L’ órí agbófinró tó pa èèyàn kan l’Eko, iléesẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ̣ìwádìí.

L’ órí agbófinró tó pa èèyàn kan l’Eko, iléesẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ̣ìwádìí.

Gbọ́láhàn Quseem

À fi bí èèdì ni ọ̀rọ̀ jẹ́ fún rìpẹ́tọ̀ Taofeek tó jẹ́ ọlọ́pàà lágbègbè Ajah, ní ìpìnlẹ̀ Èkó,bó ṣe f’ọ̀bẹ gún arákúnrin kan, Olóògbè Anosikwe Patrick, pa nínú oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí.
Ní báyìí,Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ bí rìpẹ́tọ̀ ọ̀hún ṣe gbérú ìgbéṣẹ̀ bẹ́ẹ̀.

A rigbọ pe oloogbe ati ọlọpaa ọhun wa nile itaja igbalode kan ti wọn n pe ni Skymall, to wa lagbegbe Ajah, ọrọ ti ko to nkan lo dija silẹ laarin ọlọpaa yii ati oloogbe naa, k’awọn to wa nitosi si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, agbofinro ọhun ti fọbẹ aṣooro ọwọ rẹ gun oloogbe pa patapata.

lṣẹlẹ ọhun lo mu ki idarudapọ waye ninu ọgba ile itaja igbalode naa, t’awọn araalu si n sa asala fun ẹmi wọn nitori ti wọn ko mọ ohun to le ṣẹlẹ lọjọ yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to f’ idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun akọroyin wa sọ pe, awọn ti mu alakooso eto aabo ile itaja igbalode naa, awọn si ti n ṣe iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ati pe ọdọ awọn ni ripẹtọ Taofeek to gun arakunrin ọhun pa wa bayi to n ran awọn lọwọ ninu iwadii awọn.

Alukoro ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ Eko, C.P Adegoke Fayoade, ti paṣẹ pe ki awọn tuṣu desalẹ ikoko lori iṣẹlẹ naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here