṣètò ìfẹ̀hònúhàn mì-ín, èyí tó wáyé lọ́jọ́ kẹrin oṣù
karùn-ún, ní gbàgede gbajúgbajà ọjà Chicago, Haymarket Square. Níbẹ̀ lẹnìkan tí wọn ò mọ̀ dònìí yìí ti ju bọ́m̀bù lu àwọn ọlọ́pàá, ọlọ́pàá méje (7) kú, mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (67) sì farapa. Bákan náà, mẹ́rin nínú àwọn tí bọ́m̀bù náà bà pàdánù ẹ̀mí wọn, èèyàn ọgbọ̀n (30) mì-ín sì farapa. Lẹ́yìn rògbòdìyàn yìí, èèyàn mẹ́jọ ni wọ́n dajọ ikú fún nínú àwọn tó bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hònúhàn náà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rídìí ẹ̀ fi múlẹ̀ pé wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn, síbẹ̀, ẹ̀mí wọn lọ sí i.

Nígbà tó wáá di ọdún 1889, ọdún kẹta lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ìpinnu kan wáyé láti ṣèrántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ́jọ́ àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́. Gbogbo àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tọ́rọ̀ náà kàn ló péjú, aṣojú òṣìṣẹ́ sì wá láti orílẹ̀-èdè ogún (20
countries). Rògbòdìyàn tó ṣẹlẹ̀ ní Chicago yìí ló jẹ́ ìwúrí àti ìṣípayá fáwọn yòókù tí wọn kò tí ì darapọ̀ mọ́ wọn tẹ́lẹ̀. Àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sàmi ọjọ́ yìí.

Ní Gúúsù orílẹ̀-èdè Yúróópù, àwọn èèyàn Slovenia àti Croats ni wọ́n kọ́kọ́ ṣayẹyẹ ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́. Iṣẹ́ àṣelàágùn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí pẹ̀lú owó táṣẹ́rẹ́ tí wọ́n ń san fún wọn, ló mú àwọn èèyàn Serbia ṣètò ìwọ́de tiwọn ní ọdún 1893. Àyájọ́ àwọn òṣìṣẹ́ gan-an ni wọ́n gbé ìwọ́de náà sí.

Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé àkọ́kọ́ parí, tí ayípadà rere ti ń bá àwọn òṣìṣẹ́, tí ìdàgbàsókè ti ń dé pẹ̀lú ìyànjú àwọn ajàfẹ́tọ́ọ̀ ọmọnìyàn ní Russia, ó dohun tí àwọn òṣìṣẹ́ ń bèèrè ohun gbogbo tó tọ́ sí wọn káàkiri ayé. Ní Germany, àyájọ́ òṣìṣẹ́ di ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, ní ọdún 1933, lẹ́yìn ìgbà tí ẹgbẹ́ Nazi gbàjọba. Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, tó di àjàyé, ohun gbogbo yípadà lórí àtẹ àgbáyé. Ètò òṣèlú àti ọrọ̀ ajé dohun tí wọ́n sàmì rẹ̀ dáadáa.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni wọ́n fi ń ṣayẹyẹ ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Cuba, Soviet Union ayé ọjọ́un àti China. Wọ́n yà á sọ́tọ̀ bíi ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ ìsinmi pàtàkì. Bí wọn yóò bá ṣayẹyẹ náà, gbàgede tó tẹ́jú ni wọn máa ń lò; bíi irú èyí tí wọ́n ṣe ní gbàgede Red
Square, ni Moscow. Àwọn èèyàn ńlá ńlá nílùú ló máa ń péjú síbẹ̀, ó sì tún dúró bíi agbára ológun àwọn Soviet.
Àwọn ajàfẹ́tọ́ọ̀ gbàgbọ́ pé sísàmì ọjọ́ òṣìṣẹ́ àti yíya ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún ìsinmi yóò jẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ Europe àti Amẹ́ríkà parapọ̀ láti bèèrè ẹ̀tọ́ wọn. Ní Yugoslavia, àwọn náà kéde àyájọ́ òṣìṣẹ́ ní ọdún 1945. Wọ́n yan bíi ológun ṣájọyọ̀ náà, wọ́n sì kéde rẹ̀ fúngbà pípé. Káàkiri ayé lónìí, níṣe ni àwọn òṣìṣẹ́ máa ń bèèrè ẹ̀tọ́ wọn ní gbogbo àyájọ́ tí wọ́n fi sọrí wọn yìí. Awọ kò ká ojú ìlù. Ó ṣe pàtàkì láti fún wọn lóhun tó tọ́ sí wọn, pẹ̀lú bí ìṣẹ àti òṣì ṣe pọ̀ nílẹ̀, tí àwọn mì-ín kò sí ríṣẹ́ kankan ṣe.

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló jẹ́ pé àfikún owó oṣù tí wọ́n ń san fún òṣiṣẹ kò mú ìyàtọ̀ kankan bá, nítorí ojoojúmọ́ ni ohun tí wọ́n nílò ń wọ́n sí i gẹ́gẹ́ bí àjọ International Labour Organization (ILO) ṣe ṣàlàyé nínú àfojúsùn wọn fún ọdún 2024. Lọ́dún tó kọjá, òǹkà àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń gbé nínú ìṣẹ́ àti òṣì tó lágbára tún gùnkè sí i ni. Àwọn tí ìyà tó ń jẹ wọ́n mọ níwọ̀n nínú àwọn òṣìṣẹ́ ń pọ̀ sí i ni. Ìdá mẹ́jọ ààbọ̀ mílíọ̀nù (8.4m) ni àjọ ILO pè wọ́n báyìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here