Ikú! Ìràwọ̀ òṣèrè e tíátà kan tún ti wọ̀ọ̀kùn òjijì
Ọrẹ Òtítọ́jù
Àrùn la rí wò, a ò rí ti ọlọ́jọ́ ṣe.
Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn òṣèré tíátà ilẹ̀ wa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìdelẹ̀bọ̀, Adejumọkẹ Aderounmu, arẹwà òṣèrébìnrin tó kópa “Esther” nínú eré àtìgbàdégbà tí Funkẹ Akindele ṣe, tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Jenifa Diary, ti jáde láyé, lẹ́ni ogójì (40) ọdún!
Ọkan ninu awọn mọlẹbi oṣere ọhun, Adeọla Aderounmu, lo kede iku rẹ lori ayelujara laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin ta a wa yii.
Oun ti a gbọ ni pe, ko tii sẹni to mọ pato ohun to ṣokunfa iku ojiji fun oṣere naa. Lori ọkan lara awọn ikanni ayelujara nibi ti wọn ti kede iku awẹlẹwa yii, ni wọn kọ ọ si pe: “Ọkan ninu awọn mọlẹbi irawọ oṣere to fakọyọ ninu ere atigbadegba Jenifa Diary, Jumọkẹ Aderounmu, ti kede pe onitiata to n goke agba bọ yii ti ku. A o tii mọ hulẹhulẹ nipa iku rẹ. Ki Ẹlẹdaa rẹ fun ẹmi ẹ lalaafia.”
Nigba aye rẹ, Jumọkẹ Aderounmu wa lara awọn oṣere-binrin ti wọn forukọ rẹ silẹ lati gba ẹbun oṣere to fakọyọ ju lọ lọdun 2013, nibi ayẹyẹ International Film Festival, to waye niluu Dallas, lorileede Amẹrika.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 1984 ni Adejumọkẹ dele aye, o si jade laye lọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin ọdun yii, nileewosan aladaani kan, ti wọn ko darukọ rẹ.
Ọmọ bibi ilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun ni, ibẹ lo si ti bẹrẹ ere tiata lẹyin to pari ẹkọ fasiti rẹ, amọ ọdun 2016 to kopa to jọju ninu ere Jenifa Dayari ni irawọ rẹ bẹrẹ si i tan.
Bakan naa lo kopa Yejide ninu ere elede oyinbo ti wọn pe akọle rẹ ni Dazzling Mirage, o si wa ninu awọn to fakọyọ ninu Industreet ati Alakada 2.
Àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ arò àti ìbánikẹ́dùn nípa ikú òṣèrébìnrin ọ̀hún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé fọ́tò àti fídíò rẹ̀ kan sójú òpó ayélujára wọn láti fihàn pé ìpapòdà a rẹ̀ jẹ́ ìbànújẹ́.