Ọlọ́run ṣeun! Pásítọ̀ ìjọ Rìdíìmù ti gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé tí wọ́n ji gbé.

Ọlọ́run ṣeun! Pásítọ̀ ìjọ Rìdíìmù ti gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé tí wọ́n ji gbé.

Ọlámídé Motúnráyọ̀

Orin ìdúpẹ́ lórísirísi ló gbẹnu àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, olólùfẹ́ àti ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ Rìdíìmù lápapọ̀ fún oore ìdásílẹ̀ tí ọlọ́run ṣe fún Pásítọ̀ ìjọ wọn, Olùṣọ́àgùtàn Olúgbénga Ọláwore, ẹni tí àwọn ajínigbé jí gbé, ṣe ti jáde níbùbá àwọn olubi èèyàn ajínigbé náà.

Báyìí Pásítọ̀ Ọláwore, alákòóso ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ń pè ní Heavens Gate Parish, Redeemed Christian Church of God, ìyẹn, ẹka ìjọ Rìdíìmù, tó wà lọ́nà Àgbàrá sí Lusada, nípínlẹ̀ Ògùn, ẹni tí àwọn ajínigbé jí gbé pẹ̀lú àwọn èrò mẹ́tàlá yòókù tí wọ́n jọ wà nínú bọ́ọ̀sì kan náà.

Pásítọ̀ yìí ló pàdánù ìyá ẹ̀, tó ń jẹ́ Díákónì Deborah Ọláwore láìpẹ́ yìí, tó sì lọ sílùú Ìpàpo, nípínlẹ̀ Ọ̀yọ́, láti ṣètò bí ayẹyẹ ìkẹyìn ìyá rẹ̀ náà tí wọ́n fi sí Fúráídèé, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n (26), oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí, àti Fúráídèé, ọjọ́ kẹta, oṣù Karùn-ún ọdún yìí, yóò ṣe dùn, tí yóò sì lárinrin, kó tóó kàgbákò àwọn jàndùkú agbébọn tí wọ́n ji gbé lórí ìrìn-àjò rẹ̀ padà sílùú Èkó.

Mílíọ̀nù mẹ́wàá Náírà la gbọ́ pé àwọn olubi èèyàn náà ń bèèrè pé kí àwọn ẹbí rẹ̀ san fún àwọn kí àwọn tóó lè fi sílẹ̀, tí kò sì jọ pé ìrètí wà rárá fún òjíṣẹ Ọlọ́run náà láti bọ́ nínú ìgbèkùn àwọn ajínigbé tó há sí láti nnkan bíi aago marun-un ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Jímọ̀ tó ti há síbùbá wọ́n
Ṣùgbọ́n lọ́sàn-án ọjọ́ Àìkú, Sánńdè, ọjọ́ kọkànlélógún (21), oṣù yìí, nìròyìn ayọ̀ gbòde kan pé àwọn agbófinró ti gba Pásítọ̀ náà sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹrúukú.

Ọ̀gá àgbà àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ACP Adébọ́lá Hamzat, ti sọ ṣáájú tó sì ṣèèrì pé òun yóò gbé ìgbìmọ̀ atọpinpin kan dìde láàrin àwọn ọlọ́pàá láti gba
àwọn arinrìnàjò náà sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú, Sánńdè, ọjọ́ kọkànlélógùn (21), oṣù yìí, ni Kọmísánnà fètò ìròyìn nínú ìjọba Gómìnà Ṣèyí Mákindé tìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọmọọba Dọ̀tun Oyèadé, kéde pé CP Hamzat, ti ṣàṣeyọrí lórí ìlérí tó ṣe nípa òmìnira òjíṣẹ Ọlọ́run náà. Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “Gbogbo bó ṣe ń lọ là ń bèèrè lọ́wọ́ ọ̀gá àgbà àwọn ọlọ́pàá nípa aktiyan wọn láti gba àwọn tí wọ́n jí gbé sílẹ̀, wọ́n sì fi tó ìjọba
létí pé àwọn ti gba Pásítọ̀ ìjọ Rìdíìmù yẹn sílẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ikọ̀ agbófinró ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́”.

Ó wá fi dá àwọn ará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lójú láti fọkàn balẹ̀ nípa ètò ààbò, nítorí àwọn ọlọ́pàá àtàwọn agbófinró ìpínlẹ̀ náà kápá ètò ààbò ìpínlẹ̀ yìí dáadáa. Ṣùgbọ́n ohun tí kọmíṣánnà náà kò mẹ́nu bà nínú àtẹ̀jáde rẹ̀ ọ̀hún ni bóyá àwọn agbófinró rí ẹlòmí-ìn gbà sílẹ̀ nínú àwọn arirìn-àjò yòókù tí wọ́n jí gbé pẹ̀lú Pásítọ̀ ìjọ Rìdíìmù náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here