Àgbáríjọpọ̀ orílẹ̀-èdè Áfíríkà bẹ̀rẹ̀ ìpàdé alágbára lórí wíwú egbò ìgbésùnmọ̀mí.

Àgbáríjọpọ̀ orílẹ̀-èdè Áfíríkà bẹ̀rẹ̀ ìpàdé alágbára lórí wíwú egbò ìgbésùnmọ̀mí.

Gbọ́láhàn Quseem

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ba àwọn olórí orílẹ̀-èdè nílẹ̀ aláwọ̀ dúdú se ‘pàdé pọ̀ ní
‘llú Abuja lórí dídẹ́kun ìwà ìgbésùmọ̀mí àti ìdúnkoòkòmọ́ni nìlẹ̀ Áfíríkà.

Odidi ọjọ meji ni ipade naa yo fi waye, eyi ti awọn olori orilẹ-ede nilẹ adulawọ yo peju se.Akori ipade apero naa, ti aarẹ Bola Tinubu bawọn side rẹ ni “Riro okun ajọsepọ laarin awọn orilẹ-ede lagbara si ati sise agbega awọn ileesẹ ti yoo tẹ ori ‘wa igbesunmọmi ba”.

Ọọfisi oludaninimọran fun Aarẹ Naijiria lẹka eto aabo lo se agbekalẹ ipade apero naa.

Afojusun ipade apero naa si ni lati mu ki igbesẹ gbigbogun ti iwa igbesunmọmi le koko si laarin awọn orilẹ-ede Afirika, lati ipasẹ ajọsepọ ileesẹ ologun, ki wọn si dẹkun bi ohun ija oloro ati owo se n kọja lati orilẹ-ede kan si omiran lati se atilẹyin f’awọn ọdaran.

Ipade apero yi si lo n waye lasiko yi ti ọpọ orilẹ-ede nilẹ Afirika n koju iwa idunkookomọni lẹka eto aabo lati ọwọ awọn ajijagbara ẹsin Islam ati agbebọn, paapaa lawọn agbegbe asalẹ Sahara.

Orilẹ-ede Nigeria to n gbalejo ọọfisi ajọ isọkan agbaye to n gbogun ti iwa titako igbesunmọmi, lo n dari ipade naa.

Ileesẹ ologun Naijiria si lo ti leri leka lati gbẹsan bi wọn se sẹburu awọn ọmọogun rẹ mẹfa to n lọ pẹtu si aawọ nipinlẹ Niger, ti wọn si pa wọn ni ipakupa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here