Bobrisky! Bó ṣé pín àga ọ̀fẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ló ń tún p’ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà gbà pé èèyàn tí òmìnira rẹ̀ kò sí ní ìkápá rẹ̀, ọ̀wọ́ ọlọ́wọ́ ni onítọ̀hún wà.
Ọkùnrin tó máa ń múra bíi obìnrin, Idris Olanrewaju Okuneye, ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tako ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà tí ilé ẹjọ́ dá fún un lẹ́yìn tó jẹ̀bi ẹ̀sùn títàbùkù owó náírà.
Idris, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky, ló pe ẹjọ́ náà láti ọwọ́ agbẹjọ́rò rẹ̀, Bimbo Kusanu, pé kí ilé ẹjọ́ yí ìdájọ ẹ̀wọn tó fún òun padà, kó sì fún òun láǹfàní láti san owó ìtanràn dípò ẹ̀wọ̀n.
Ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2024 yìí ni adájọ́ Abimbola Awogboro ti ilé ẹjọ́ gíga ìlú Èkó ṣèdájọ́ ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà láì sí ànfààní láti san owó ìtanràn kankan fún Bobsirky lẹyìn tó jẹ̀bi ẹ̀sùn títàbùkù owó náírà.
Nígbà tó ń dájọ́ ọ̀hún, adájọ́ náà ní ìdájọ́ náà yóó kọ́ àwọn aráàlú tó bá fẹ́ máa wu irúfẹ́ ìwà bẹ́ẹ̀ lọ́gbọ́n.
Ṣaájú ìdájọ́ yìí lọ́jọ́ kàrún un, oṣù Kẹrin yìí kan náà ni ọ̀daràn ọ̀hún ti kọ́kọ́ sọ pé òun jẹ̀ẹ
bi ẹ̀sùn tí àjọ EFCC fi kan òun.
Nínú ìwé ìpẹ̀jọ́ kòtẹ́milọ́rùn rẹ̀, ọ̀daràn náà sọ pé ilé ẹjọ́ fún òun ní ìjìyà tó pọ̀ jùlọ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí òun ṣẹ bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò ní àkọsílẹ̀ kankan ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi arúfin.
Gẹ́gẹ́ bíi ohun tó sọ, ìdájọ́ ọhún wáyé láì sí ojú àánú kankan fún òun, èyítí kò sì ní ìbámu pẹ̀lú àlàkalẹ̀ òfin Administration of Criminal Justice, ACJA, ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó fi kún pé adájọ́ náà kò tún wo ti pé òun kò fi àkókò ilé ẹjọ́ ṣòfò látàrí bí òun ṣe tètè sọ pé òun gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.
Ẹ́wẹ̀, láàrin nǹkan bíi ọ̀sẹ̀ méjì péré lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ìròyìn tó ń tẹ wá lọ́wọ́ sọ pé Bobrisky ti fi àwọn àga kan ta ọgbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì tó wà lọ́rẹ̀.
Nínú àwòrán àga náà tó gba orí ayélujára kankan, wọ́n kọ àkọlé “si iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Nàìjíríà láti ọwọ́ idris Okuneye Bobrisky” sí lára.
Ìròyìn tó gba ìgboro nípa àwọn àga náà ni pé ó wà fún agbègbè tí àwọn àlejò yóò máa jókòó sí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ọ̀hún.